Aya ààrẹ àná rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá he lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tọ̀kọ rẹ̀ lọ sẹ́wọ̀n ọdún méjìla

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile ẹjọ ti ju iyawo olootu ijọba orilẹ-ede Malaysia nigba kan, Najib Razak, si ẹwọn ọdun mẹwaa fun ikọọkan ẹsun mẹta ti wọn fi kan an.
Ile ẹjọ fidirẹ mulẹ pe Rosmah Mansor jẹbi bibeere fun owo ẹyin, to si tun gba owo ẹyin lọwọ ileeṣẹ kan ki wọn le ri iṣẹ agbaṣe ti owo rẹ to 1.25bn Ringgit ($279m,
Ile ẹjọ giga naa sọ pe ẹẹkan naa ni yoo ṣe ẹwọn mẹtẹẹta.
Idajọ naa waye lẹyin ọjọ diẹ ti wọn dajọ ẹwọn ọdun mejila fun ọkọ rẹ nitori iwa ibajẹ.
Arabinrin Mansor, to jẹ ẹni aadọrin ọdun gbajumọ fun lilo awọn nkan ati ẹṣọ ara olowo iyebiye nigba ti ọkọ rẹ fi wa ni ipo.
Lọdun 2018 ti awọn ọlọpaa orilẹ-ede Malaysia yabo awọn ile oun ati ọkọ rẹ, wọn ri ẹ̀gbà ọrun kan ti wọn fi goolu ati dayamondi ṣe eyi ti owo rẹ jẹ $ 1.6m, ade ori obinrin mẹrinla, ati 272 baagi alafẹ Hermes.
Rosmah ni oun ko jẹbi ẹsun naa, to ṣi sọ fun adajọ to ju si ẹwọn, Onidajọ Zaini Mazlan, pe ibanujẹ ni nkan to ṣẹlẹ nile ẹjọ jẹ fun oun.
Pẹlu omije loju ni Rosmah fi sọ eyi fun adajọ lẹyin ti igbẹjọ pari, gẹgẹ bu ileeṣẹ iroyin Reuters ṣe sọ.
“Ko si ẹnikẹni to ri mi pe mo gba owo, ko si ẹni to ri pe mo n ka owo... sugbọn to ba jẹ pe nkan ti ile ẹjọ fẹ niyii, mo fi gbogbo rẹ le Ọlọrun lọwọ.”
Ẹsun mẹtadinlogun miran tun wa ti Rosmah n koju lori aisan owo ori ati kiko owo lọ silẹ okeere lọna aitọ.
Yatọ si ẹwọn, ile ẹjọ tun ni ko san 970m owo ringgit.
Ẹsun mẹtadinlogun miran tun wa ti Rosmah n koju lori aisan owo ori ati kiko owo lọ silẹ okeere lọna aitọ.
O ni oun ko jẹbi awọn ẹsun naa.
Awọn to rojọ tako Rosmah nile ẹjọ sọ pe o beere fun 187.5m ringgit owo ẹ́yìn, to si gba 6.5m, lọwọ ọga ileeṣẹ kan to gba iṣẹ agbaṣe fun ipese ina Solar.
Ṣaaju lo ti sọ pe amugbalẹgbẹ oun kan ati awọn oṣiṣẹ ijọba kan to mọ nipa iṣẹ agbaṣe naa lo parọ ẹsun naa mọ oun, ṣugbọn adajọ sọ pe awijare rẹ ko lẹsẹ nilẹ rara.
Agbarijọpọ ẹgbẹ araalu kan gboriyin fun idajọ naa, ti wọn si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi idajọ ododo fun awọn eniyan Malaysia.
Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Mandeep Singh, sọ fun BBC pe lootọ ni Rosmah le pe ẹjọ kotẹmilọrun, ṣugbọn ireti awọn ni pe yoo papa darapọ mọ ọkọ rẹ ni ẹwọn.
Ko ti i daju igba ti Rosmah yoo bẹrẹ ẹwọn rẹ, nitori pe o ti ri iwe aṣẹ gba lati ma bẹrẹ titi idajọ yoo fi waye lori ẹjọ kotẹmilọrun to pe.

















