Wo tọkọtaya ti ìgbéyàwó wọn ti pé àádọ́ta ọdún nílùú tí ìgbéyàwó kìí ti í tọ́jọ́

Oríṣun àwòrán, Mahmud Yakasai
Àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n ń ṣàjọyọ̀ àádọ́ta ọdún tí wọ́n ti ṣègbéyàwó ni àwọn kan ti ń kan sáárá sí fún ìbáṣèpọ̀ àti ìbágbépọ̀ wọn.
Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí ìlú táwọn tọkọtaya náà ń gbé jẹ́ ìlú tí ọ̀pọ̀ gbàgbọ́ pé ìgbéyàwò kìí pẹ́ túká níbẹ̀ àti pé ibẹ̀ ni olú ìlú ìgbéyàwó tí kìí tọ́jọ́.
Mahmud Kabir Ykasai àti Rabiatu Tahir tó bá BBC Hausa sọ̀rọ̀ ṣàlàyé àwọn àṣírí tó ṣokùnfà tí ìgbéyàwò wọn fi tọ́jọ́ di àsìkò yìí.
Yakasai ní ìyàwọ òun jẹ́ ènìyàn tó lawọ́ gan àti pé ó wà lára nǹkan tó jẹ́ kí ìgbéyàwó àwọn pẹ́ púpọ̀.
“Kìí ṣe onímọ̀ tara ẹni nìkan, tó sì máa ń fojú fo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nǹkan fún mi,” bàbá ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin náà sọ fún BBC Hausa.
Ọmọ mẹ́tàlá ni àwọn tọkọtaya náà bí, tí ìyàwọ náà, Rabiatu Tahir sì júwe ọkọ rẹ̀ bí onísùúrù àti oníwàpẹ̀lẹ́ níwájú ìṣòro.
“Mo lè sọ pé súùrù ọkọ mi wà lára nǹkan tí ìgbéyàwó wa fi pé àádọ́ta ọdún.”
Àwọn tọkọtaya náà ní àwọn fẹ́ràn ara àwọn gidi, tí inú àwọn sì máa ń dùn sí ìbáṣepọ̀ àwọn.
'Ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún mi pé tọkọtaya le lo àádọ́ta ọdún papọ̀'
Fún Hassana Mahmud nǹkan ńlá ni ìgbéyàwó yìí jẹ́ fun nítorí òun tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógójì gan ti fẹ́ ọkọ ní ẹ̀ẹmàrùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Ó ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún òun pé tọkọtaya le gbé fún ìgbà pípẹ́ tó bẹ́ẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé ọkọ tí òun pẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ jùlọ ni òun lo ọdún mẹ́rin pẹ̀lú tó sì ní ohun ńlá ló jẹ́ fún òun láti rí tọkọtaya tó ti wà papọ̀ fún ìgbà pípẹ́ bíi ti Yakasai àti Tahir.
“Àwọn ọkọ tí mo fẹ́ ni wọ́n máa ń ṣe dada sí mi nígbà tí a bá ń fẹ́ ara wa lọ́nà, ní kété tí a bá ti ṣe ìgbéyàwó ni wọ́n máa ń yípadà.
“Ó máa ń jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún mi nígbà ti mo bá gbọ́ tí àwọn èèyàn ń pe Kano ní ìlú tí ìgbéyàwó ti máa ń túká jùlọ ní Nàìjíríà, mo lérò pé èyí máa yípadà lọ́jọ́ kan,” Hassana, tó ti bí ọmọ mẹ́rin ṣàlàyé.
Ìlú Kano bẹ̀rẹ̀ sí ní gbajúmọ̀ fún ìlú tí ìgbéyàwó kìí tọ́jọ́ níbẹ̀ lọ́dún 1990 tó sì ń gbajúmọ̀ títí di àsìkò yìí.
Ní oṣooṣù ni ọ̀pọ̀ tọkọtaya máa ń kọ ara wọn sílẹ̀ ní Kano tí ìwádìí tí BBC àti ìjọba ìbílẹ̀ ṣe lọ́dún 2022 ṣàfihàn pé ìdá méjìlélọ́gbọ̀n ìgbéyàwó ni ìlú Kano ni kìí kọjá oṣù mẹ́ta sí oṣù mẹ́fà.
Ìwádìí náà tún fi hàn pé àwọn èèyàn tí ọja orí wọn wà láàárín ogún ọdún sí ọdún márùndínlọ́gbọ̀n ni wọ́n ti ṣe ìgbéyàwó tó mẹ́ta.
Báwọn tọkọtaya ṣe máa ń kọ ara wọn sílẹ̀ láì tọ́jọ́ jẹ́ ohun ìkọnilóminú pàápàá fún ikọ̀ Hisbah, àjọ ẹ̀sìn Islam kan tí ìpínlẹ̀ Kano dá sílẹ̀ láti rí sí àwọn ìwà kò tọ́ àti láti máa ṣàmójútó òfin Sharia ní ìpínlẹ̀ náà.
Ikọ̀ Hisbah máa ń mójútó àwọn ìwà bíi ríri pé àwọn mùsùlùmí ìlú Kano kò mu ọtí àti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn tọkọtaya tó bá ń ní ìpèníjà nínú ìgbéyàwó wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kí ló fà á tí ìgbéyàwọ kìí fi tọ́jọ́ ní Kano?
