“Ìgbéayé wa ni Amapiano jẹ́, a kò lè ṣe ohunkóhun lẹ́yìn rẹ̀”

Àkọlé fídíò, “Ìgbéayé wa ni Amapiano jẹ́, a kò lè ṣe ohunkohun láì sí Amapiano”
“Ìgbéayé wa ni Amapiano jẹ́, a kò lè ṣe ohunkóhun lẹ́yìn rẹ̀”

Awọn eeyan orilẹ-ede South Africa ti ba BBC sọrọ lori pataki orin ati ijo Amapiano to n milẹ titi kaakiri agbaye.

Olorin to n lewaju awọn to kọ orin Amapiano naa, Dali Wong, sọ pe orin ọhun ki n ṣe ori ti awọn eeyan orilẹ-ede South n fi ṣere.

Quinton Xapo, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si DJ Atuko, to jẹ ọkan gbogi lara awọn to maa n gbe orin naa larugẹ ṣalaye fun BBC pe Amapiano tumọ si “Piano” iyẹn dùrù.

Awọn ololufẹ orin naa ni South Africa sọ pe Amapiano tumọ si igbeaye awọn nitori wọn ko le ṣe ohunkohun lai si Amapiano yii ninu rẹ.

Ẹlomiran to tun ba BBC sọrọ, Kamo Mphela, sọ pe Amapiano tun jẹ orin kan to tun maa n mu ki ijo wu ẹni to ba n gbọ orin naa lati jo.

Yatọ si awọn eeyan wọnyii, oriṣiriṣi awọn eeyan lo fẹran Amapiano, ti wọn a si maa fi fidio bi wọn ṣe n jo ijo Amapiano yii lede loju opo TickTok wọn.

Wo fidio yii fun ẹkunrẹrẹ.