Ìjọba ko ọmọ Nàìjíríà 190 pàda wale lẹ́yìn tí UAE gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de físà wọn

Oríṣun àwòrán, SEEK
Ko din ni aadọwaa eeyan ti wọn jẹ ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti ijọba apapọ ti ko pada wa sile lati United Arab Emirates (UAE) lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu keje ọdun 2024 yii.
Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, National Emergency Management Agency (NEMA), lo sọ eyi di mimọ lati ẹnu Adari ẹkun Aarin-gbungbun Ariwa, Bashir Garga.
Nnkan bii aago mẹfa owurọ ku iṣẹju mẹta ni aadọwaa awọn ọmọ Naijiria naa balẹ si papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe International Airport, niluu Abuja.
Awọn aṣoju NEMA to wa nikale si tẹwọ gba wọn.
Gẹgẹ bi ajọ NEMA ṣe wi, gbogbo akọsilẹ awọn eeyan naa lo ti wa lọdọ awọn ajọ to yẹ.
Wọn ni awọn ti gba wọn nimọran lati jẹ ọmọluabi bi wọn ṣe pada si ilẹ abinibi wọn.
“Ijọba apapọ wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati jẹ aṣoju rere nibikibi ti wọn ba wa, ki wọn ma ṣi ṣe gbagbe ifẹ orilẹede wọn, ibọwọ fun ofin ati jijẹ olootọ nigba gbogbo.’’ NEMA lo sọ bẹẹ.
Tẹ o ba gbagbe, o le lẹẹdẹgbẹta ọmọ orilẹede Naijiria ti ijọba apapọ ko wale pada lati UAE kan naa lọdun 2022.
Kí ni ìdí rẹ̀ tí ìjọba ṣe ń kó àwọn èèyàn wálé láti UAE?
Bo tilẹ jẹ pe ijọba apapọ ko sọ idi ti wọn fi ko awọn iṣi miran wọle bayii, ibeere ti ọpọ ọmọ Naijiria n beere ni pe ki lo tun de ti wọn ko wọn wale.
Eyi ri bẹẹ pẹlu bijọba Naijiria ṣe ṣẹṣẹ kede pe awọn eeyan Naijiria ti le maa rin irinajo lọ si UAE bayii, lẹyin ajọsọ pẹlu orilẹede naa.
Ijọba Naijiria kede pe awọn ti pari gbogbo eto lori adehun to so UAE pọ mọ orilẹeede wa, eto si ti pari fawọn to ba ni fisa ibẹ lati le maa lọ siluu naa.
Wọn ni eyi yoo bẹrẹ lati ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu keje ọdun 2024 yii.
Bi ijọba to kede ajọsẹpọ pẹlu UAE tun ṣe waa n ko awọn eeyan tiẹ wale lojiji yii ti mu ki araalu maa sọ pe abi awọn eeyan naa ṣe aṣemaṣe nilu oniluu ni.
Bakan naa lawọn miran n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe iṣoro kan ti ko le jẹ ki wọn gbe orilẹede naa mọ, lo mu ijọba Naijiria tete lọọ ko wọn wa sile.
Wo bí o ṣe lè gba físà UAE lẹ́yìn t’íjọba orílẹ́èdè náà gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de físà ọmọ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Minisita eto iroyin ati ilanilọyẹ ni Naijiria, Mohammed Idris ti sọ pe awọn ọmọ Naijiria le maa gba fisa lati rinrin ajo lọ si orilẹede United Arab Emirates(UAE) bayii lẹyin to ni ijọba orilẹede naa ti wọgile ofin to fi de fisa awọn ọmọ Naijiria.
Minisita ṣalaye ọrọ yii fawọn akọroyin nile iṣẹ ijọba niluu Abuja lọjọ Aje.
Ọgbẹni Idris ni igbesẹ yii waye lẹyin ti ijọba apapọ fẹnuko pẹlu orilẹede UAE lori ọrọ fisa ọhun.
Minisita ni ijọba Naijiria ti n ba orilẹede UAE sọrọ naa tipẹ lori bawọn ọmọ Naijiria yoo ṣe lanfaani pada lati maa gba fisa rinrin ajo lọ si UAE.
‘’Lonii ọjọ Aje ọjọ kẹẹdogun ni a buwọlu adehun lori ọrọ naa.
Lati oni lọ, awọn ọmọ Naijiria to ba fẹ rinrin ajo lọ si orilẹede UAE ti lanfaani lati ṣe bẹẹ bayii,'' minisita eto iroyin lo sọ bẹẹ.
Ti e o ba gbagbe, ọdun 2022 ni ijọba orilẹede UAE fofin de fisa awọn ọmọ Naijiria lọ si orilẹede naa.

Oríṣun àwòrán, Ministry of info & national orient./X
Wo ilana lati gba fisa lọ orilẹede UAE
- Ileeṣẹ ijọba orilẹede Naijria to n ri si eto iroyin ati ilanilọyẹ ti ṣe alakalẹ bi awọn ọmọ Naijiria to ba fẹ lọ si UAE ṣe le gba fisa lọ si orilẹede naa.
- Alakalẹ yii wa loju opo itakun ayelujara X ileeṣẹ ijọba naa.
- Igbesẹ akọkọ ni pe ẹnikẹni to ba fẹ gba fisa UAE gbọdọ gba nọmba fun ayẹwọ awọn iwe irinna rẹ.
- Gẹgẹ bi ilana tuntun ti ijọba UAE fi lelẹ, eleyii ni yoo jẹ ki aridaju wa pe gbogbo iwe ẹni to fẹ rinrin ajo lọ si ilẹ naa lo pe ki o tiẹ to forukọ silẹ fun fisa rara.
- Amọ, awọn ọmọde ti ọjọ ori ko ba to ọdun mẹtala ko nilo lati ṣe eyi ki wọn to forukọ silẹ fun fisa.
- Igbesẹ to kan ni pe o ni lati forukọ silẹ fun fisa lori ẹrọ kọmputa ki o ṣi ri pe o dahun gbogbo ibeere ti wọn bi ọ.
- Lẹyin naa ni o ni lati fawọn iwe irinajo rẹ ranṣẹ fun ayẹwo – eleyii ni ṣe pẹlu awọn irinajo ti o ti lọ lati ẹyin wa atawọn nnkan mii.
- Lẹyin ti o ba ti fawọn iwe irinajo rẹ ranṣẹ tan ni wa gba nọmba DVN rẹ ti i ṣe nọmba ayẹwo iwe irinajo rẹ.
- Igbesẹ to kẹyin naa ni pe ki o forukọ silẹ lati gba fisa rẹ.












