N kò ní kọyán olùdíje kankan kéré lásìkò ìbò, mo kórira ìrẹ́jẹ - Buhari

Àwòrán Ààrẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ni oun ko ni fi aye gba oludije kankan lati fi ọwọ ọla gba awọn oludije yoku loju tabi lo dukia adani rẹ fi rẹ́ ẹnikẹni jẹ saaju ibo 2023.

Buhari ni nibayii to ku oṣu mẹfa tí idibo yoo waye, awọn ọmọ orílẹ̀èdè yii yoo mọ rírí isejọba rẹ.

Ninu atẹjade kan tí agbẹnusọ aarẹ, Femi Adeshina fisita fawọn akọroyin ni Aarẹ ti sisọ loju ọrọ yii nigba to n gba alejo awọn gomina niluu Abuja.

Aarẹ ni gẹgẹ bi ibo awọn araalu ṣe fọhun ninu eto ìdibo gomina ni Ipinlẹ Anambra, Ekiti ati Osun.

Bẹẹ naa ni yoo ṣe waye ninu eto ìdibo lọdun 2023.

Aarẹ Buhari tẹsiwaju pe isejọba oun yoo fun gbogbo ẹgbẹ oselu ni anfani, tí oun ko si ni kọyan oludije kankan kere lati fi ṣafihan pe ìjọba oun lodi sì irẹjẹ.

Laarin osu mẹfa, ọmọ Naijiria yoo mọ riri isejọba mi - Buhari

Buhari sọ siwaju pe "Mo fẹ ki gbogbo ọmọ orílẹede Naijiria mọ pe a ni ibọwọ fun wọn.

Ti a ba si fẹ ki wọn mọ bẹẹ, ani lati fun wọn ní anfani lati yan ẹgbẹ oselu to ba wu wọn.

Gbogbo wa la ri nnkan to waye ni Ipinlẹ Osun, Ekiti ati Anambra, eyi to fun mi ni igbagbọ pe aseyọri tí ń de ba isejọba wa.

" A ko ni gba fun ẹnikẹni lati lo ọwọ agbara fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria.

Laarin oṣu mẹfa, awọn ọmọ Orilẹede yii yoo mọ rírí isejọba ẹgbẹ oselu APC.