''Àwọn òbí ọkọ mí lù ọkọ ni àlùbami nígbà tó ní òun fẹ́ fẹ́mí ''

Aworan Arabinrin Ibeadua Judith Chioma

Arabinrin Ibeadua Judith Chioma ni ohun iyalẹnu lo jẹ fun oun pe oun lọ si ile ẹkọ, ti oun si tun fẹ ọkọ alalubarika pẹlu gbogbo ipenija to oun dojukọ ni ibẹrẹ aye rẹ.

Judith, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, to sẹsẹ pari agunbaniro re, lo ni ipenija ara.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu ileesẹ BBC , O ni oun padanu awọn obi oun ni ẹni ọdun mẹfa, ti oun si ro boya ile aye ti pari nitori pupọ lara awọn to ni ipenija ni wọn ko ni anfani lati lọ si ile iwe tabi ri ọkọ gidi lati fẹ wọn.

O tẹsiwaju pe nigbati ọkọ sọ fun awọn obi re pe oun lo wu lati fẹ gẹgẹ bi iyawo, lilu ni alubami ni awọn obi ọkọ fi jẹ ọkọ oun niya.

“Mo padanu ẹse nigba ti mo wa ni ọmọ ọdun mẹrin, mi ko le sọ pe nkan bayi lo sẹlẹ ati pe awọn obi mi to mọ nipa bi mo ṣe padanu ẹsẹ mi ti jade laye . ''

“Ẹgbọn lobinrin lo tọ mi dagba, to ran mi lọ si ile ẹkọ titi mo fi pari ile ẹkọ fasiti.”

aworan Arabinrin Ibeadua Judith Chioma

“Nigba ti mo pade ọkọ mi, ori foonu ni ati kọkọ sọrọ sugbọn a rira soju lẹyin ọdun meji ti a ti n sọrọ.”

Judith ni ọkọ oun jẹ ogunakan soso awọn obi rẹ, ti wọn ko si fi ọwó si pe ki awọn fẹ ara awọn.

“Inu mi dun pe ọkọ mi ko saa fun mi sugbọn nigbati ọkọ oun lọ si ile lati lọ sọ fun awọn rẹ pe emi lo wu oun lati fẹ, nise ni iya rẹ bẹrẹ si n ma pe awọn eeyan pe ki wọn gba ọmọ oun, awọn ẹgbọn rẹ lu ni alubami, koda wọn ṣe leṣe.''

“Ọkọ mi jiya gan lori mi.”

Judith ni nkan to tun ṣe ọpọlọpọ ibẹru fun oun ati ọkọ ni bi wọn ṣe bimọ to oun ba loyun nitori ipenija ara oun.

O ni pẹlu irọrun ni oun fi bi gbogbo awọn ọmọ rẹ.