Ohun tí a mọ̀ rèé nípa afurasí ọ̀dọ́kùnrin ẹni ogún ọdún tí ẹ̀ṣọ́ aláàbò FBI ló yìnbọn sí Trump

Aworan Matthew Crooks

Oríṣun àwòrán, CBS

Ẹṣọ alaabo FBI ti darukọ ọkunrin ti wọn lo yinbọn si aarẹ Amẹrika tẹlẹ, Donal Trump, nibi ipolongo idibo gẹgẹ bi Thomas Matthew Crooks.

Ọdọkunrin Crooks ẹni ogun ọdun ni iroyin sọ pe o yinbọn fun Trump nigba to n bawọn eeyan sọrọ nibi ipolongo eto idibo ni Butler ni ipinlẹ Pennsylvania l'Amẹrika.

Eeyan kan ni iroyin fidi rẹ mulẹ pe o ba iṣẹlẹ naa lọ nigba tawọn meji mii ṣi farapa yanayana.

Ọdọkunrin ọhun ni iroyin sọ pe awọn ẹṣọ alaabo yinbọn pa lẹsẹkẹsẹ.

Ninu atẹjade kan ti ẹṣọ eleto abo FBI fi sita ni o ti sọ pe Crooks ni ẹni to wa nibi igbesẹ lati gbẹmi Trump.

Ajọ naa sọ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.

Ta ni ọdọkunrin to yinbọn fun Donald Trump?

Aworan Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Reuters

  • Ẹṣọ eleto abo FBI ti sọ pe Thomas Matthew Crooks ni orukọ afurasi to yinbọn si Donald Trump nibi to ti n ṣe ipolongo idibo.
  • Ẹni ogun ọdun Crooks i ṣe.
  • Lati agbegbe Bethel Park ni Pennsylvania ni Crooks ti wa si Butler nibi to ti yinbọn si Trump.
  • Awọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ lo yinbọn pa Crooks, bẹẹ ni ẹṣọ FBI ko le sọ orukọ rẹ lẹsẹkẹsẹ.
  • Lẹyin ti esi ayẹwo DNA ti ẹṣọ eleto abo FBI ṣe lori oku rẹ tan ni wọn to da a mọ.
  • Crooks jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican ti i ṣe ẹgbẹ oṣelu Trump gan an naa.
  • Ileeṣẹ iroyin Reuters fidi rẹ mulẹ pe nigba ti Crooks wa ni ẹni ọdun mẹtadinlogun, o da $15 fun igbimọ kan to n ṣe ikowojọ fawọn oloṣelu ẹgbẹ Democrat.
  • Iwe iroyin Pittsburgh Tribune-Review fidi rẹ mulẹ pe Crooks kẹkọọ jade nile ẹkọ girama Bethel Park lọdun 2022 nibi to gba ẹbun $500 lẹyin to fakọyọ ninu idije ẹkọ iṣiro ati sayẹnsi.
  • Matthew Crooks to jẹ baba rẹ sọ fun ileeṣẹ tẹlifisan CNN pe ohun to ṣẹlẹ si ọmọ oun ṣi n ṣe oun ni kayeefi; o ni oun maa ni lati bawọn ọlọpaa sọrọ ki oun to le sọrọ daadaa lori iṣẹlẹ ọhun.
  • Awọn agbofinro sọ pe Crooks ko ni ami idanimọ kankan lara rẹ nigba to yinbọn fun Trump.
  • Awọn agbofinro ko tii mọ ohun to ṣokunfa igbesẹ Crooks lati yinbọn fun Trump, amọ awọn alaṣẹ sọ pe ọna lati ṣeku pa Trump ni iṣẹlẹ naa.
  • Ẹṣọ eleto abo FBI ti sọ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ ọhun.

Àwọn ẹṣọ ààbò tí pá ẹni tó yín ìbọn sì Ààrẹ Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀ri Donald Trump

Ileeṣẹ́ ààbò ti fi atẹjáde síta ti wọn jẹri nínú rẹ wípé àwọn ti mú ẹni to yín ìbọn ni àpéjọpọ ti Trump wa balẹ.

Wọn ní oluworan kan to wa ni àpéjọpọ naa jẹ́ Ọlọhun nipe tí èèyàn méjì sí farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Atẹjáde náà sọ pé ẹni tó yín ìbọn yẹn ṣe ọ̀ṣẹ́ náà láti òkè kan ni ìtosi agbo tí ìpàdé Trump tí wáyé.

