Ọwọ́ Ọlọ́pàá tẹ àlùfáà ìjọ tó fun ọmọ ọdún méjìlá lóyún

Oríṣun àwòrán, OGUN POLICE
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tí nawọ gan alufaa ijọ The Light House Gospel Church to wa ni Oluwo, Owode Ẹgba, Michael Abiodun fẹsun wi pe o fun ọmọ ìjọ, ọmọ ọdun mejila loyun.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si BBC News Yoruba, ni ọwọ tẹ alufaa naa lẹyin ti awọn mọlẹbi ọmọdébìnrin fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti.
Oyeyemi ni iya ọmọ ọhun darapọ mọ ile ìjọsìn naa lẹyin to padanu awọn ọmọ rẹ obìnrin meji sọwọ iku òjijì.
O ni lati fi opin iṣẹlẹ naa, Arabinrin naa morile ile jọsin lati gba adura fun idabobo awọn ọmọ yooku.
Oyeyemi tẹsiwaju pe ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, iya ọmọ naa salaye pe alufaa Abiodun ransẹ si oun pe ki oun ni kí ọmọ oun wa ri oun nítorí pe Oluwa ran oun si ọmọdebinrin naa.
"Ṣugbọn nigba ti ọmọdébìnrin naa debẹ, alufaa mu wọ ninu yara to si fi tipatipa ba ni ibalopọ, eyi to pada di oyun.
"Kete ti iroyin naa de ileeṣẹ ọlọpaa ni a nawọ gan alufaa, to si jẹwọ sugbọn o ni isẹ esu ni ati pe oun ni o ja ibale ọmọdebinrin naa, ẹni ọdun mejila."
Oyeyemi fikun pe iya ọmọ naa ni oun ko se akiyesi nitori ọmọ oun o ti maa ṣe nnkan oṣu lai mọ pe oyun naa ti de oṣu méje.
Nigba to n sọrọ lori bi ọrọ naa ṣe waye lẹyin to bimọ tan fun ileeṣẹ ọlọpaa, Ọmọ ti alufaa naa fipabalopọ ni ọpọ igba ni alufaa ọhun dunkoko mọ oun pe oun ko gbọdọ sọ ohun to ṣẹlẹ fun ẹnikẹni.
O ni idi niyii ti oun ko le sọ fun iya oun nitori ibẹrubojo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Lẹyin oṣu meje ni iya ọmọ to mọ pe ọmọ oun ti loyun nítorí pe ọmọ ko to ẹni to ṣe nnkan oṣu, eyi ko jẹ iya ọmọ naa fura.
Kọmisona ileeṣẹ ọlọpaa, Lanre Bankole tí palasẹ pe ki wọn gbe alufaa naa lọ sí ika ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, tí iwadi yoo si tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa















