Lẹ́yìn tí ilé alájà méje dàwó lulẹ̀, iná tún sọ!

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ijamba miran tun ti waye ni agbegbe Oniru, Lekki nipinlẹ̀ Eko lẹyin ti ina sọ ni ile alaja mẹta nibẹ.

Ibi ti iṣẹlẹ ijamba ina ti ṣele naa wa ni tosi ibi ti ile alaja meje ti wo, ti ẹmi eniyan meji si lọ si iṣẹlẹ naa.

Agbegbe Ifeanyi Street ni iṣẹlẹ naa, ti waye to si jẹ adugbo kẹta si ibi ti ile alaja meje naa ti wo ni owurọ ọjọ Isinmi.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣe oju ẹ ni aarọ ọjọ Aiku kan naa lo waye.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Titi di asiko yii ohun to fa ina naa ko i tii han si gbangba amọ awọn oṣiṣẹ pajawiri to fi mọ awọn panapana wa nibi iṣẹlẹ naa.

Bakan naa ni ko i tii si ẹnikẹni to ku ninu iṣẹlẹ naa amọ o ṣeeṣe ki ọpọlọpọ dukia ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ninu ile alaja meje to wo naa ni wọn ti gbe oku eniyan meji jade ni abẹ ile naa, ti awọn mẹrin si ha si inu ilẹ.

Amọ Ajọ pajawiri ni awọn ṣi n sa gbogbo ipa wọn lati doola ẹmi awọn to ha sibẹ.