Ìjọba Eko pàṣẹ kí ọlọ́pàá mú agbaṣẹ́ṣe tó ń kọ́ ilé alájà méje tó dàwó

Building collapses in Lagos

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Ijọba ipinlẹ Eko ti paṣẹ ki wọn fi ṣikun ofin mu alagbaṣe, to fi mọ awọn oṣiṣẹ to n kọ ile alaja meje kan to to dawo lagbegbe Lekki lọjọ Aiku.

Kọmiṣọna to n ri si ile kikọ ati ato ilu nipinlẹ Eko, Idris Salako lo kede bẹẹ lasiko to bẹ ile naa wo ninu atẹjade kan.

Salako ni awọn to n ṣisẹ ile ọhun ko tẹle ofin to rọ mọ ile kikọ nipinlẹ Eko, wọn si gbọdọ foju wina ofin.

O ni “Ki eeyan to kọ ile, o gbọdọ gba aṣẹ lọwọ awọn ileeṣẹ ijọba to yẹ, ko si kọ ile naa gẹgẹ bii alakalẹ iwe aṣẹ to gba.”

Salako ni iwadii ti bẹrẹ lori ile naa to dawo lati mọ eredi ohun to jẹ ki ile ọhun wo lulẹ.

Atẹjade naa ni “Awọn ọlọpaa ti n wa agbaṣẹṣe to n kọ ile naa ati gbogbo awọn to lọwọ ninu rẹ bii ayaworan ile, awọn mọlemọle to fi mọ amojuẹrọ.”

O ni ijọba ipinlẹ Eko yoo ri daju pe awọn agbaṣẹṣe ile bẹrẹ si n tẹle gbogbo ofin to rọ mọ ile kikọ ki irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ma baa waye mọ.

Lẹyin naa lo ke si awọn eeyan ipinlẹ Eko lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lori ile kikọ nipinlẹ naa fun anfani gbogbo mutumuwa.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?

Wọ́n ti yọ òkú èèyàn méjì lábẹ́ ilé alájà méje tó dàwó l’Eko

Building collapses in Lagos

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Eeyan mẹfa ti ha sabẹ ile alaja meje kan to dawo lagbegbe Sand field, to wa ni Lekki, nillu Eko.

Awọn adoola ẹmi ti wa nibi ti isẹlẹ naa ti waye lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.

Ninu atẹjade kan ti ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni Naijiria, NEMA, fi ṣọwọ si awọn akọroyin, wọn ni awọn ti ri oku eeyan meji yọ labẹ ile naa.

Lagos building collapse

Oríṣun àwòrán, lasema

Atẹjade ọhun ni “Ile alaja meje kan ti dawo ni adugbo Oba Idowu lẹba ile iwosan Avi Maria, lagbegbe ibudokọ Sand Field, ni Lekki.”

“A gbọ pe eeyan mẹfa lo ha sabẹ ile naa, awọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri l’Eko, LASEMA ati ọlọpaa ti wa nibẹ.”

“A ti ri oku eeyan meji yọ.”

Lagos building colapse

Oríṣun àwòrán, lasema

Ọga agba ajọ LASEMA, Olufemi Oke-Osanyintolu sọ pe ni kete ti awọn gba ipe pajawiri lori iṣẹlẹ naa lawọn ko awọn akọṣẹmọṣẹ adoola ẹmi lọ sibe.

O ni “Nigab ti a de ibẹ, a ba ile alaja meje naa ti wọn kọ lọwọ to ti dawo, a si gbọ pe awọn eeyan mẹfa lo ha sabẹ rẹ.”

Oke-Osanyintolu ni iṣẹ ti lọ lọwọ lati doola awọn eeyan to ha sabẹ ile ọhu to dawo.