Kí ní ọba Irele l‘Ondo ṣe, tí Akeredolu fi ní kí ọlọ́pàá lọ gbe?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti paṣẹ fun kọmisọna ọlọpaa, Oyediran Oyeyemi, lati fi panpẹ ọba mu Olofun ti Irele, Ọba Oloworiyibi Ademola Idowu.

Ijọba ibilẹ Irele ni ipinlẹ Ondo ni Ọba naa jọba le lori.

Gomina Akeredolu ni Ọba Oloworiyibi ṣe ju ara rẹ lọ, ti oun ko si fi ọwọ si iṣejọba naa tabi fun ẹnikẹni ni ipo Olofun ti ilu Irele.

Oṣu to kọja ni Ọba Ademola naa gori itẹ baba rẹ gẹgẹ bi ọba.

Amọ awọn kan fi aidunnu wọn han, ti wọn si kọ lẹta ranṣẹ si ijọba wipe magomago wa ni ọna to gba de ade ọba.

Ninu lẹta ti gomina kọ si ileeṣẹ ọlọpaa naa lo ti ṣapejuwe bi ọba naa ṣe jẹ gẹgẹ bi aimọ ala ẹni ati ọna ti ko ba ofin mu.

Gomina Akeredolu ni iyansipo rẹ le da rudurudu silẹ ni agbegbe naa, ti ohun to ti n dara nibẹ tẹlẹ si le tu ka.

Atẹjade ti Akeredolu fisita

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi/Facebook