Awọn ẹṣọ aabo ṣàlàyé wípé láàrin ìwọ̀n ẹsẹ igba sì ọ̀ọ́dúrún sì agbo ìpàdé tí Trump wá ní ẹni tó yín ìbọn naa tí ṣe ìṣẹ̀ ibi rẹ.

Ni bayii, Trump tí kúrò ní ilé ìwòsàn lẹ́yìn àyẹ̀wò dókítà nigbati o farapa lójú agbo tí wọn tí ń yín ìbọn

Awọn ẹṣọ ààbò bẹ mọ Trump láti dáàbò bo ó

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bí wọn ṣe du Ààrẹ tẹ́lẹ̀ri Donald Trump kúrò lójú agbo òṣèlú nigbati ìró ìbọn dùn lakọ-lakọ

Báyìí ni àwọn ẹṣọ ààbò ṣe du Ààrẹ Trump kúrò lójú agbo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwọn ẹṣọ aabo tí du Ààrẹ orílẹ̀ede Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀ rí Donald Trump dìgbà-dìgbà kúrò loju agbo nígbà tí ìró tí ó fara jọ tí ìbọn bẹ̀rẹ̀ si ni dùn lakọ-lakọ ni àpéjọpọ àwọn òṣèlú ni ilu Pennsylvania.

Fọ́nrán kan tí ó jáde láti ibi apejo náà ṣàfihàn bí Trump ṣe tá ara ti o si fi ọwọ kan etí rẹ bí ẹni tí nkan ṣe kí ìró ìbọn to bẹ̀rẹ̀.

Ní kíá làwọn ẹṣọ tí rọgba yíì ká tí wọn sì du ú lọ si ìdí ọkọ kan tí ó ń dúró dè é.

Nínú atẹjáde kan tí ẹgbẹ́ to ń ṣe ìpolongo fún Trump látàrí eto ìdìbò to ń bọ̀ lọ́nà fi síta, Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí náà sọ pé òun wà ní àlàáfíà àti wipe àwọn dókítà ń yẹ ara òun wo ni ilé ìwòsàn.

"Ààrẹ Trump ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn agbófinró àti àwọn tó dáhùn ni kíá fún bí wọn ṣe yàrá siṣẹ́ wọn lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ búburú báyìí," àgbẹ̀nusọ Steve Cheung sọ̀rọ̀.

Lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó jọ wípé ẹ̀jẹ̀ ń jáde létí Ààrẹ tẹ́lẹ̀ri Trump àmọ́ ó ṣì na ọwọ sókè bí wọn ṣe du ú kúrò lójú agbo.

Ẹ̀jẹ̀ ń jáde létí Ààrẹ tẹ́lẹ̀ri Trump bí wọn ṣe du ú kúrò lójú agbo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bawo lo ṣe ṣẹ̀lẹ̀ gan an?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àwọn oṣojúmikoro to ba BBC sọ̀rọ̀ níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà daba wípé ìró ìbọn yẹn wá láti ilé alájà kan tó wà ní ọwọ otun sì ibi pátákò tí Trump tí ń sọ̀rọ̀ kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà to ṣẹ.

Ọkàn nínú wọn, Greg, so fún BBC wípé óun rí arákùnrin tí ó ń faya wọlẹ lórí òrùlé ilé alájà kan náà ni bí ìṣẹ́jú marun sì asiko ti Trump bo si ori pátákò láti sọ̀rọ̀. Ó nipe òun tọ́ka ẹni tí òun fura si yii fún àwọn ọlọ́pàá.

"ìbọn wá ní ọwọ rẹ. Ó hàn dájúdájú wípé arákùnrin náà mú ìbọn lọ́wọ́. Àá ń tọ́ka ẹ fun àwọn ọlọ́pàá àmọ́ ṣe ni wọn ń sáré kiri lórí ilẹ̀. A sì ń sọ fún wọn wípé arákùnrin naa wà lórí òrùlé pẹ̀lú ìbọn àmọ́ nkan tó ń ṣẹlẹ̀ kò yẹ àwọn ọlọ́pàá," Greg ṣàlàyé.

Oṣojúmikoro miran, Jason sọ fún BBC wípé óun gbó ìró ìbọn ni igba marun un.

"A rí wọn ẹṣọ ààbò tí wọn bẹ mọ Trump láti dáàbò bo ó. Gbogbo èèyàn tó wà lójú agbo náà bẹ̀rẹ̀ ni kíákíá.

Lẹ́yìn náà ni Ààrẹ tẹ́lẹ̀ri Trump dìde dúró òsì náà ọwọ rẹ sókè, o si sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan.

Tim to wá ní àpéjọpọ náà pelu sọ pé òun gbọ́ ìró ìbọn lọpọlọpọ