Obìnrin méjì tó ni ibùdó tí wọ́n ti ń ta ọmọ ní N400,000 rugi oyin l‘Ogun

Baby factory

Oríṣun àwòrán, Abimbola Oyeyemi

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ obinrin meji, Christiana D'ivoire Iyama ati Margaret Ogwu lori ẹsun pe wọn da ibudo ti wọn ti n ta ọmọ silẹ.

Akara awọn afurasi naa tu sepo lẹyin ti wọn fi ọrọ wọn lọ ni agọ ọlọpaa to wa ni Agbado, nipinlẹ Ọhun.

Ọlọpaa ni ile kan to wa ni ojule kẹrin, ni adugbo Ibrahim Famuyiwa ni wọn ti n ṣiṣẹ laabi naa.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ṣe ni awọn afurasi naa maa n bẹ awọn ọkunrin lọwẹ lati fun obinrin loyun, ti yoo si ta awọn ọmọ ti wọn ba bi lẹyin ọjọ ikunlẹ.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejọ, ọdun 2022 yii ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa.

Ọmọ mẹta ni a ti ta, a ta ẹyọ kan ni ₦400,000

Oyeyemi sọ pe iwadii awọn fi han pe, Margaret Ogwu wa lara awọn ọdọbinrin ti Christiana D'ivoire gba sile, ti ọkunrin kan fun loyun, ti wọn si ta ọmọ jojolo naa ni ẹgbẹrun lọna irinwo naira.

Ọlọpaa ni D'ivoire tun jẹwọ pe ọmọ mẹta ni oun ti ta ninu owo naa ki aṣiri to tu.

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti paṣẹ ki wọn tari ọrọ naa lọ si ẹka CID to n ṣe iwadii iwa ọdaran fun iwadii ni kikun, ki awọn afurasi ọhun si le foju bale ẹjọ ni kankan.