Wo obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò lọ sínú òfurufú láti ilẹ̀ Adúláwọ̀

Àkọlé fídíò, Wo obìnrin àkọ́kọ́ tó lọ sínú òfurufú láti ilẹ̀ Adúláwọ̀
Wo obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò lọ sínú òfurufú láti ilẹ̀ Adúláwọ̀

Ko si ohun ti ọkunrin ṣe ti obinrin naa ko le ṣe, gẹgẹ bi wọn ṣe maa n sọ.

Bẹẹ gan an lọrọ ri pẹlu Sara Sabry to jẹ obinrin akọkọ ti yoo lọ sinu ofurufu lati ilẹ Afirika.

Sabry ni awọn obinrin ko nilo ironilagbara ti ọpọ maa n pe fun fawọn obinrin, tori awọn obinrin ti ni gbogbo agbara ti wọn nilo.

O ni nnkan ti awọn obinrin nilo ni ibadọgba.

Sabry ni jijẹ obinrin akọkọ ti yoo lọ sinu ofurufu lati ilẹ Afirika jẹ ohun iwuri nla.

‘’Wọn maa n sọ fun wa ni orilẹede wa pe ko ṣeeṣe.

Eyi gan an lo fi jẹ ohun apọnle ati awokọṣe nla ti n ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu.

Wọn mu mi lọ sinu ofurufu laarin ẹgbẹẹgbẹrun eeyan kaakiri agbaye,’’ Sabry lo sọ bẹẹ.

O ni oun ti maa n ṣe oriṣiiriṣii nnkan tẹlẹ tori pe oun nifẹ sawọn iru bẹẹ.

Sabri ni oun ti kẹkọọ nipa imọ ẹrọ nitori o wu oun ati lati mọ bi ile aye ṣe n ṣiṣẹ.

Bakan naa ni o sọ pe oun maa n nifẹ lati wa ojutuu si iṣoro, oun ṣi maa n ṣe eleyi pẹlu igboya.

Sabri ni ‘’lati iran kan de iran mii titi de iran oun lawọn eeyan ti maa n ro pe awọn obinrin ko le ṣe awọn nnkan kan tori pe wọn jẹ obinrin.

Lati igba ti mo ti de lati inu ofurufu ni mo ti n ṣiṣẹ lori awọn nnkan kan lati maye dẹrun fawọn eeyan kaakiri agbaye.

Mo ṣi tun n kẹkọọ lọwọ lori ati gboye imọ ijinlẹ Ọmọwe ni ile ẹkọ giga fasiti lori ewu to wa ninu ofurufu.