"Àna mi, ọmọ rẹ̀ méjì ló kú pẹ̀lú ọkọ́ ìyàwó tuntun àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́jọ́ kejì ìgbéyàwó"

Mo fura pé wọn fi májèlé sínú oúnjẹ àwọn tó wá ṣegbeyàwó ni - Ósojúmikòró

Ọkọ iyawo tuntun to ku ati aya rẹ

Oríṣun àwòrán, OBINNA DIEKE

Iṣẹlẹ ìbanujẹ ni iṣẹlẹ to sẹlẹ si awọn eeyan Obollo-Eke, Udenu ati Aka-Utara ni agbegbe Adani ni ìjọba ibilẹ Uwani ni Ipinlẹ Enugu.

Abule yii ni eeyan mẹfa ti padanu ẹmi wọn níbi ayẹyẹ igbeyawo kan.

Lara awọn to padanu ẹmi wọn ní ọkọ ìyàwó to ṣe ajọyọ lọjọ naa, ti orukọ rẹ jẹ Obinna Dieke.

Iyawo rẹ, Nebechi sì wa nile wosan níbi to ti ń gba itọju pẹlu awọn mẹjọ miiran.

Obinna Dieke lo wa lati Makudi niipinlẹ Benue, to jẹ onisowo, ko to jẹ Ọlọhun nipe.

Aburo oloogbe, Chinedu Dieke, ẹni to ba BBC sọrọ ni àna òun, Joseph Ogbonna pẹlu ọmọ rẹ meji lo ba isele lọ.

Chinedu tẹsiwaju pe aburo oun lobinrin Goodness ati iya awọn wa nile iwosan, níbi tí wọn ti gba itọju.

Ósejumikoro lati abule Adani ni oun fura pe wọn fi majele sì oúnjẹ awọn mọlẹbi naa sugbọn iwadi si n lọwọ.

Nkan tí Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá sọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà 

Kọmisona Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Enugu, Ahmed Ammani tí pa a lasẹ pe ki iwadi bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa. Ninu atẹsita kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa fi sọwọ sì awọn akọroyin, Daniel Ndukwe ni Kọmisona rọ awọn araalu lati fọwọsowọpọ pẹlu ìjọba lori iwadi wọn nipa iṣẹlẹ naa. Kọmisona ni awọn ti bẹrẹ iwadi ni kete tí awọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa.

Àlàyé rèé lórí bí wọn ṣe rí òkú ọkọ ìyàwó àti èèyàn márùn-ún míì

Kò dín ní ènìyàn mẹ́fà tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn lẹ́yìn tí wọ́n kópa níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan ní ìlú Akutara, agbègbè Adani ní ìjọba ìbílẹ̀ Uzo-Uwani, ìpínlẹ̀ Enugu.

Lára àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn náà ni ọkọ ìyàwó gangan, Obinna Dike ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n, tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tẹ̀lé lọ sí ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó ọ̀hún.

Ọ̀pọ́ àwọn eeyan mìíràn ló sì tún wà ní ilé ìwòsàn báyìí níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́.

Lára àwọn mẹ́jọ mìíràn tí wọ́n ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn ni ìyàwó gan -an fúnra rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Enugu, Daniel Ndukwe fi tó àwọn akọ̀ròyìn létí, ó ní lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹjọ̀ ni ìgbéyàwó ní ìlànà ìbílẹ̀ wáyé kí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà tó ṣẹlẹ̀.

Ndukwe ní lẹ́yìn ìgbéyàwó náà ni ọkọ ìyàwó àti àwọn ènìyàn rẹ̀ padà sí Adani láti túbọ̀ tẹ̀síwájú pẹ̀lú ayẹyẹ wọn.

Ó ní nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì tí wọn kò rí kí ọkọ ìyàwó àti àwọn ènìyàn rẹ̀ márùn-ún jáde kúrò nínú yàrá tí wọ́n sùn, ni àwọn ara ilé já ilẹ̀kùn wọlé.

Ó ṣàlàyé wí pé nígbà tí wọ́n fi ma já ilẹ̀kùn wọlé ni wọ́n bá àwọn ènìyàn ọ̀hún níbi tí wọ́n ti ń pọ̀kàkà ikú, tí wọ́n sì ń pọ nǹkan funfun jáde lẹ́nu.

Kí àwọn mẹ́fẹ́ẹ̀fà ọ̀hún tó dé ilé ìwòsàn ni wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn

Ndukwe fi kun pé nígbà tí wọ́n fi máa gbé àwọn ènìyàn mẹ́fẹ́ẹ̀fà naa dé ilé ìwòsàn, wọ́n ti jẹ́ Ọlọ́run nípè.

Ó ní wọ́n ti wà ní yàrá ìgbóòkúsí fún àyẹ̀wò àti ìwádìí tó péye.

Bákan náà ló ní àwọn tó wà ní ilé ìwòsàn ti ń gba ìtọ́jú, tí ara wọn sì ti ń balẹ̀.

Ó fi kun pé Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Enugu, Ahmed Ammani ti pè fún ìwádìí tó péye láti fi ìdí ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an múlẹ̀.

Nígbà tó ń bá àwọn ẹbí olóògbé kẹdùn, ó rọ àwọn ènìyàn ìlú náà láti fi ẹ̀sọ̀ ṣe, kí wọ́n sì ran àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ lórí ìwádìí wọn.