Wo ọ̀pọ̀ èèkàn NURTW tó kú láìtọ́jọ́ láàrin ọdún kan

Oríṣun àwòrán, Other
Ni ọjọ Aiku ni iroyin jade pe awọn janduku kan ti ṣa alaga awọn ọlọkọ ero ni ibudokọero Mile 12, Sulaimon Ọnaọlapọ ti ọpọ mọ si ‘Arikuyẹri’ pa.
Iroyin yii ti fa ọpọ ikayasoke ati hilahilo lawọn agbegbe kan nilu Eko.
Sugbọn gẹgẹbi ọpọ ṣe mọ, igba yii kọ ni akọkọ ti wahala ọlọkọ ero yoo di eyi ti yoo ran awọn eekan ẹgbẹ naa lọ si ọrun alakeji.
Laarin ọdun kan sẹyin awọn aṣiwaju ẹgbẹ yii, ti rogbodiyan awakọ ero ti ran sọrun alakeji kii ṣe ẹyọ kan tabi meji.
Eyi lo mu ki BBC Yoruba se atupalẹ ati akojọpọ awọn aṣiwaju ẹgbẹ awakọ ero to ti ku laitọjọ laarin ọdun kan sẹyin.
Akurẹ, ipinlẹ Ondo. Ọjọ kẹjọ oṣu kẹta ọdun 2021
Eeyan kan ku nilu Akurẹ lasiko rogbodiyan laarin awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ ero NURTW nipinlẹ naa.
Wahala naa waye lagbegbe Ọja ọba ni opopona Ọba Adeṣida.
Ademọla Adegboyegun ni wọn pe orukọ oloogbe naa, ẹni ti wọn yinbọn fun un gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, lagbegbe Old Garage nilu Akurẹ.
Agboju, Eko Ọjọ kẹsan an oṣu keje ọdun 2021

Oríṣun àwòrán, other
Samuel Kayọde ti ọpọ mọ si Epokinkin, lo jẹ igbakeji Alaga ẹgbẹ awakọ ero ni ipinlẹ Eko.
Agbegbe Agboju nipinlẹ Eko ni wọn pa a si lasiko to wa nibi eto ipolongo ẹgbẹ oṣelu APC kan.
Awọn alaṣẹ ẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ Eko sọ pe, n ṣe lo n gbiyanju lati daabo bo oloṣelu kan, Wale Yusuf lasiko ti wọn fi pa a.
Osogbo, ipinlẹ Osun. Ọjọ karun un oṣu kẹjọ dun 2022
Awọn agbebọn kan yinbọn pa ọkan lara awọn korikosun alaga ẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ Ọṣun ti ọpọ mọ si Spanal.
Agbegbe oke ijẹtu ni gareji Ilesha nilu Osogbo ni wọn ti pa oun pẹlu ọmọ rẹ obinrin, ọmọ ọdun meje.
Lẹyin wakati diẹ ti iyawo rẹ bimọ tuntun ni iroyin sọ pe iṣẹlẹ yii waye.

Oríṣun àwòrán, other
Osogbo, ipinlẹ Ọṣun. Ọjọ kọkanlelogun, Oṣu kẹjọ ọdun 2022
Ali Kazeem, alaga ẹgbẹ ọlọkọ ero NURTW nilu Apomu dagbere fun aye ni ogunjọ oṣu kẹjọ ọdun 2022.
Awọn agbebọn kan lo yinbọn fun un lagbegbe Oke- Alfa nilu Apomu.
Iroyin sọ pe awọn to pa a wa ninu ọkọ meji kan ti wọn si tẹ le ọkọ rẹ to jẹ ọkọ ayọkẹlẹ Toyota corola pẹlu nọmba APM 203AA de ibi ti wọn ti dabu rẹ ti wọn si wọ ọ sita ninu ọkọ ti wọ ṣaa laṣapa ni nnkan bii agogo mẹjọ si mẹsan alẹ jọ naa.
















