Kí o tó 'Japa', á dára kí o mọ ewu tó wà nínú rẹ̀; díẹ̀ lára ewu 'Japa' nìyí

Young man in a baseball cap
    • Author, Hannah Gelbart
    • Role, BBC What in the World, Lagos

Olotu Olanrewaju, ọmọ Naijiria to ṣẹsẹ kẹkọọjade nile ẹkọ giga n koju ipinnu meji ọtọtọ; ṣe ko duro Naijiria to fẹran tabi ko tẹkọ leti lọ soke okun fun igbeaye to dara.

Ọdọkunrin naa kundun aṣa, ounjẹ, orin atawọn mọlẹbi rẹ ni Naijiria, paapaa bi wọn ṣe maa n tọju ara wọn.

Amọ ẹni ọdun mẹrinlelogun naa ko ni itẹsiwaju ninu igbeaye rẹ, paapaa nipa iṣẹ to amojuẹrọ to yan laayo.

O ni “kaka ki n ha si Naijiria, mo n wa anfani lati lọ soke okun ki n le ri anfani to dara ju eyii ti mo nile lọ.”

Olanrewaju sọ fun BBC pe o dabi pe niṣe aye oun wa loju kan naa.

Ninu ọrọ rẹ, oniruru iṣoro lo n koju Naijiria, lara rẹ ni eto abo to mẹhẹ, ina ọba ti ko ṣe dede atawọn ohun amayedeorun ti ko si.

Olanrewaju jẹ ọkan lara ẹgbẹgbẹrun ọmọ Naijiria to ni erongba lati japa lọ silẹ mii fun ọjọ iwaju to dara.

BBC kan si ijọba lati mọ erongba rẹ nipa bi awọn ọdọ ṣe n japa amọ ijọba kọ lati fesi.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn ọdọ yoo maa fi orilẹede Naijiria silẹ lọ soke okun fun igbeaye to dara ju eyii ti wọn n gbe nile lọ.

Lati ọdun 1980 soke ni awọn eeyan to lowo diẹ lọwọ ti n salọ ilẹ mii amọ ọrọ naa gbajumọ lasiko yii laarin awọn ọdọ ju ti atijọ lọ.

Iwadii kan ti ajọ African Polling Institute ṣe lọdun 2022 fi han pe ida 69% ọdọ ti ọjọ ori wọn bẹrẹ lati ọdun mejidinlogun si marundinlogoji ni yoo fi Naijiria silẹ ti aye ba gba wọn.

Lọdun 2019, ida 29% ọdọ ni Naijiria ni yoo gbe igbesẹ naa.

Lọwọ yii, ọpọ ọdọ ni Naijiria lo ti bẹrẹ si n sọ iriri wọn lẹyin ti wọn japa tan.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe awọn n saaro awọn mọlẹbi ti wọn fi silẹ nile, lawọn mii n sọ pe igbesẹ to tọ fun awọn ni bi wọn ṣe japa, ti wọn si n ke si awọn akẹgbẹ wọn ki awọn naa gbe irufẹ igbesẹ kan naa.

Wayi o, ko rọrun lati japa, owo gọboi si lawọn to n japa n na ki wọn to de oke okun.

Fun awọn ti ko ri aye japa lọna to rọrun, wọn n fi ẹsẹ rin gba aṣalẹ Sahara, eyii to maa n mu ẹmi pupọ ninu wọn lọ.

Fun Olanrewaju, o ti mura lati japa lọ si Germany tabi Spain, oun atawọn obi rẹ si ti n kowo jọ fun irinajo naa bayii botilẹ jẹ pe ẹgbọn rẹ kan ti kọkọ lọ ṣaaju.

A young woman with maroon braids and a red top

Ọdun to kọja ni Oluwatobi Abodunrin, to jẹ oṣiṣẹ awujọ niluu London japa, o sọ pe inu oun si bi oun ṣe fi Naijiria silẹ.

O ni “mo pinnu lati kuro ni Naijiria nitori ọwọ mi ko tẹ ohun ti mo n wa.”

Abodunrin tun sọ pe ko rọrun lati fi gbogbo ọrẹ atawọn ẹbi oun silẹ ni Naijiria lọ soke okun.

Ẹni ọdun mẹtadnilọgbọn naa ni “ko rọrun fun mi lati fi ile silẹ, lati fi awọn eeyan to dara bẹẹ silẹ, ko rọrun rara amọ inu ki dun pe mo gbe igbesẹ ọhun, nnkan si n lọ dede fun mi.”

O le ni 270,000 awọn ọmọ Naijiria to n gbe nilẹ Gẹẹsi nikan ṣoṣo, gẹgẹ bii atẹjade ijọba ilẹ naa.

UK jẹ ilẹ kan ti awọn ọmọ Naijiria n japa lọ, o si le ni ilọpo mẹrin wọn to ti tẹkọ leti lọ ilẹ naa lati ọdun 2019.

Wayi o, ilẹ UK ti gbe awọn ofin tuntun kalẹ lati mu ko le koko lati wọ ilẹ ọhun.

Orilẹede Canada ati Amẹrika naa ti gbe irufẹ igbesẹ kan naa.

Ni Canada, iye awọn ọmọ Naijiria to n fẹ wọ ilẹ naa ti le si, eyii ti wọn n pe ni “Canada Rush”.

Elizabeth Ademuyi Anuoluwapo to ṣi wa ni Naijiria ni ko rọrun lati japa amọ igbesẹ naa jẹ ọna kan gboogi lati lu aluyọ ti oun n fẹ.

O ni “mo maa saaro awọn eeyan mi, ounjẹ Naijiria, awọn mọlẹi ati ọrẹ mi… boya mo kan maa lọ ti mo si maa pada laarin ọdun diẹ si.”

Lara awọn ẹka ti japa n pa lara julọ ni Naijiria ni ẹka eto ilera.

Ẹgbẹ awọn dokita ni Naiiria, NMA sọ pe aadọta dokita lo n japa laarin ọsẹ kan ni Naijiria, igbesẹ naa si n ṣe ipalara to lewu fun ẹka eto ilera Naijiria.

Ijọba ni oun yoo ṣe idanuilẹkọọ fun awọn dokita mii ti yoo maa rọpo awọn to n japa.

Laipe yii ni ile igbimmọ aṣofin daba lati mu ki dokita to ba kẹkọọjade ni Naijiria ṣiṣẹ ni Naijiria fun ọdun marun un gbako ko to le japa, amọ ẹgbẹ awọn dokita tako igbesẹ naa.

Dokita Vongdip Nankpah to wa ni ile ẹkọ ẹkọṣẹ iṣegun ilu Abuja sọ pe o ṣe pataki ki awọn dokita maṣe japa nitori o san ki eeyan sin ilu rẹ ju ko tẹ ara rẹ lọrun lọ.

Nigba ti iru awọn eeyan bii Olaranwaju gbagbọ pe oun ko jẹ ijọba ni ohunkohun ti yoo mu ki oun kojo si Naijiria.

O ni kaka ki oun joko si Naijiria, oun yan lati japa ki oun si maa ṣoju Najiria loke okun.

Wayi o, fun awọn to lowo lọwọ, ṣe ni wọn n jap abo tilẹ jẹ o n tumọ si pe ọpọ wọn yoo fi ẹbi ati ara silẹ.

Awọn mii to lọwọ si iroyin yii niMakuochi Okafor, Faith Oshoko, Emily Horler ati Alex Rhodes.

A woman looking at her mobile phone and the graphic BBC News Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images/BBC