Kí ló dé táwọn èèyàn kan fi ń ro ikú ro Kemi Afolabi?

aworan kemi afolabi

Oríṣun àwòrán, Kemi Afolabi/Instagram

Gbajugbaja oṣerebinrin Kemi Afolabi ti bọ si ori ayelujara lati fesi si iroyin kan to n ja kiri pe o ti ku.

Kemi Afolabi ni irpyin ẹlẹjẹ ni iroyin naa nitori oun wa laye ati laaye.

Osere tiata naa ni iroyin naa ba oun ninu jẹ lọpọlọpọ, to si ni oun ko ni ku, bi ko ṣe yiye.

Nigba to n fesi lori ayelujara, Kemi Afolabi ni lori awọn opo ayelujara Youtube ati Facebook, ni awọn oniroyin kan ti kọ iroyin pe oun ti jade laye.

“Kemi Afolabi ko ni ku, bi ko ṣe yiye lagbara Ọlọrun nitori o fẹ jẹri si isẹ Ọlọrun.

“Ẹnikẹni to ba ro iku si Kemi Afolabi ni yoo rọpo nitori gbogbo erongba wọn lori Kemi Afolabi ko ni wa si imusẹ.”

Arun wo lo n se Kemi Afolabi?

Ni ibẹrẹ ọdun yii lori eto ori ayelujara kan pẹlu gbajumọ sọrọsọrọ Chude Jideonwo, ni Kemi Afolabi ti sisọ loju pabanbari aisan to n ṣe e gangan.

Aisan yii si lo ni oun ti n de mọra lati ọjọ pipẹ.

Pẹlu omije loju, Kemi Afolabi kẹnu bọ ọrọ lori ohun to n la kọja, ti ko sọ faraye tẹlẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, Afolabi sọ pe ọkan lara awọn dokita rẹ ti sọ fun oun pe ọdun marun lo ku fun oun, lati lo loke eepẹ.

Koda o fi kun un pe, dokita ọhun ṣee lalaye pe ki oun gbiyanju lati ri daju pe oun n wa pẹlu awọn eeyan oun.

Paapaa awọn eeyan to fẹran oun, ki oun le gbe o kere tan, ọdun marun laye".

aworan ayelujara kemi afolabi

Oríṣun àwòrán, kemi Afolabi/Instagram

Ta ni Kemi Afolabi?

Gbajumọ osere tiata ni Kemi Afolabi Adedipe.

Ọjọ kejidinlgbọn osu Kerin ọdun 1980 ni wọn bi gbajumọ osere tiata naa.

Ọmọ bibi ipinlẹ Ogun nii se.

Laipẹ yii lo kede pe oun ni arun to n ba isan ara ja, ti wọn n pe ni Lupus.

O ni dokita sọ fun oun pe oun ko ni pẹku.

Amọ o ti lọ silẹ Amrika bayii lati gba itọju nitori aisan naa.

Ọmọbinrin kan soso ni Kemi Afolabi bi ninu igbeyawo rẹ