Ìgbìmọ̀ tó gbọ́ awuyewuye ìbò ààrẹ ní Kenya bẹ̀rẹ̀ ìjọ́kòó

Igbimọ to n gbọ ẹjọ awuyewuye ibo ni Kenya

Ileẹjọ giga lorilẹede Kenya tí bẹrẹ agbeyẹwo awọn awuyewuye to nii se pẹlu agbeyẹwo esi ìdibo aarẹ.

Adajọ agba lorilede Kenya, Martha Koome, to lewaju igbẹjọ ọhun, ti wọgile ẹhonu meji, to si gba meje wọle.

Adajọ naa ni awọn ẹsun meji to wọgile naa lo fara pẹ meje to ku nitori ẹhonu kannaa ni wọn tọkasi ninu wọn, ti wọn si tun n bẹbẹ fun awijare to jọra.

Bakan naa nile ẹjọ ọhun tun kọ lati tẹwọ gba iwe ẹbẹ mẹta to fi mọ ẹbẹ William Ruto eyi to n beere pe ki mase faaye gba ẹgbẹ awọn agbẹjọro lorilẹede Kenya laaye lori igbẹjọ naa.

Ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye ibo ni Kenya ti se agbekalẹ koko mẹsan ti yoo fi sepinnu lori idajọ rẹ ti yoo gbe kalẹ lọjọ Karun osu Kẹsan to n bọ.

Aba mẹsan ni ileẹjọ tẹwọ gba lọsẹ to kọja, eyi to n pe fun pe ki wọn da esi ìdibo to gbe William Ruto wọle danu.

Agbeyẹwo esi ibo naa ni yoo ṣe iwadi lori awọn aba ohun, ti ileẹjọ yoo si kede ipinnu laipẹ.

Lara awọn agbeyẹwo ti wọn yoo ṣe ní boya alaga fun ajọ eleto ìdibo, Wafula Chebukati tapa si ofin gẹgẹ bi o ṣe kede Ruto pe oun lo borí eto ìdibo.

Bakan naa ni ileẹjọ yoo ṣe agbeyẹwo awọn igun meji ti wọn kọwe ransẹ, igun kan bẹrẹ pe ki wọn esi ìdibo danu tí awọn miiran si n pe fun pe ki ileẹjọ fi ofin kede esi ìdibo pe o lọ ní alaafia.

Adajọ meje ni yoo dari agbeyẹwo lori awọn aba lori esi ìdibo to waye lọjọ kẹsan oṣu kẹjọ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Awọn adajọ naa ni jinroro lori awọn aba naa ki wọn to kede lori Igbẹjọ naa.

William Ruto naa fi atẹransẹ sì ileẹjọ, to si n pe fun pe ki wọn osisẹ ajọ eleto ìdibo to wa lara awọn buwọlu iwẹ tí alakato rẹ fi pe lẹjọ.

Awọn yoo pinnu boya ki wọn tun ibo naa ka gẹgẹ bii Odinga ṣe pe fun.

Agbeyẹwo naa ni yoo se riri awọn eeyan Orilẹede Kenya lori ẹrọ momaworan lati fun wọn ní anfani lati bi Igbẹjọ naa ṣe lọ.

Odinga ní ko tẹwọ gba esi ìdibo, tí ó sì bu ẹnu atẹlu bi ikede naa ṣe waye. O ni rogbodiyan bẹẹ silẹ laarin awọn ajọ eleto ìdibo ati bi alage ajọ eleto ìdibo ṣe kuna lati salaye bí o ṣe de ìparí ibo.

Alaga ajọ eleto ìdibo,Wafula Chebukati kede William Ruto gẹgẹ bii aarẹ tuntun pẹlu ibo toto milọnu meje ati ẹgbẹrun kan tí Odinga sí ní milọnu mẹfa ati ẹgbẹrun mẹsan ibo.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kìnìún fa ọkùnrin tó fo odi wọ inú ọgbà rẹ̀ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ní Ghana

Kiniun naa ati awọn ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, FORESTRY COMMISSION GHANA

Awọn alaṣẹ ni Ghana ti n ṣe iwadii lẹyin ti kiniun fa ọkunrin kan ya pẹrẹpẹrẹ to si ku u, ni ọgba ẹranko kan to wa nilu Accra, olu ilu orilẹ-ede naa.

Arakunrin naa ti wọn ko tii dagba pupọ, ku nitori ọgbẹ ti eyin kiniun da si lara lọjọ Aiku.

Iroyin sọ pe ọkunrin naa fo odi ọgba ẹranko naa wọle ni, ko to o bọ sọwọ kiniun.

Amọ awọn alaṣẹ ọgba naa sọ pe awọn fura si ọkunrin naa pe o ṣeeṣe ko jẹ awọn ọmọ kiniun meji kan, ti iru wọn ko wọpọ lo fẹ ẹ jigbe.

Oṣu Kọkanla, ọdun to kọja ni wọn bi awọn ọmọ kiniun naaa ti awọ wọn jẹ funfun. Lati igba naa si ni oju ọpọ ti wa lara wọn.

Ọpọlọpọ awọn arinrinajo igbafẹ si lo ma n wa sibẹ lati wa a wo wọn.

Awọn ọmọ kiniun naa

Oríṣun àwòrán, FORESTRY COMMISSION GHANA

Àkọlé àwòrán, Lati ọdun to kọja ti wọn ti bi awọn ọmọ kiniun naa, ni ọpọ eeyan ti ma n wa wo wọn nitori awọ ara wọn to yatọ

Abo kiniun kan ati akọ kiniun kan, pẹlu awọn ọmọ wọn mejeeji ọhun, lo jọ wa ninu ile ti wọn kọ fun wọn nigba ti iṣẹlẹ naa waye.

Igbakeji minisita fun ọrọ ilẹ ati awọn nkan alumọni, Benito Owusu Bio, sọ fun awọn akọroyin pe “awọn kiniun naa ni ọmọ, nitori naa ni wọn fi ma n ro pe o gbiyanju lati ko awọn ọmọ naa ni, to ba sunmọ ibugbe wọn ju boṣe yẹ lọ”.

Awọn alaṣẹ sọ pe odi to ga to ẹsẹ bata mẹwaa, ni arakunrin to ti di oloogbe naa kọkọ fo wọ inu ọgba ẹranko naa, ko tun to o fo odi miran to ga to ẹsẹ bata ogún wọ ibi ti awọn kiniun naa wa.

Awọn ọlọpaa si ti bẹrẹ iwadii nkan to le jẹ erongba ọkan oloogbe naa, ati nakn to fa bi kiniun ṣe kọlu u.

Bakan naa ni wọn ti ti ọgba ẹranko naa, Accra Zoo, pa fun asiko diẹ nitori iṣẹlẹ buruku naa, ti wọn si tun ti gbe oku ọkunrin naa lọ si mọṣuari.