Mọ̀ nípa Anuoluwapo Opeyeri tó ti oko bírísopé di ẹni tó ń gbé ògo Africa ga ní ìdíje Olympics
- Author, Isaiah Akinremi
- Role, BBC Sport Africa
- Reporting from, Lagos
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oríṣun àwòrán, Badminton Confederation Africa
Anuoluwapo Opeyori, ọba ere idaraya ‘badminton’ nilẹ adulawọ ti n mura lati lọ ṣoju ilẹ rẹ ninu idije Olympic ti yoo waye niluu Paris, ni France.
Bo tilẹ jẹ pe ọmọ atapata dide ni lati ilu Eko, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn naa ti gba ife ẹyẹ mẹrin ọtọtọ, eyii to jẹ akọkọ iru rẹ ni Afrika.
Ohun to mu ki aṣeyọri Opeyori ṣe pataki ni pe o wa lati Naijiiria, to jẹ orilẹede ti ko fi bẹẹ ka ere idaraya badminton si.
Ninu ifọwerọ pẹlu BBC, o ni “afojusun mi ni lati de ipele komẹsẹ-o-yọ ninu idije naa nitori mo mọ pe ti mo ba le bori ninu ifẹwọnseọ naa, mo ti di ẹrujẹjẹ si awọn to ti wa niwaju tẹlẹ lọrun, amọ mo gbagbọ pe mo le kọja ipele naa.
“Ki n ma parọ, ẹru ko ba mi nitori awọn to mọ nipa ere idaraya naa daadaa ni mo maa koju.
“Awọn lo yẹ ki ẹru maa ba nitori wọn maa koju mi laipẹ”
Lati igba ti badminton ti wọ idije Olympics lati ọdun 1992, ọmọ alawọ dudu kankan ko wọ ipele keji idije naa ri.
Fifopin si ijakulẹ ilẹ adulawọ ninu badminton

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba to n ṣalaye bo ṣe bẹrẹ ere badminton o ni “emi ati ọrẹ mi kan la n gba bọọlu ti akọnimọọgba si ri wa.
“Mo gbagbọ pe akọnimọọgba naa ni oju fun ohun to dara, nitori ọmọ kekere to kan n fi bọọlu ṣere ni wa nigba naa.”
O ṣalaye pe ni kete ti akọnimọọgba naa fi oju oun si ere badaminton naa ni oun bẹrẹ si n nifẹ si i.
Aarẹ fun ere idaraya badminton ni Naijiria, Francis Orbih, sọ fun BBC pe “yoo ya yin lẹnu ti mo ba sọ fun yin pe ni Naijiria, ko si ibi kankan ti eeyan ti le gba badminton.
“Ni ọpọlọpọ gbagede ẹ maa ri ibi ti awọn eeyan ti le gba oriṣiṣi bọọlu fun ere idaraya, bii bọọlu afẹsẹgba, bọọlu ẹlẹyin ati bẹẹ bẹẹ lọ, ayafi badminton nikan ṣoṣo ni ko si.
Nigba to n sọrọ nipa Opeyori, Francis Orbih sọ pe oun gbagbọ pe yoo ṣe aṣeyọri ninu idije Olympics to n lọ.
Bawo ni ile to ti jade ṣe ri?

Oríṣun àwòrán, Badminton Confederation Africa
Ko to bẹrẹ iṣẹ badminton, awọn iṣẹ pẹpẹpẹ ni Opeyeri n ṣe, bii ko ba iya rẹ duro si ṣọọbu tabi ko lọ si oko birisope.
Iya rẹ ni “nigba to sọ fun mi pe oun fẹ maa gba badminton mo tii lẹyin bo tilẹ jẹ pe oun funra rẹ ko mọ pe emi naa ti gba badminton ri.
“Gbogbo igba to ba fẹ rinrinajo fun idije ni mo maa n gbadura ati awẹ fun ko le ṣe aṣeyọri nitori mo mọ pe ti ọmọ mi ba ṣe oriire, emi naa ti ṣe oriire niyẹn.”
Ẹgbọn rẹ ọkunrin, Funsho naa n gba badminton ṣugbọn o fi iṣẹ naa silẹ lọna ati le ṣatilẹyin fun aburo rẹ ko le ṣe aṣeyọri.
O ni “mo pa ala mi nidi badminton ti fun aburo mi nitori mo ri pe o ni ọjọ iwaju rere nidi ere idaraya naa.
“Ini mi dun pe oun lo n keke tente ninu ere idara ọhun nilẹ adulawọ, mo si gbagbọ pe yoo ṣe daadaa ninu idije Olympics to n lọ.”
Nigba ti Opeyori yoo fesi pada, o ni “badminton n ṣan ninu ẹjẹ idile wa, o ti di oro idile fun wa.”









