Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ́ nípa JD Vance ti Trump kéde bíi igbákejì rẹ̀

Aworan Trupm ati JD Vance ti wọn n bọ ara wọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty image

Àkọlé àwòrán, Trump ati JD Vance

Ninu igbiyanju rẹ lati di aarẹ ilẹ Amẹrika lẹẹkan si i, Donald Trum ti yan ọkunrin kan, JD Vance, gẹgẹ bii ẹni ti yoo ṣe igbakeji rẹ bi ala lati di aarẹ lẹẹkan si i ọhun ba wa si imuṣẹ.

‘’ Lẹyin aṣayan ati apero to jinlẹ, pẹlu wiwo ọgbọn inu ọpọ, mo ti pinnu pe ẹni to kunju oṣuwọn ju lati di ipo igbakeji aarẹ Amẹrika mu ni Senator JD Vance, to wa lati ilu nla Ohio.’’

Bẹẹ ni Trump kọ ọ akọsilẹ rẹ lori igbakeji to kede naa.

Ẹ o ranti pe wọn ti yan Donald Trump lati dupo aarẹ, nibi ipade apapọ awọn eeyan rẹ ti i ṣe ‘Republicans’ ni wọn ti kede ọkunrin naa lati waa dije.

Ta a ni JD Vance?

Aworan JD VAance laarin ero

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ọdun 1984 ni wọn bi James David Bowman tawọn eeyan n pe ni JD Vance, Ohio, l’Amẹrika ni wọn ti bi i.

Ẹya Scottish-Irish ni ipilẹ rẹ, o si wa lati idile alawọ funfun ti wọn n ṣiṣẹ.

Awọn obi iya JD Vance ni wọn tọ ọ dagba nibi kan ti a mọ si Appalachia, ilu eedu.

Ilu naa wa lara agbegbe ti wọn ka kun aaye awọn otoṣi ju bayii.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Vance dara pọ mọ awọn ti wọn n wakusa, o si ṣiṣẹ ni Iraq ko too lọ si Yunifasiti Ohio, nibi to ti kẹkọọ gboye ninu imọ oṣelu ati irori (Political science and Philosophy).

O lọ sileewe imọ ofin Yale, o si kọ ọrọ apilẹkọ to jinlẹ tawọn eeyan si tẹwọgba, o pe e ni ‘Hillbilly Elegy.’

Ọrọ apilẹkọ naa da lori awọn ẹya funfun ti wọn n jaṣẹ mọra ṣugbọn tawọn eeyan maa n foju abuku wo, ti wọn si jẹ ọmọ ibilẹ gidi (conservatives).

Ni 2017, Vance pada si Ohio lati California,nibi to ti n ṣiṣẹ fun Biotech.

O lọọ da ileeṣẹ tirẹ silẹ pẹlu iranlọwọ Peter Thiel, oludasilẹ PayPalwey.

Ni ibẹrẹ ọdun 2021, Thiel fun igbimọ kan to fẹẹ fa Vance kalẹ fun ipo Sẹnetọ ni miliọnu mẹwaa dọla $10m (£8m).

Bi Vance ṣe bẹrẹ irinajo lati di sẹnetọ naa lo yi ohun pada lorii Trump, o tọrọ aforiji fun bo ṣe pe e ni ẹni ẹ̀kọ̀ tẹlẹ, o si ko awọn ọrọ buruku to ti sọ nipa aarẹ tẹlẹ naa jẹ.

Nigba ti Vance ti ṣe ti Trump, ọwọ kan lo ri ipo sẹnetọ naa mu, latigba naa lo si ti di alẹnulọrọ ni Washington.

Ẹni ọdun mọkandinlogoji (39) pere ni Vance, ireti si wa pe yoo fi jijẹ ọdọ rẹ koju awọn agba to n dije lai fi tiwọn ṣe.