Rúkèrúdò ẹgbẹ́ òṣèlú PDP l‘Osun tún búrẹ́kẹ́ si

Oríṣun àwòrán, Adeleke and babayemi
Ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Osun ti fi ọwọ osi juwe ile fun oludiije sipo gomina, to ba Ademola Adeleke du ipo naa, Dotun Babayemi.
Ẹsun ti wọn fi kan Babayemi, ti wọn fi yọ ninu ẹgbẹ naa ni pe o n ṣiṣẹ lodi si ẹgbẹ oṣelu ọhun.
Nibi ipade awọn akọroyin kan niluu Osogbo, akọwe ẹgbẹ naa lati wọọdu keji niluniluu Gbongan, Ogunleye Bukayo, lo kede igbesẹ naa.
Ogunleye ni awọn iwa ti Babayemi n hu, n doju ti ẹgbẹ naa, ati pe o tun n ba orukọ ilu awọn jẹ.
O ni awọn gbe igbesẹ lati yọ oludije sipo gomina naa kuro ninu ẹgbẹ ọhun gẹgẹ bii ofin ẹgbẹ naa ṣe sọ, abala ofin kejidinlọgọta, ẹsẹ kinni rẹ.
PDP Osun ni ẹnikẹni to ba huwa to lodi si ofin ẹgbẹ yoo jẹyan rẹ nisu
Wayi o, awọn adari ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Osun ti fi ontẹ lu iyọnipo Babayemi.
Ninu atẹjade kan ti alaga fidihẹ ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Osun, Adekunle Akindele fi lede ni eyi ti jẹyọ.
Akindele ni igbesẹ ti ẹka ẹgbẹ naa, to wa ni ijọba ibilẹ Ayedaade gbe, wa ni ibamu pẹlu ofin ẹgbẹ naa.
Atẹjade ọhun tun sọko ọrọ si alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Osun, Gboyega Falodun, fun bo ṣe maa n da si ọrọ awọn.
PDP ni bi Falodun ṣe n da si ọrọ Babayemi n fi han pe igbesẹ ti awọn gbe lati yọ Babayemi ninu ẹgbẹ kii ṣe aṣiṣe.
Lẹyin naa ni PDP ni ẹnikẹni ninu ẹgbẹ ọhun to ba ṣisẹ lodi si ẹgbẹ yoo jẹ iyan rẹ niṣu.

Oríṣun àwòrán, Engr Brill Murphy
Awada kẹrikẹri ni iyọnipo mi – Babayemi
Ẹwẹ, Dotun Babayemi ti fesi si iyọnipo rẹ.
Agbẹnusọ Babayemi, Kayode Oladejo sọ pe awọn to yọ Babayemi nipo ko mọ ohun ti wọn n ṣe.
O ni “Gbogbo awọn to ṣe ohun ti wọn pe ni iyọnipo Omooba Dotun Bbabayemi kuro ninu ẹgbẹ PDP, ko mọ nnkankan nipa ofin to so ẹgbẹ wa ro.”
“Oniyẹyẹ ni awọn ati gbogbo awọn to ran wọn niṣẹ lati yọ Babayemi nipo, nitori ẹni ti araalu fẹran ni Babayemi.”
Ti ẹ ko ba gbabe, Babayemi ti kọkọ gbe ẹgbẹ oṣelu naa lọ sile ẹjọ pe Sẹnetọ Ademola Adeleke ko kunju oṣuwọn, to lati du ipo gomina ninu ẹgbẹ ọhun.















