N kò le dúró láti bẹ̀rẹ̀ sáà kejì pẹ̀lú igbákejì mi tuntun - Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo ni o wu oun ko jẹ oe oun ati igbakeji gomima tuntun, Adebayo Lawal, ni awọn jọ bẹrẹ iṣejọba lati ọdun 2019.
Makinde sọ eleyi nigba to pada de lẹyin o gba isimi ranpẹ lẹnu isẹ.
Fun Igba akọkọ laarin ọdun mẹta ti o ti n se ijọba ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde kọ iwe ranṣẹ si ile igbimọ aṣofin lati beere isinmi lẹnu iṣẹ.
Bakan naa si ni Makinde ti yọnda agbara fun igbakeji rẹ, Adebayo Lawal lati maa dele gẹgẹ bii gomina nibamu pẹlu ilana ofin.
O ni isinmi naa fun oun ni anfani lati ro bi ilọsiwaju yoo ṣe ba ipinlẹ Oyo.
Makinde ni oun gbosuba fun igbakeji gomina tuntun fun bi o se mu ile duro lẹyin ti oun rinrinajo lọ sinmi.
O ni bi Igbakeji ṣe di ile mu ti safihan pe ijọba ipinlẹ Oyo jẹ ajumọse gbogbo wa.
“Nkan ti afihan awọn eeyan ni ipinlẹ Oyo ni pe ko ki n ṣe ẹnikan lo ṣe ijọba ipinlẹ, bi ko ṣe ajumọse gbogbo lapapọ.
Bayo Lawal kúnjú ìwọ̀n ni mo ṣe fa àkóso Oyo le lọ́wọ́ láti lọ sinmi - Makinde
“Lati ni ọsẹ mẹta bayii, ipinlẹ Oyo ko ti mọ pe emi ko si nile nitori pe Igbekeji mi ṣe isẹ gidi.
“Mo dupe lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo fun atilẹyin wọn lori ilọsiwaju ipinlẹ Oyo.
“Mo fẹ ki igbakeji Gomina fun isẹ ribiribi ti wọn. O yẹ ki ajọ bẹrẹ iṣejọba yii sugbọn ko pẹ ju.
“Mo dupe, mi o lẹ duro lati bẹrẹ isẹ pelu igbakeji gomina titi saa yii o fi pari, ti a si tun jọ bẹrẹ saa keji papọ lọdun 2023.
Nigba to ki Makinde kaabọ, Igbakeji gomina, Adebayo Lawal ni laarin ọsẹ mẹta ti oun fi ṣe ijọba, oun ri isẹ ribiribi ti Gomina Makinde n ṣe fun ilọsiwaju ipinlẹ Oyo.
O wa dupẹ lowọ Gomina fun igbagbọ to ni ninu oun lati gbe iṣejọba ipinlẹ oyo le oun lọwọ nigba to lọ sinmi.

Oríṣun àwòrán, Facebook.com/OfficialSeyiMakinde
Afurasí méjì gún èèyàn mẹ́wàá pa ní Canada, 15 míì farapa

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ileeṣẹ ọlọpaa Canada ti n wa awọn ọkunrin meji kan ti wọn fura si pe awọn lo gun eeyan mẹwaa pa nigba ti awọn marundinlogun mii farapa lagbegbe Saskatchewan.
Awọn afurasi naa, Damien Sanderson ati Myles Sanderson ti na papa bora bayii, ọlọpaa si ti kede wọn gẹgẹ bii ewu nla fun awọn araalu.
Agbegbe mẹtala ni wọn ti ri awọn eeyan ti awọn afurasi naa gun pa ni iha James Smith Cree Nation ati Weldon.
Olootu ijọba Canada, Justin Trudeau ni iṣẹlẹ naa jẹ eyi to buru ju iru rẹ ti yoo waye ninu itan orilẹ-ede ọhun.
Trudeau sọ pe “Iṣẹlẹ yii jẹ eyii to bu omi tutu simi lọkan, gbogbo awọn to lọwọ ninu ikọlu naa si gbọdọ fi oju wina ofin.”
O kere tan, eeyan marundinlogun lo farapa nibi isẹlẹ naa, ileeṣẹ ọlọpaa si ti gba awọn araalu niyanju lati maa ṣora.

Oríṣun àwòrán, RCMP SASKATCHEWAN
Ijọba ilẹ naa ti wa fi atyẹjiṣẹ ṣọwọ si gbogbo ẹrọ ilewọ to wa lagbegbe Saskatchewan, Manitoba ati Alberta bayii.
Bakan naa ni wọn ti kede ofin ilu o fararọ ni James Smith Cree Nation, nibi ti nnkan bii ẹgbẹrun meji eeyan n gbe.
Titi di asiko ti a nko iroyin yii jọ, ko si ẹni to tii le sọ eredi ti awọn afurasi naa ṣe ṣekọlu ọhun.
Ọlọpaa ni o ṣeeṣe ki awọn to farapa ju awọn marundinlogun ti awọn ni akọsilẹ rẹ lọ.















