Dunsin Oyekan sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó móríbọ́ nínú ìjàmbá ọkọ̀

Oríṣun àwòrán, Dunsin Oyekan/@Ama_Goh
Ori ti ko gbajugbaja olorin ẹmi, Dunsin Oyekan yọ ninu ijamba ọkọ kan lasiko to n lọ si ipinlẹ Oyo.
Iroyin ni ijamba ọkọ ọhun waye lasiko to n lọ ṣiṣẹ iranṣẹ niluu Ibadan.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ọkan lara awọn alabaṣiṣẹ rẹ farapa amọ ko si eyikeyi ninu awọn to n ba rinrinajo naa to ba iṣẹlẹ ọhun lọ.
Lasiko to n sọrọ lori ijamba ọkọ naa nibi to ti ṣiṣẹ iranṣẹ ninu ile ijọsin kan, Dunsin ni orun ni o n sun ninu ọkọ ayọlẹlẹ naa ki oun to ṣakiyesi pe awọn ti ko wọ abẹ ọkọ nla tirela.
O ni “Satani ko fẹ ki n wa sibi yii lonii o, ti ẹ ba ri inu ijamba ọkọ ti mo wa sibi yii lonii ẹ koni gbagbọ pe ẹsẹ ara mi ni mo fi jade ninu rẹ.”
“Mo ni ki n sun diẹ lasiko ti a n bọ nibi ki ara mi le mokun daadaaa, ohun ti mo ṣaa mọ ni pe a wa nibikan, ọkọ Jeep ti a wa ninu rẹ si ti wọ abẹ ọkọ nla tirela.”
“Bi mo ba tilẹ n rin laarin afonifoji ojiji iku... ti ẹ ba n wa iyanu, iyanu gan lo duro niwaju yin yii.”
Ta ni Dunsin Oyekan?
Oyekan jẹ ọkan lara awọn akọrin ẹmi, ti wọn tun jẹ ọdọ ti irawọ wọn n tan lasiko yii ni Naijiria ati kaakiri agbaye.
Wọn bi Dusin lọjọ karun un, oṣu kọkanla, ọdun 1984.
Lara awọn orin ti Dunsin ti kọ to milẹ titi lawujọ awọn ọmọlẹyin Krisiti ni “Do to me what you want” lọdun 2016, “Imọlẹ de” to gbe jade lọdun 2019, “More than a song” lọdun 2021, ati bẹẹ bẹẹ lọ.












