Ọ̀nà mẹ́rin tí Nàíjíríà lè gbà bọ́ lọ́wọ́ ebi àti ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ

Awon to n ru ounje

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọsẹ to kọja, ajọ iṣọkan agbaye (UN) ṣe ikilọ nla wi pe miliọnu mejilelọgọrin awọn ọmọ Naijiria – nnkan bii ida mẹrinlelọgọta ọmọ Naijiria – lo ṣee ṣe ki wọn koju ebi, ki wọn ma si ri nnkan jẹ mọ nigba ti yoo ba fi di ọdun 2030.

Ajọ to n ri si ipese ounjẹ ati eto ọgbin lagbaye (FAO) ninu akọsilẹ wọn nipa iwadii ti wọn ṣe fi han pe nigba ti a o ba fi ri ọdun diẹ si asiko yii, wahala naa yoo peleke sii lorileede Naijiria.

Ajọ iṣọkan agbaye tun ke si ijọba orileede Naijiria lati yanju iṣoro ayipada oju ọjọ ati awọn iṣoro kokoro to n ba ere oko jẹ, ki gbogbo wahala ọhun to le dopin.

“Esi abajade iwadii wa jẹ eyi to n kọni lominu, bi miliọnu mejilelọgọrin ni yoo koju ebi nla nigba ti yoo ba fi di ọdun 2030,” wọnyi ni ohun ti Taofiq Braimoh sọ nibi ipade idagbasoke nipa iṣẹ agbẹ to waye niluu Abuja laipẹ yii.

Bo tilẹ jẹ pe wahala airi ounjẹ jẹ ti bẹrẹ sii ba awọn ọmọ Naijiria kan finra bayii. Awọn kan to ba BBC sọrọ ṣalaye nipa bi wọn ṣe n lo gbogbo ọjọ wọn lai ri ounjẹ gidi jẹ.

Lapa keji, ijọba orileede naa si bẹrẹ sii gbe awọn igbesẹ meloo kan, pẹlu erongba lati ṣagbelarugẹ fun ọrọ iṣẹ agbẹ ati ọgbin, eyi ti Aarẹ Bọla Tinubu kede rẹ lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii, lẹyin to fi igbimọ ti yoo ṣiṣẹ labẹ rẹ lelẹ.

Ọmọwe Abubukar Suleiman

Oríṣun àwòrán, NGFMAFS

Ọmọwe Abubukar Suleiman ni igbakeji aarẹ tẹlẹ fun ajọ FAO lorileede Naijiria, o si ṣalaye ọna marun-un to nilo lati gba.

Awọn ohun to n mu ki iṣoro naa peleke sii

Awon agbe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọwọlọwọ bayii, miliọnu mọkanlelọgbọn ni wọn ti wa ninu ebi ọgaja-fọwọ-mẹkẹ, gẹgẹ bi esi abajade iwadii ajọ FAO ṣe sọ.

Awọn mọkanlelọgọrin eeyan ni wọn ti wa ni bebe lati ma ṣe ri ounjẹ jẹ mọ ni ọdun mẹfa si asiko yii, gẹgẹ bi ajọ naa tun ṣe kọ ọ jade.

“Ohun kan gboogi to si fa ohun to n ṣẹlẹ yii ni eto ọrọ aje ilẹ Naijiria,” Ọmọwe Suleiman lo sọ bẹẹ. “Bi owo ounjẹ ati awọn nnkan lilo miran ṣe n lọ soke ti ṣe iranwọ gidi.”

O fi kun un pe alekun lori owo epo bẹntiroolu lo fa a ti owo awọn ọja fi lọ soke, to si n nira lati ra, nitori pe gbogbo ire oko patapata ni wọn n gbe gba ori ilẹ.

“Wahala eto aabo naa tun jẹ ki awọn eeyan sa, to si n jẹ ki wọn padanu awọn oko wọn.”

Awọn igbesẹ to nilo lati gbe

Ọmọwe Abubukar Suleiman

Oríṣun àwòrán, Sulaiman Abubakar

Ọmọwe Abubukar Suleiman sọ pe awọn igbesẹ kiakia ati eyi ti yoo jẹ ọlọjọ pipẹ wa lati gbe. O ṣalaye rẹ lẹkunrẹrẹ bayii:

Mimulo/Adoption

Akọṣẹmọṣẹ naa sọ pe awọn eeyan kan wa ti wọn ti bori ni ti wọn, to si ni awọn wọnyi ni ajọ WFP fi si ipo keji ati ipo kẹta ninu ipele ebi.

O ni awọn eeyan yii nilo ki wọn ran wọn lọwọ nitori pe ko siye ohun ti wọn le ṣe lati ri ounjẹ nitori pe wọn ko ni ọna lati mọ bi wọn yoo ṣe rii.

Aabo ọfẹ

Awọn eeyan ko fi bẹẹ da oko mọ, bẹẹ si ni wọn ko kowo le ori iṣẹ agbẹ ati ọgbin mọ nitori wahala ati iṣoro eto aabo.

Awọn eeyan n da oko ṣugbọn wọn ko ri ere nibẹ, nitori pe awọn ologun ti ko gbogbo ire ati anfaani wọn lọ, tabi ka sọ pe wọn nilo lati san owo ori.

Awọn nnkan wọnyi maa n fa ki ounjẹ pọ lati ṣe jade.

Ṣiṣe ayipada si ilana oko dida

O pọn dandan lati mu ayipada ba ọna ti a n gba lati da oko, paapaa julọ awọn oko ti a n da sori ọgbẹ ilẹ ati bi a ṣe n tọju awọn ire oko, ki awọn ounjẹ ma ba a bajẹ nibi ti a ba tọju wọn si.

Awọn eso igbalode la nilo lati maa ṣe, ti ko wọn ko si ni nilo ọpọ omi.

Ṣiṣẹ iranwọ fawọn agbẹ keekeeke

Ijọba nilo lati ṣe iranwọ fawọn agbẹ keekeeke nitori pe awọn ni igi lẹyin ọgba fun iṣẹ agbẹ ni Naijiria.

Kii ṣe pe ijọ pe ijọba ko pese iranwọ, wahala to wa nibẹ ni pe ko de ọdọ awọn agbẹ to wa lorileede. Nitori pe wọn gbọdọ ṣe wahala gidi.