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn obìnrin máa ń tò síwájú ọ́fíìsì àwọn Hisbah láti lọ fi ẹjọ́ àwọn ọkọ wọn ti kò bá ṣe ẹ̀tọ́ wọn pàápàá lórí ọmọ sùn.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ìlú Kano ló máa ń ṣègbéyàwọ lásìkò tí ọjọ́ orí wọn ṣì kéré – lọ́pọ̀ ìgbà wọn kìí pé ọdún méjìdínlógún tí òfin Nàìjíríà là kalẹ̀.
Àwọn mìíràn máa ń rò ó pé òfin Islam tó fàyè gba ìkọraẹnisílẹ̀ wà lára ìdí tí ìgbéyàwó fi máa ń túká láì tọ́jọ́ ní Kano.
Ṣùgbọ́n onímọ̀ ẹ̀sìn Islam kan, Abdullahi Ishaq Garangamawa ní kìí ṣe pé Islam mú ìkọraẹnisílẹ̀ rọrùn rárá.
Ó ṣàlàyé pé ìdí tí Islam fi fàyè gba ìkọraẹnisílẹ̀ ni láti ri pé kò ní dàbí pé àwọn èèyàn ń wà nínú ìgbèkùn nígbà tí ìgbéyàwó wọn bá ti ń nira fún wọn.
Ó wòye pé àwọn èèyàn ló ń ṣi àǹfàní yìí lò fún ìmọ̀taraẹninìkan nítorí ìgbéyàwọ máa ń tọ́jọ́ láyé ìgbà kan tí ojú kòì tíì là tó báyìí.
Aminu Daurawa tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Hisbah láti fòpin sí bí ìgbéyàwó ṣe máa ń tètè túká ní Kano. Ó ní lára àwọn ìgbésẹ̀ tí àwọn ń gbé ni láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn èèyàn kí wọ́n tó ṣe ìgbéyàwó.
Ó ní pẹ̀lú gbogbo ìgbìyànjú àwọn, àwọn ṣì mọ̀ pé bí ìgbéyàwó ṣe ń tuka ṣì ń pọ̀ si tí àwọn sì ti gbé ìgbìmọ̀ dìde láti ṣàmójútó rẹ̀.
Olùdásílẹ̀ àjọ tí kìí ṣe ti ìjọba kan, Women and Children Initiative, Hadiza Ado ní bí àwọn tọkọtaya ṣe ń kọ ara wọn ṣì ń pọ̀ si.
Àṣà fífi tọkọtaya fúnra wọn

Oríṣun àwòrán, Mahmud Kabir Yakasai
Ó ní ojoojumọ́ ni àwọn máa ń gba ẹjọ́ tó lé ní ọgbọ̀n lórí ìgbéyàwọ ní ọ̀dọ́ àwọn àti pé ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà ti kò ṣe dada náà wà lára àwọn nǹkan tó ń fà á.
Àṣà ká máa fi ọkọ àti aya fúnra wọn jẹ́ ohun tó wọ́pọ̀ láwùjọ àwọn mùsùlùmí nítorí ọkùnrin àti obìnrin kò ní àǹfàní láti ṣe papọ̀.
Èyí ló máa ń fà á tí ọ̀pọ̀ fi máa ń ṣe ìgbéyàwó láì mọ ara wọn dada.
Kòdá wọ́n fa Muhammad Kabir Yakasai àti Rabiatu Tahir fúnra wọn ni nígbà tí wọ́n ṣì wà lọ́mọdé.
Àmọ́ àwọn méjéèjì dúró fún ọdún méjìlá láti mọ ara wọn dáadáa kí wọ́n tó ṣe ìgbéyàwó.
Ọ̀gbẹ́ni Yakasai, ẹni tó ti fìgbà kan ṣiṣẹ́ rí pẹ̀lú Nigeria Airways, ní ṣíṣe ọ̀pọ̀ nǹkan papọ̀ pẹ̀lú ìyàwọ òun àti ríran ara ẹni lọ́wọ́ wà lára ohun tó mú kí ẹ̀mí ìgbéyàwó àwọn gùn.
Bákan náà ló ní àwọn gba ìfẹ́ láàyè láàárín àwọn nítorí ìfẹ́ tó wà ló jẹ́ kí àwọn le bá ara wọn gbé fún ìgbà pípẹ́.
“Mo gba àwọn èèyàn tó bá fẹ́ ṣe ìgbéyàwó nímọ̀ràn láti jìnà sí ìwà ìmọtaraẹninìkan, àmọ́ kí wọ́n lọ sínú ìgbéyàwọ pẹ̀lú ọkàn mímọ́.”
Ìyàwó rẹ̀, Rabiatu Tahir náà kín ọ̀rọ̀ ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn nígbà tó ní sùúrù ṣe pàtàkì púpọ̀ nínú ìgbéyàwó.
“Tí èèyàn kan bá ń bínú, ó yẹ kí ẹnìkejì fọwọ́ wọ́nú ni.”












