Ariwo sọ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Niger níbi táwọn ẹlẹ̀wọ̀n alákatakítí ẹ̀sìn ti sálọ; bó ṣe ṣẹlẹ̀ nìyí

Niger Prison Break

Oríṣun àwòrán, AFP

Awọn alaṣẹ orilẹede Niger ti kede ofin konile-o-gbele lagbegbe Tillaberi lẹyin ti awọn ẹlẹwọn kan salọ kuro lọgba ẹwọn to wa nibẹ.

Ọgba ẹwọn naa lo ni ogiri giga ti ọpọ ẹṣọ si n ṣọ latari pe awọn ọgara alakakiti ẹsin ni wọn n ko sibẹ.

Iroyin ni aadọta kilomita pere lo wa laarin ọgba ẹwọn ọhun ati ilu Niamey to jẹ olu ilu orilẹede naa.

ọdun 2019 amọ wọn ko ṣe aṣeyọri.

Lemọlemọ ni ija maa n waye laarin awọn alakatiki ẹsin naa atawọn ologun to n gbiyanju lati bojuto ijọba ti wọn ditẹgba lọdun to kọja.

Ileẹṣẹ ọmọ ogun ilẹ naa ti fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni awọn ẹlẹwọn kan salọ ṣugbọn ko mẹnuba iye awọn to salọ ni pato.

Igbagbọ wa pe awọn alakataiti ẹsin ti ọwọ tẹ pe wọn ni ibaṣepọ pẹlu al-Qaeda ati Islamic State wa lara awọn to salọ.

Ẹẹmeji ọtọtọ lawọn ẹlẹwọn naa ti gbiyanju lati ja ọgba ẹwọn naa lọdun 2016 ati

Ijọba ti wa kede ofin igbele lati alẹ titi di ọjọ keji kaakiri agbegbe Tillaberi, bẹẹ lo tun da awọn ẹṣọ alaabo sita fun abo araalu.

Ofin naa fofin de gbogbo irina ọkọ, alupupu, kẹkẹ atawọn eeyan.

Niger, toun ti awọn orilẹede to fẹgbẹkẹgbẹ rẹ, Mali and Burkina Faso ti ologun n dari lo n koju ikọlu lemọlemọ lati ọwọ awọn alakatakiti ẹsin.

Lọjọ Aje to kọja, ko din ni ọmọ ogun mẹrinla ti awọn alakakiti al-Qaeda ṣekupa lagbegbe Tillaberi nigba ti awọn mọkanla mii farapa yanayana.