Wọ́n lẹ̀ mí lókò nígboro torí àwòrán ìhòhò mi tó lu sórí ayélujára - Òṣeré tíátà

Oríṣun àwòrán, Safiya Yusuf
Oṣere tiata kan ni ẹkun ariwa, lagbo Kannywood, Safiya Yusuf, ti awọn eeyan ariwa Naijiria mọ sì 'Safara'u,' ti sọrọ lori riri rẹ lẹyin ti aworan ihoho rẹ bọ sì orí ayelujara.
Safiya ni odidi oṣu mẹta ni oun lo ninu ile lẹyin ti foran naa bọsi ori ayelujara.
Safiya lo di ilumọọka lẹyin to kopa ninu ere sinima Kwana Casa 'in'.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News, Safiya salaye pe oun ti gba ìsinmi lẹnu isẹ tiata, lati ni asiko fun isẹ orin tí oun yan layo.
O tẹsiwaju pe lẹyin iṣẹlẹ naa ni ọpọlọpọ eeyan bẹrẹ si bu oun, ti wọn ba ti pade oun níbi kibi.
‘N ko le jade nile fun osu mẹta tori itiju nigba ti aworan ihooho mi jade sita’
"Igba ti fọnran ihoho mi bọ sorí ayelujara jẹ igba manigbagbe ninu igbesi aye mi nítorí mo lo oṣu mẹta ninu ile lai fi oju gaani ilẹkun abawọle wa.
Mo kan wa ninu ile."
"Nigba ti mo wa ṣe ọkan akin lati bọ sita, ọpọlọpọ eeyan lo bẹrẹ si n ma bu mi, koda mo ranti ẹni kan to lẹ mi ni oko.
"Safiya tẹ siwaju pe ti ko ba ṣe ọpẹlopẹ awọn mọlẹbi oun ti wọn duro ti oun, omi o ba pọju ọka lọ.
"Mo dupẹ gan-an lọwọ awọn mọlẹbi mi nítorí pe awọn ni wọn ran mi lọwọ nigba isoro lati bọ ninu rogbodiyan naa.
Awọn ẹgbọn mi, awọn obi mi ati gbogbo mọlẹbi pata ni wọn duro timi.”
Safiya ni ko si nkan ti o jọ mọ pe wọn le oun kuro lawujọ awọn oṣere tiata, ó ni fura oun ni oun gba ìsinmi fun igba diẹ.
Ilegbe Sọ́jà ní mó gbé dàgbà, eyi ló fà bí mó ṣe má múra‘

Oríṣun àwòrán, Safiya Yusuf
‘Awọn ọkunrin ni mo ba sere dagba, lo se jẹ pe awọn ọkunrin ni mo n ba kọrin’
Safiya sọrọ imura pe lọpọ igba, ko wu oun lati ma wọ asọ ibile nítorí pe wọn ko fi kọ oun lati kekere.
O ni imura asa oyinbo lo mọ oun lara julọ.
Safiya tun salaye idi to fi jẹ pe awọn ọkunrin nìkan ni oun ba kọrin papọ.
O ni kii ṣe wipe oun ko fẹ ba obinrin kọrin sugbọn oun ko ti rí obìnrin ti yoo ba oun kọrin papọ bayii.
"Emi ko ti rí obìnrin tí ma ba kọrin, nítorí rẹ ni lo fi jẹ pe ọkùnrin nikan ni mo n ba kọrin.
"Alaye miran ni wipe pupọ lara awọn tí a jọ dagba lo jẹ ọkùnrin, emi nkan ni obìnrin.
Nítorí rẹ ni ko fi jẹ ohun iyalenu fun mi."
















