Ẹ̀yin tẹ̀ ń pe Oluomo ní ọmọ ìta àti apaàyàn, éèló ló wà nínú àkáǹtì yín? - Esther Ajayi

Obasanjo and MC Oluomo

Oríṣun àwòrán, kingmcoluomo

Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Aarẹ Naijiria nigba kan ri, Oloye Olusegun Obasanjo, Musiliu Akinsanya, ti ọpọ mọ si MC Oluomo, Dele Momodu, Sir Shina Peters, atawọn eeyan jankan mii lo peju sinu ijọ Love of Christ Generation Church lọjọ Aiku.

Oludasilẹ ijọ naa, alufaa obirin, Esther Ajayi lo fi iwe pe awọn eeyan ọhun fun ayẹyẹ ajọdun ọdun karundinlogun ti wọn da ijọ naa silẹ, ati ayẹyẹ ọdun kan ti wọn ṣi olu ijọ naa, eyii to wa ni VI, niluu Eko.

Ọpọ awọn ọmọ ijọ, alufaa, oloṣelu, akọroyin, to fi mọ awọn ẹṣọ alabo lo peju sibi ayẹyẹ ọhun.

Maalu mẹrin ati ₦1m ni Oluomo fi ranṣẹ si wa fun ajọdun - Esther Ajayi

Nigba to n sọrọ nipa Oluomo ninu isin ọhun, oludasilẹ Esther Ajayi sọ pe odidi maalu mẹrin ni Oluomo fi ta ijọ naa lọrẹ ki wọn fi ṣe ọdun, koda o tun fi miliọnu kan naira kun maalu naa lati ra elo.

Ajayi sọ pe ọpọ eeyan lo maa n fi oju ọmọ ita wo Oluomo ti wọn si maa n wo bi ẹlẹṣẹ, amọ Oluomo ki ṣe ero ọrun apaadi.

O ni “Oluomo maa bọ nibi ṣebi ọmọ mi ni ẹ.

“Waa ro pe ọrun apaadi lo (Oluomo) maa amọ o ti ṣe aṣiṣẹ lati maa ronu bẹẹ.”

“Eeyan lo maa n juwe bi aye rẹ ṣe maa ri... Ti ẹ ba sọ fun ọmọkunrin yii pe aago mẹta ni adura yẹn o, ko ni jẹ ki akoko naa yẹ pẹlu iṣẹju kan.

Ajayi ni Oluomo ṣe maa n ṣe amin lori foonu gan dara ju ti awọn Kristẹni kan lọ ti wọn maa n fi Jesu ṣakọ, bo tilẹ jẹ pe Musulumi ni, Musuliu si ni orukẹ rẹ.

Ajayi tẹsiwaju pe “Bi a ṣe sọ pe a maa ṣe ajọdun, o ni maami emi naa maa nipa ninu ẹ o, maalu mẹrin lo fi ranṣẹ si wa... Nigba to tun ya, o ni mililọnu kan naira loun fi si ka fi ra elo ti a maa fi se ọbẹ.”

Obasanjo and Oluomo

Oríṣun àwòrán, kingmcoluomo

Ẹ̀yin tẹ̀ ń pe Oluomo ni ọmọọ̀ta àti apaayan, eelo lo wa ni akanti yin - Esther Ajayi

Lẹyin naa ni alufaa Ajayi bu ẹnu atẹ lu awọn Kristẹni to maa n sọrọ kobakjungbe nipa Oluomo pe wọn ti dẹṣẹ.

O ni awọn Kritẹni kan a maa sọ pe “Apaayan ni wọn, wọn n ṣe ọmọ ita, iwọ ti o ko ṣe ọmọ ita ṣebi o mọ iye to wa ninu apo iṣuna rẹ ni banki?”

Bo tilẹ jẹ pe Oluomo ko sọ ohunkohun lasiko isin naa, ọpọ eeyan lo mọ pe o wa nibẹ.

Bi Oluomo ṣe n dọbalẹ ki Ooni naa ni ko yọ Obasanjo, Shina Peters atawọn ladelade mi to yọju sibi ajọdun naa sẹyin.

Ooni Ile Ife

Oríṣun àwòrán, Rev Esther Ajayi

Ki ni Obasanjo sọ?

Oloye Olusegun lo waasu nibi ajọdun naa, eyii to pe akori rẹ ni “Ẹri ti a fi fun ni,” to si mu ẹsẹ bibeli rẹ ninu iwe Gen 40:8.

Obasanjo tọka si iwaasu akọkọ ninu gbọngan ile ijọsin naa eyi ti alufaa agba ninu ijọ RCCG, pasito E.A. Adeboye ṣe lọdun to kọja ti wọn ṣi ijọ ọhun.

Aarẹ Naijiria tẹlẹ ri naa sọ pe o dara lati sọ ẹri ohun ti Ọlọrun ṣe fun ẹda nitori o maa n gbe iṣẹ Oluwa ga bnwaju ẹlọmiran.

Obasanjo wa gba Esther Ajayi lamọran lati gbe iwaasu iyinrere kaakiri agbaye.