Ọkọ mi ń fi oorun dùn mí ni mo ṣe ní kí wọ́n jigbé – afurasí

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Àìrìn jìnà làìrí abuké ọ̀kẹ́rẹ́, mẹ́wàá ń ṣẹlẹ̀ ní dúnníyàn.
Obìnrin kan ló ti ń kà bòròbòrò ní àgọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Akwa Ibom lórí ohun tó mọ̀ nípa bí àwọn ajínigbé ṣe jí ọkọ̀ rẹ̀ gbé nínú oṣù keje ọdún 2022.
Ìyàwó ilé náà, Joy Sunday ẹni ogójì ọdún ni ohun tí òun fi ní ki àwọn ajínigbé bá òun jí ọkọ̀ òun gbé ni nítorí ìbálòpọ̀ tó fi ń dun òun.
Sunday ní yàtọ̀ sí ìbálòpọ̀, ọkọ̀ òun kìí tún tọ́jú òun àti àwọn ọmọ ni òun ṣe lẹ̀dí àpòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ajínigbé láti bá òun jí ọkọ òun gbé kí wọ́n le bá òun gba owó lọ́wọ́ rẹ̀.
Obìnrin ló wà lára àwọn afurasí mọ́kàndínlọ́gbọ̀n tí Kọ́míṣọ́nà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Akwa Ibom, Olatoye Durosinmi fojú wọn léde fẹ́sùn ìwà ọ̀daràn kan tàbí òmíràn ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kejì, oṣù Kẹsàn-án ọdún 2022.
Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ẹ̀gbin ni òun máa ń ṣe kí òun tó le rí oúnjẹ jẹ fún ara òun àti àwọn ọmọ láti ìgbà tí ọkọ̀ òun ti pa òun àti àwọn tì láti lọ fẹ́ obìnrin mìíràn.
Bákan náà ló fi kun pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ òun ló ti parí ilé ẹ̀kọ́ girama ṣùgbọ́n kò sí owó lọ́wọ́ òun láti lè jẹ́ kí ọmọ náà tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí ọkọ̀ òun kò sì ṣetán láti rán ọmọ náà lọ sílé ẹ̀kọ́.
“Láti ojú ayé àwọn òbí ọkọ mi ni kò ti ń tọjú èmi àtàwọn ọmọ mi, ìdí nìyí tí mo fi ní kí àwọn ajínigbé bámi ji gbé.”
“Ohun tí mo ṣe ní kí wọ́n bá mi jigbé gan ni wí pé láti ọjọ́ pípẹ́ ni ọkọ mi ti súnmọ́ mi gẹ́gẹ́ bí lọ́kọláya, kò sí ohun tó jọ́ ìbálòpọ̀ láàárín wa fún ìgbà pípẹ́.”
“bẹ́ẹ̀ náà ló pa èmi àti àwọn tì láìsí ìtọ́jú bíi gbígbọ́ oúnjẹ àti àwọn nǹkan mìíràn.”
Báwo ni ọwọ́ ọlọ́pàá ṣe tẹ̀ ẹ́?
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní lásìkò tí àwọn ajínigbé ń pín mílíọ̀nù méjì náírà tí wọ́n gbà gẹ́gẹ́ bí owó ìtúsilẹ̀ láti tú ọkọ náà sílẹ̀ ni ọwọ́ ti tẹ̀ wọ́n.
Kọmíṣọ́nà Ọlọ́pàá Akwa Ibom Olatoye Durotimi ní mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà ni àwọn ajínigbé náà kọ́kọ́ bèrè kí wọ́n tó mú àdínkù bá owó náà sí mílíọ̀nù méjì.
Joy Sunday òun kò ì tíì gba kọ́bọ̀ lọ́wọ́ olórí àwọn ajínigbé náà, Udo Umoji, ẹni tó ti sálọ báyìí, kí ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tó tẹ òun.
Ó ní nígbà tí ọwọ́ tẹ àwọn ajínigbé náà ni wọ́n dárúkọ òun tí àwọn ọlọ́pàá sì wá fi póró òfin gbé òun náà.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́ láti nawọ́ gán àwọn mìíràn tó lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti gbogbo àwọn tó bá ń hu ìwà ọ̀daràn ní ìpínlẹ̀ náà.















