Àwọn ọ̀dọ́ Eruwa fẹ́ ṣe ẹyẹ fún Timothy Adegoke

aworan oloogbe Timothy Adegoke

Oríṣun àwòrán, Timothy Adegoke Damilare

Ẹgbẹ to n se kokari ami ẹyẹ fawọn ọdọ niluu Eruwa ti kede pe wọn yoo fi ami ẹyẹ da oloogbe Timothy Adegoke lọla nibi ayẹyẹ kan ti yoo waye lọj Aiku.

Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa, Eruwa Youths Award (EYA) fi ransẹ si BBC Yoruba ni iroyin naa ti jẹyọ.

Ẹgbẹ ọdọ naa ni awọn fi ami ẹyẹ da oloogbe naa lọla nitori ipa ribiribi to ti ko si idagbasoke ilu naa.

Bakan naa ni wn ni ami ẹyẹ ọhun tọ si Timothy Adegoke nitori pe ọna ti iku rẹ gba waye dun awọn de egungun.

Ọjọ kọkanla oṣu kẹsan, ọdun 2022 ni ayẹyẹ naa yoo waye ninu gbọngan kan nilu Eruwa.

Timothy Adegoke, to jẹ akẹkọọ to n gba imọ kun imọ nile ẹkọ fasiti Obafemi Awolowo (OAU) lo ku lọjọ karun un oṣu kọkanla ọdun 2021.

Iku oloogbe naa waye lasiko to rinrin ajo lati Abuja lọ si Ile Ife lati ṣe idanwo MBA ni fasiti OAU.

Ile itura Hilton, ti oloogbe naa wa kẹyin, kawọn bi rẹ to kede pe o di pe di awati.

Lẹyin ọ rẹyin, oku Timothy ni wọn pada ri pada lagbegbe kan nilu Ile Ife.

Lẹyin naa ni awọn ọlọpaa mu oludasilẹ ile itura Hilton hotel, Ramon Adedoyin at'awọn afurasi mẹfa mii.

Igbẹjọ iku Timothy Adegoke yii si lo n tẹsiwaju lọwọ nile ẹjọ giga ti ipinlẹ Osun.

Atẹjade ti ọdọ Eruwa fisista