Wo iṣẹ́ ọ̀nà tí wọn ń lo ìṣó bíi 74,000 láti yà

Àkọlé fídíò, Nail Artist: Odunayo Fapounda ní kìí ṣe ìṣẹ́ ló mú òun máà lo ìṣó láti ya àwòrán
Wo iṣẹ́ ọ̀nà tí wọn ń lo ìṣó bíi 74,000 láti yà
Onisẹ ọna iso

Oniruuru isẹ ọna aworan yiya lo wa, eyi ti awọn eeyan maa n lo awọn eroja to wọpọ ya.

Awọn isẹ ọna aworan ti wọn fi awọn eroja bii aro ta mọ si ink, pẹnsu, irin ati pako ya si wọpọ ni awujọ wa.

Amọ aramọnda gbaa ni ọtun isẹ ọna aworan iya kan to tun de awujọ wa bayii.

Ìṣó ta fi n kan ile si ni wọn n lo bii eroja lati fi ya aworan naa.

Koda, BBC Yoruba se alapade ọkunrin kan, Odunayo Fapounda, to n lo iso lati fi ya aworan nilu Akurẹ, tii se olu ilu ipinlẹ Ondo.

Kii se isẹ tabi airikansekan lo mu ki n maa fi iso ya aworan isẹ ọna - Fapounda

Nigba to n ba wa sọrọ, Fapounda ni kii se isẹ tabi airikansekan lo mu ki n maa fi iso ya aworan isẹ ọna.

O wa fi ọwọ gbaya pe yoo nira fun oun lati fi isẹ ọna ti wọn n fi iso naa ya silẹ, nitori ifẹ nla ti oun ni si isẹ ọna naa.

Fapounda, tii se akẹkọjade fasiti, salaye pe ni ọdun marun gbako ni oun fi kọ isẹ ọna naa, ti oun si nifẹ isẹ naa gidigidi.

‘Lara ipenija to wa ninu isẹ ọna yii ni pe a maa n gba iso mọ ara wa lọwọ’

Nigba to n mẹnuba ọpọ ipenija to wa ninu isẹ ọna lilo iso lati fi ya aworan, Fapounda ni lara ipenija naa ni ki awọn seesi gba iso mọ ara wọn lọwọ.

O fikun pe isẹ ọna naa tun maa n gba akoko pupọ lati se, to si tun maa n nira pupọ lati se atunse si awọn asise ti awọn ba se lori aworan kan.

O fikun pe awọn aworan to ba jẹ olowo nla lo saba maa n gba akoko awọn.

Fapounda ni o le gba awọn bii ọsẹ kan si osu meji abọ, ki awọn to le pari yiya aworan isẹ ọna kan.

O ni akoko ti awọn yoo lo si wa lọwọ bi owo aworan ba se wọn si.

O tun ni owo tawọn fi n pese eroja fun aworan ti wọn fi iso ya yii wọn pupọ ju awọn aworan isẹ ọna yoku lọ.

‘A le lo iso 35,000, 50,000 titi de 70,000 lati fi ya aworan kan’

Onisẹ ọna iso naa si tẹsiwaju pe aworan kan le gba to lilo iso to pọ, bẹrẹ lati iso ẹgbẹrun marundinlogoji, ẹgbẹrun lọna aadọta titi de iso ẹgbrun lọna aadọrin.

Bakan naa lo ni awọn eeyan maa n fi ẹnu yẹpẹrẹ tabuku aworan oniso, ti ọpọ awọn eeyan ti awọn ba si ya aworan wọn, ni kii mọ riri rẹ.

O ni owo tasọrẹ ni iru awọn eeyan yii ma n ko le isẹ naa lori eyi to mu ki ọpọ eeyan maa lero pe isẹ naa ko le mu ki awọn la nile aye.