Ọlọ́pàá yìnbọn pa olùfẹ̀hónúhàn 19 ní Madagascar, 21 farapa yánayàna

Madagascar police

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O kere tan, eeyan mọkandinlogun lo ti ku, nigba ti awọn mọkanlelogun mii farapa yanayana lẹyin ti awọn ọlọpaa ṣina ibọn bolẹ fun awọn oluwọde ni Madagascar.

Awọn eeyan naa n ṣe ifẹhonunan lori bi awọn eeyan kan ṣe ji ọmọ kekere kan to jẹ afin gbe lọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn to farapa ti wa nile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.

Ileeṣẹ iroyin AFP jabọ pe awọn olufẹhonuhan kan ti iye wọn to nnkan bii ẹẹdẹgbẹta pẹlu ada lọwọ wọn gbiyanju lati wọ agọ ọlọpaa ti wọn ko awọn afurasi mẹrin to ji ọmọ naa gbe si ki ọrọ ọhun to di iṣu ata yanyan.

A ko jẹbi iṣẹlẹ naa – Ileeṣẹ ọlọpaa

Adari ileeṣẹ ọlọpaa, Andry Rakotondrazaka, sọ fun awọn akọroyin pe awọn ọlọpaa ko jẹbi bi wọn ṣe dana ibọn ya awọn olufẹhonuhan naa nitori wọn lẹtọ labẹ ofin lati daabo ara wọn lọwọ ewu.

Ijọba ti gbe iwadii dide lati wa okodoro iṣẹlẹ naa.

anpaa Madagascar

Titi di asiko ti a ko iroyin yii jọ, ko sẹni to le sọ irufẹ ipo ti ọmọ afin naa wa, amọ ijọba ni awọn janduku ti ṣekupa iya rẹ.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn eeyan yoo ji afin gbe ni ilẹ adulawọ nitori igbagbọ pe ẹya ara wọn wa lara awọn ohun elo ti wọn fi n pelo oogun owo.