‘’Ọkùnrin tó kú níbi ìpolongo ìbò Donald Trump fara gb’ọta láti dáàbò bo ẹbí rẹ̀’’

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkunrin ti ibọn pa nibi eto ipolongo idibo Donald Trump lọjọ Abamẹta ni agbegbe Butler ni Pennsylvania ni a ti gbọ pe o fara gbọta lati daabo awọn ẹbi rẹ ti wọn jọ wa nibi eto ọhun.
Corey Comperatore ẹni aadọta ọdun ni iyawo rẹ sọ fawọn akọroyin pe raga bo oun ati ẹbi rẹ yoku nibi eto naa lati daabo bo awọn.
Comperatore ni iroyin sọ pe o maa n fi ara rẹ silẹ lati ṣe iṣẹ panapana nigba aye rẹ.
Gomina ipinlẹ Pennsylvania, Josh Shapiro, ti sọ pe akinkanju ni ọkunrin to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Gomina Shapiro ṣalaye pe oun le sọ nipa ọkunrin yii lẹyin ti iyawo rẹ ti ba oun sọrọ.
Shapiro fikun ọrọ rẹ oun ṣi n ba awọn ẹbi eeyan meji ti ibọn ba nibi ipolongo ibo naa sọrọ nipa ilera awọn eeyan naa.
Wo ipò tí ìlera Trump wà lẹ́yìn tí ìbọn bá a níbi ìpolongo ìbò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ America tẹlẹ, Donald Trump ti n ṣe daadaa lẹyin ti ibọn ba a, to si ti n dupẹ lọwọ awọn agbofinro lori ipa ti wọn ko, gẹgẹ bi atẹjade to wa loju opo ayelujara ti igbimọ ẹgbẹ oṣelu Replublican, iyẹn (RNC).
Atẹjade ọhun sọ pe “o n foju sọna lati darapọ mọ gbogbo yin ni Milwaukee nigba ti a o ba maa tẹsiwaju pẹlu ipade gbogboogbo nibi ti a ti maa fa a kalẹ gẹgẹ bi aarẹ kẹtadinlaadọta nilẹ Amẹrika.
“Gẹgẹ bi ẹni ti ẹgbẹ oṣelu wa fa kalẹ... o maa tẹsiwaju lati maa sọ awọn afojusun rẹ lati tun jẹ ki ilẹ Amẹrika ga lẹẹkan sii,” bayii ni atẹjade lati ileeṣẹ olupolongo Trump ati RNC ṣe ka.
Ṣaaju, Trump ti kọ ọ soju opo ayelujara ti Truth rẹ, iyẹn ikanni to da silẹ.
O dupẹ lọwọ awọn agbofinro ati awọn ọtẹlẹmuyẹ lori ipa ti wọn ko ni pajawiri.
“Eyi to ṣe pataki julọ, mo fẹẹ fi ọrọ ibanikẹdun mi ranṣẹ si mọlẹbi ẹni ti wọn pa nibi ipolongo naa, ati si mọlẹni ẹni to farapa yannayanna. O ṣeni laanu pe iru iṣẹlẹ yii le ṣẹlẹ ni orileede wa.”

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ FBI ni orile-ede America, ti mọ ẹni to gbiyanju lati pa Donald Trump.
Ọkùnrin naa ni FBI sọ pe iwadii fihan pe orúkọ rẹ n jẹ Thomas Matthew Crooks, ẹni ogun ọdun.
Crooks ni atẹjade awọn ọtẹlẹmuyẹ sọ pe o wa lati agbegbe Bethel Park, Pennsylvania.
Ilu naa ko ju aadọrin kilomita si Butler, nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.
FBI sọ pe "isẹ iwadii ṣi n lọ lọwọ, ki ẹnikẹ́ni to ba ni ẹri bii aworan tabi fidio, to le ran wọn lọwọ, fì ranṣẹ.
Bawo lo ṣe ṣẹ̀lẹ̀ gan an?
Àwọn oṣojúmikoro to ba BBC sọ̀rọ̀ níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà daba wípé ìró ìbọn yẹn wá láti ilé alájà kan tó wà ní ọwọ otun sì ibi pátákò tí Trump tí ń sọ̀rọ̀ kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà to ṣẹ.
Ọkàn nínú wọn, Greg, so fún BBC wípé óun rí arákùnrin tí ó ń faya wọlẹ lórí òrùlé ilé alájà kan náà ni bí ìṣẹ́jú marun sì asiko ti Trump bo si ori pátákò láti sọ̀rọ̀. Ó nipe òun tọ́ka ẹni tí òun fura si yii fún àwọn ọlọ́pàá.
"ìbọn wá ní ọwọ rẹ. Ó hàn dájúdájú wípé arákùnrin náà mú ìbọn lọ́wọ́. Àá ń tọ́ka ẹ fun àwọn ọlọ́pàá àmọ́ ṣe ni wọn ń sáré kiri lórí ilẹ̀. A sì ń sọ fún wọn wípé arákùnrin naa wà lórí òrùlé pẹ̀lú ìbọn àmọ́ nkan tó ń ṣẹlẹ̀ kò yẹ àwọn ọlọ́pàá," Greg ṣàlàyé.
Oṣojúmikoro miran, Jason sọ fún BBC wípé óun gbó ìró ìbọn ni igba marun un.
"A rí wọn ẹṣọ ààbò tí wọn bẹ mọ Trump láti dáàbò bo ó. Gbogbo èèyàn tó wà lójú agbo náà bẹ̀rẹ̀ ni kíákíá.
Lẹ́yìn náà ni Ààrẹ tẹ́lẹ̀ri Trump dìde dúró òsì náà ọwọ rẹ sókè, o si sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan.
Tim to wá ní àpéjọpọ náà pelu sọ pé òun gbọ́ ìró ìbọn lọpọlọpọ












