Luz Truss di Olóòtú ìjọba tuntun nílẹ̀ UK

Ijọba ilẹ UK ti kede Liz Truss, tẹgbẹ oselu Conservative Party, gẹgẹ bi ẹni to bori ninu ifigagbaga lati jẹ Olootu ijọba ilẹ naa.
Ọjọ Isẹgun ọla ni yoo gba ipo Olootu ijọba naa lẹyin to ba se abẹwo si Ọbabinrin Elizabeth Nilu Balmoral.
Asiko abẹwo yii ni yoo fi to Ọbabinrin Elizabeth leti pe oun fẹ gbe ijọba tuntun kalẹ nilẹ UK.
Ọlọla Graham Brady ti wa kede iye ibo ti Liz Truss gba lati fi ẹyin Rishi Sunak, tii se alatako rẹ ninu ifigagbaga naa janlẹ.
Graham ni Truss ni ibo 81,326 nigba ti Sunak ni ibo 60,399.
O fikun pe ida mejilelogoji ati mẹfa ninu ọgọrun lo kopa ninu eto idibo naa.
Ẹgbẹ oselu Conservative ni yoo bori Labour ninu eto idibo 2024 - Luz Truss
Nigba ti wọn n patwọ fun lori bo se jawe olubori ninu ifigagbaga naa, Luz ni ohun ọwọ ati iwuri lo j fun oun pe wọn yan oun bii olori.
O wa dupẹ lọwọ ẹgbẹ oselu naa fun bo se seto ifọrọwerọ igbanisisẹ to tii gun julọ ninu itan,
Bakan naa ni Luz dupẹ lọwọ awọn alatilyin r fun iwuri wọn.
Luz wa kede pe oun yoo se aseyọri nla lori ipo naa.
O wa fọwọ gbaya pe ẹgbẹ oselu Conservative ni yoo bori ẹgbẹ oselu Labour ninu eto idibo gbogbo gboo ti yoo waye lọdun 2024.

Olóòtú ìjọba túntún yóò fojú hán ní UK laìpẹ́

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ni wakati diẹ si asiko yii, ni Olootu ijọba tuntun fun ilẹ United Kingdom, UK yoo fi oju han.
Ẹgbẹ oṣelu to ṣe ijọba lọwọ lorilẹede UK ni anfani ti wa fun labẹ ofin lati yan olotu ijọba tuntun ti yoo tukọ iṣejọba lẹyin ti Olootu ijọba tẹlẹ, Boris Johnson, fi ipo silẹ.
O ti han si ọpọlọpọ bayii pe ipo olotu ijọba orilẹede UK wa laarin Liz Truss ati Rishi Sunak
Lọsẹ diẹ sẹyin, Liz Truss ni igbagbọ wa pe yoo bori ninu eto idibo aarẹ lorilẹede UK.
Ninu osu kẹjọ, YouGov gbe iroyin pe Liz Truss fi ida lọna mẹrindinlaadọrin ibo bori Rishi Sunak, ẹni to ni ibo ida mẹrinlelọgbọn.
Ni bayii, awọn adari ẹgbẹ oṣelu ti ṣetan lati lati kede ẹni to bori ninu awọn oludije ti wọn fifẹ han si ipo naa.
Ẹgbẹ oṣelu naa lo jẹ ọkan lara awọn ẹgbẹ oṣelu to ti pẹ lorilẹede UK.
Ohùn márùn-ún tó yẹ kó mọ nípa àwọn Olùdíje
Rishi Sunak
Sunak ba olotu ijọba tẹlẹ Boris Johnson sisẹ sugbọn wọn daduro.
O wa lara awọn lara to ke sita pe ki wọn fikun ọjọ ti awọn to lugbadi aarun Covid 19 ma lo nile.
Olopaa fẹsun kan lọdun 2020 pe o tapa sofin
Okiki iyawo Sunak tan kiri lẹyin to kọ lati san owo ori.
Liz Truss
Truss jẹ akọwe ileeṣẹ to risi ọrọ okere nigba ti Boris Johnson wa ni ijọba.
Ọpọ ara ilu ti ni Truss ni yoo bori eto idibo naa.
Ile ẹkọ ijọba ni Truss ti kawe jade
O wa lara awọn to pe fun pe ki wón fi opin si ipo olotu ijọba lorilẹede UK
Truss ni o wa lara awọn to ni ki Britain ma kuro lara awọn orilẹede EU sugbọn o pada ni o da bi wọn se kuro.















