Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ọkùnrin tó ti pa obìnrin 42, ju òkú wọn sì orí àkìtàn

Àkìtàn tí wọ́n ti bá òkú

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Afurasí náà sọ pé áti ọdún 2022 ni òun ti bẹ̀rẹ̀ sí pa áwọn obìnrin náà

Ileeṣẹ ọlọpaa ti mu ọkunrin kan ti wọn ni apaayan ni, fun ẹsun pe o pa obinrin mẹsan - an, to si ju oku wọn si ori akitan kan.

Arakunrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, Jomaisi Khalisia, sọ fun awọn ọlọpaa orile-ede Kenya pe, obinrin mejilelogoji ni oun ti pa lati ọdun 2022 to ti bẹrẹ ipaniyan leralera, eyi ti wọn n pe ni 'Serial Killer' ni ede Gẹẹsi.

Iyawo rẹ naa wa lara awọn obinrin naa.

Nibi ti afurasi ọhun ti n wo aṣekagba idije Euro 2024 nile ọti, lọwọ ọlọpaa ti tẹ ẹ.

Iyalẹnu nla si lo jẹ fun awọn eniyan orile-ede Kenya, lati ọjọ Ẹti, ọjọ kejila, oṣu Keje, ti wọn ti ri oku awọn obinrin naa niluu Nairobi.

Mohammed Amin, to jẹ Ọga Agba fun ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ sọ pe, "o jẹwọ pe oun fi ẹtan mu awọn obinrin naa, o pa wọn, o si ju oku mejilelogoji lara wọn si akitan idalẹsi ọhun.

Laarin ọdun 2022 si Ọjọbọ ọsẹ to kọja lo pa gbogbo wọn.

Ọgbẹni Amin ṣalaye pe afurasi naa mu awọn agbofinro lọ si ile rẹ ti ko ju irin ọgọrun-un mita si ibi to n ju oku si.

Bakan naa lo sọ pe awọn ba awọn ẹri bii foonu mẹwaa, kọmputa laptop kan, ada kan, oriṣiriṣi kaadi idanimọ àti awọn aṣọ obinrin ninu ile naa.

"Ada naa ni awọn ọlọpaa gbagbọ pe, o fi n ge ẹran ara awọn to ba pa. Wọn tun ba baagi mẹsan-an to jẹ iru eyi to fi ju awọn oku naa sọnu.

Lati ọjọ Ẹti ni awọn ọlọpaa ti gbe nnkan di ori akitan ti wọn ti ba awọn oku ọhun to ti n jẹra lọtọọtọ.

Gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe sọ, ọjọ ori awọn obinrin naa wa laarin ọdun mejidinlogun si ọgbọn ọdun.

Wọn si ti n fi ọrọ wa afurasi ọhun lẹnu wo lati mọ idi to fi pa wọn.

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun si ni yoo foju ba ile ẹjọ.

Ajọ to n mojuto awọn ọlọpaa sọ pe awọn n wadii lati mọ boya awọn ọlọpaa mọ si iwa ọdaran naa, nitori pe akitan ti wọn ti ba oku awọn obinrin ọhun ko jina si agọ ọlọpaa.

Ọwọ ọlọpaa ko ṣẹṣẹ maa tẹ 'serial killer' ni Kenya

Lati bi ọdun diẹ sẹyin ni ileeṣẹ ọlọpaa Kenya ti n mu awọn apaniyan ‘serial killer.

Lọdun 2023, ọwọ tẹ Paul Mackinzie, to jẹ olori ẹgbẹ ẹlẹsin kan, lẹyin ti wọn ri oku eeyan to le ni irinwo, ninu eyi ti awọn ọmọde wa, ninu iboji nla kan to sin wọn si.

Apa ebi wa lara pupọ ninu wọn.

Awọn ti ori ko yọ ninu iṣẹlẹ na, ati awọn ẹbi wọn, sọ pe Mackinzie, ni ki awọn ọmọ ẹyin rẹ gba awẹ, ki wọn ba a le ri Jesu.

Bakan naa, lọdun 2021, awọn araalu lu Masten Wanjala, ẹni ogun ọdun pa, to jẹwọ pe oun pa awọn ọmọdekunrin mẹwaa laarin ọdun marun-un.

Wọn pa a lẹyin to sa kuro ni agọ ọlọpaa.

O tun jẹwọ pe oun ma n fun wọn ni oogun lo, to si tun mu ẹjẹ ara wọn.

Niṣe ni Wanjala ma n parọ pe olukọni agbabọọlu ni oun, ti yoo si fi ọgbọn tan awọn to kọlu lọ si agbegbe to pamọ, nibi to ti n pa wọn niluu Nairobi, ati ni Ila oorun ati Iwọ oorun Kenya.