Àlàyé rèé lórí ìdí tí mo fi dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú - Dele Odule

Dele Odule

Oríṣun àwòrán, Dele Odule/Instagram

Gbajúgbajà àgbà ọ̀jẹ̀ òṣèré tíátà, Dele Odule ti ṣàlàyé ìdí tó fi darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú.

Dele Odule salaye pe ẹgbẹ́ òṣèlú tí òun darapọ̀ mọ wa láti mú ìdágbàsókè bá ìlú, ìpínlẹ̀ òun àti pàápàá eré tíátà.

Agba osere naa sisọ loju ọrọ yii lasiko to ba BBC Yoruba sọrọ lori idi to fi darapọ mọ ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ogun.

Ó ní ìdí rẹ̀ gan nìyí tí òun fi lọ darapọ̀ mọ́ òṣèlú ní ẹsẹ̀ kùkú níbi tí òun yoo ti le kó ipa tó lòòrìn sí ìgbé ayé àwọn ènìyàn.

Ó tẹ̀síwájú wí pé àìsí níbẹ̀ ni àìbáwọn dásí ni ọ̀rọ̀ ọ̀hún jẹ́ nítorí tí ènìyàn kò bá máa kópa nínú òṣèlú kò ní ní àǹfàní láti dá sí àwọn tó bá yẹ ní ṣíṣe nípa àwùjọ tó.

Odule ní ó pọn dandan láti tọ́ àwọn tó wà nípò òṣèlú sọ́nà lórí àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ kí wọ́n gbé kí ìlú le fi dára ju bó ṣe wà lọ.

Bákan náà ló ní eré tíátà àti eré ìdárayá lápapọ̀ kún ìdí rẹ̀ gan tí òun fi gbégbá láti darapọ̀ mọ́ òṣèlú.

Ó fi kun pé ìdí tí òun fi darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP gan ni wí pé gbogbo àwọn tí wọ́n ń wá ìlọsíwájú eré ìdárayá ní ìpínlẹ̀ Ogun, ẹgbẹ́ PDP ni wọ́n wà.

Odule ní ká ní wí pé òun ní agbára láti dá ẹgbẹ́ òṣèlú sílẹ̀ dípò kí òun darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ PDP, òun yóò ṣe bẹ́ẹ̀ àmọ́ ipá òun kò lè ka.

“Ti mi ò bá darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú kankan mo kàn ma pariwo lásan láti ìta láti bèrè fún òun tí a bá fẹ́ ni.”

‘Ẹnikẹ́ni kò fún mi lówó láti darapọ̀ mọ́ òṣèlú’

Dele Odule tún làá mọ̀lẹ́ pé, kìí ṣe nítorí owó tàbí láti wá ipò kankan ni òun ṣe gbégbá òṣèlú ní àsìkò yìí.

Ó ní níbi tí ọjọ́ orí òun dé báyìí, òun kò nílò owó ẹníkẹ́ni láti ṣe òṣèlú nítorí gbogbo òun tí ènìyàn fi ń gbé ayé se, ni òun ti rí ní ìdí iṣẹ́ tíátà.

“Mi ò gbowó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, mi ò dẹ̀ darapọ̀ mọ́ òṣèlú nítorí kí ẹnikẹ́ni le fún mi ní owó.”

‘Ìwà mi kò lè yípadà láéláé torí mó jẹ́ olóṣèlú’

Odule sọ síwájú pé, ìwà òun kò lè yípadà sí ohun tí àwọn ènìyàn mọ̀, kí òun tó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú.

Ó ní lára ohun tí òun gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí ènìyàn fi lè ṣe àṣeyege nídìí òṣèlú, ni fífi òótọ́ inú ṣe òṣèlú.

Ó fi kun pé òun ti ṣétan láti fi òótọ́ inú ṣe òṣèlú láì fi ẹ̀tàn ṣe rárá.

Àgbà òṣèré náà ní lára òun tí òun yóò gbájúmọ́ ni láti máa ṣe ìtọ́sọ́nà fún àwọn tó wà nípò .

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní tí àwọn nǹkan tí wọ́n bá ń ṣe nínú ẹgbẹ́ kò bá tẹ́ òun lọ́rùn, òun yóò máa pe àkíyèsí àwọn tó bá wà nípò agbára si.

“Àmọ́ tí wọ́n kò bá gbọ́ sí mi lẹ́nu lẹ́sẹ̀ kan, ni máa fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀.

Dele Odule, Adebutu ati oloselu miran

Oríṣun àwòrán, Dele Odule/Instagram

Mo lè kúrò nínú òṣèlú, tó bá ma pa iṣẹ́ tíátà mi lára - Odule

Dele Odule ní tí ọ̀kan nínú àwọn iṣẹ́ tí òun yàn láàyò bá ma pa èkejì lára, òun ṣetán láti fi ọ̀kan sílẹ̀ fún ọ̀kan.

Ó ní nígbà tí kìí ṣe owó ló ń gbé òun ṣe òṣèlú, kò sí ohun tó ní kí òun má kúrò nínú ẹgbẹ́ náà, tí òun bá ri wí pé ó ti fẹ́ máa tàbùkù òun, pàápàá lọ́dọ̀ àwọn olólùfẹ́ òun.

“Tí mo bá dé ibẹ̀, tí mo bá sọ tèmi gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ yẹn, tí wọ̀n kò bá gbọ́, mà á dẹ̀ kúrò níbẹ̀.”

“Ṣùgbọ́n ayé maa mọ̀ wí pé mó sọ tèmi gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ báyìí nígbà tí mo darapọ̀ mọ́.”

Bí ìgbàságbo Dele Odule sínú ẹgbẹ́ PDP ní Ogun se waye rèé

Aworan

Oríṣun àwòrán, Dele Odule/Instagram

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe gbajugbaja oṣere tiata, Dele Odule, lọjọ isẹgun darapọ mọ ẹgbẹ oselu People's Democratic Party ni Ipinlẹ Ogun.

Isẹlẹ yìí waye níbi ayẹyẹ ẹgbẹ oselu naa to waye niluu Ìjẹ̀bú-Ode ni Ipinlẹ Ogun.

Alaga ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ogun, Sikirulahi Ogundele ati oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP, Hon Ladi Adebutu lo tẹwọ gbajugbaja osere tiata naa

Bakan naa ni igbakeji oludije sipo gomina nipinlẹ Ogun labẹ asia PDP, Adekunle Akinlade pẹlu ogunlọgọ ọmọ ẹgbẹ naa ko gbẹyin nibi ayẹyẹ naa.

Inu wa dun lati ki Dele Odule kaabọ sagbo PDP - Adebutu

Odule, ẹni to jẹ ọmọ bibi ìlu Oro ni Ipinlẹ Ogun, ni oun setan lati ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ oselu PDP lati ri pe wọn borí eto ìdibo ti yoo waye lọdun 2023.

O ni ni papajulọ, eto ìdibo gomina ipinlẹ Ogun.

Lori opo ayelujara Instagram rẹ, Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP, Hon Ladi Adebutu ni inu awọn dun pupọ lati kí Dele Odule kabọ sinu ẹgbẹ oselu People's Democratic Party ni Ipinlẹ Ogun.

"Loni mo darapọ alaga ẹgbẹ oselu PDP lati kí ọmọ ipinlẹ rere Dele Odule kabọ sinu ẹgbẹ oselu People's Democratic Party."

Dele Odule wọ PDP

Oríṣun àwòrán, Dele Odule/Instagram