Ó dídì ọjọ́ méjì ní mó fí jẹ́yá fẹsùn pé mo ní Ajẹ́ - Amarachi

Aworan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Arabinrin Amarachi Okechi ti salaye ohun ti oju rẹ ri lẹyin ti wọn fẹsun pe o ni ajẹ ni agbegbe Umueghu ni Ipinlẹ Abia.

Awọn eeyan to wa nibi iṣẹlẹ naa ni okun ni wọn fi de obinrin naa, ti wọn si wọ lọ sínu ọja nibi ti wọn ti da sẹria fun.

Nigba ti Okechi ba BBC sọrọ, o nipe iyawo aburo ọkọ oun, Arabinrin Patience Obinna lo fẹsun kan oun ati pe oun lọwọ ninu lasigbo to sẹlẹ si awọn ọmọ rẹ ati bi ọkọ rẹ ṣe ku.

O ni kete ti awọn araalu gbọ sì iṣẹlẹ naa, ni wọn mori le ile alawo nibi ti wọn ti fìdi ẹ mule pe, ajẹ ni oun.

“Wọn fẹsun kan an pe ajẹ ni mi, wọn wa si ile mi, wọn lu mi fun odidi ọjọ meji.

“Nigba ti wọn tu ile, wọn ko ri nkankan.

“Awọn agbagba ilu wa nibẹ ati awọn obinrin ilu, sugbọn wọn kuna lati gbami silẹ lọwọ awọn eeyan to lumi.”

''Awọn ọdọ tun ti pinnu lati fi lulu pa iya oun nitori ẹsẹ ti ko mọ di.

Ọmọ Amarachi Okechi, Arabinrin Onyinyechi ni ọpọlọpe igbe oun to de ọdọ iyawo gomina ipinlẹ Abia, awọn ọdọ naa ti pinnu lati fi lulu pa iya oun nitori ẹsẹ ti ko mọ di.

Pẹlu omije o wa rọ ijọba lati fi sinku ofin awọn ọdọ to ṣeṣe ibi naa nitori isẹlẹ na ti jẹ ki awọn eeyan pe iya oun ni ajẹ.

“Lọwọ bayi, a ti sa kuro ni agbegbe naa nitori bi wọn ṣe ba orukọ iya mi jẹ.''

“Wọn fẹ le gbẹmi iya mi lọwọ lulu. Wọn gbe wọn ju silẹ mọjumọ sinu ọja pẹlu bi wọn ṣe de wọn lokun.''

“Lọjọ kẹji, wọn tun tẹsiwaju nibi lulu ti wọn si ni ki iya mi mu wọn lọ sibi to ti ṣe ogun ika si ọmọ aburo baba mi.''

“Sugbọn iya mi ni oun ko mọ ile alawo kankan nitori ile ijọsin ni wón ti n jọsim fun Ọlọrun.''

“Ipinlẹ Eko ni mo wa ti mo si n fi owo ransẹ lati san gbese nitori lẹyin ti wọn bẹrẹ lulu yii, awọn ti iya mi jẹ lowo yari pe wọn gbọdọ san owo ti wọn jẹ wọn''

“Owo ti mo fi ransẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọrin naira sugbọn awọn ọdọ yii si kọ lati jẹ ki awọn ti iyawo ran wa si agbegbe naa gbe iya mi lọ.''

“Won ni iya mi gbọdọ fun wọn ni ọti ati ogogoro lati mu.”

aworan Arabinrin Amarachi Okechi ati ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, others

Eze Amaegbuato ti ilu Nkpa, Christopher Chibuike Izuo ba BBC News sọrọ, o ni oun iyalẹnu lo jẹ fun awọn oloye ilu nitori awọn ko mọ nipa isẹlẹ naa.

Izuo ni ilu alaafia ni Nkpa ni bi agbegbe Umueghu ti isẹlẹ naa ti waye wa.

O ni oun ti igba ipe lati ọdọ gomina ati awọn olopaa lori isẹlẹ .

“Awọn ọdọ ni awọn ko ara wọn jọ lati wu iwa labi yii nitori wọn ko fi to awọo olori ilu leti nipa erongba wọn

Aráàlú lu obìnrin kan ní àlùbami lórí ẹ̀sùn pé àjẹ́ ni

Obinrin kan tí orukọ rẹ jẹ Amarachi Okechi, ni awọn eeyan agbegbe Umueghu ni Ipinlẹ Abia, lu ni alubami lẹyin ti ọkan lara awọn mọlẹbi rẹ fẹsun kan pe o ni ajẹ.

Awọn eeyan to wa nibi iṣẹlẹ naa ni okun ni wọn fi de obinrin naa, ti wọn si wọ lọ sínu ọja nibi ti wọn ti da sẹria fun.

Iroyin ti a gbọ nipe iyawo aburo ọkọ arbinrin lo fẹsun kan ń pe, o lọwọ ninu lasigbo to sẹlẹ si ọmọ oun.

Iroyin naa ni, kete tawọn araalu gbọ sì iṣẹlẹ naa, ni wọn mori le ile alawo níbi ti wọn ti fìdí ẹ mule pe, ajẹ ni Amarachi Okechi.

Kete ti alawo kede pe ajẹ ni arabinrin naa, ni awọn eeyan fi tipatipa mu lọ síbi tí wọn ti lu ni alubami.

Awọn araalu naa ni wọn ko fun ẹnìkẹni ni anfani lati gba obinrin naa silẹ, tí wọn sì tun gbe bí wọn ṣe na si ori ayelujara.

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Kí ló fà ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ naa?

Ileeṣẹ BBC kan sì ọmọ Amarachi Okechi, tí orukọ rẹ jẹ Onyinye Okechi, tí o si ni pe Iyawo ẹgbọn oun lo fẹsun ajẹ kan iya oun.

O ni "Iyawo ẹgbọn mi to jẹ opo lo ni iya mi lo pa ọkọ oun."

"Nigba ti ọmọ rẹ ṣe aarẹ, o ni iya mi lo wa nidi rẹ.

"Ṣugbọn iya mi ni oun ko mọ nkankan nípa iṣẹlẹ naa ati pe ko gbe ọmọ rẹ lọ si ile iwosan.

"Ṣugbọn o kuna lati ṣe bẹẹ, tí ó sì bẹrẹ si ni ma ro kaakiri pe ajẹ ni iya mi.

"Eyi bí iya mi ninu, to fẹjọ sun awọn olori ilu.

"Onyinye tẹsiwaju pe awọn olori ilu pe alawo lati se iwadi lori ẹsun tí wọn fi kan, o sì ransẹ pe iya mi.

O ni oun ko faramọ sugbon iya oun ni igbati inu oun mọ, ko ni si nkankan.

"Nigba ti wọn de ọdọ alawo, o ni ajẹ ni iya mi, ti wọn si bẹrẹ si ni ma a lu u.

" Wọn lọ ile wa, wọn de iya mi lokun, wọn ni ti ko ba jẹwọ, awọn ko ni fi silẹ."

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Nkan tí ìyàwó gómìnà sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà 

Bakan naa ni iyawo gomina ipinlẹ Abia, Nkechi Ikpeazu tí bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa lẹyin ti o sure lati dola ẹmi arabinrin naa.

Bakan naa lo ni ki wọn gbe obinrin ọhun lọ sile iwosan.

Ikpeazu ni ìwà naa lo buru, tori wọn mọọmọ fi iya jẹ obinrin naa ni.