Ọlọ́pàá tún ti pa èèyàn mẹ́rin míràn níbi ìwọ́de tó ń wáyé ní Kenya, iye àwọn tó ti kú ti súnmọ́ 50

Ọlọ́pàá tún ti pa èèyàn mẹ́rin míràn níbi ìwọ́de tó ń wáyé ní Kenya, iye àwọn tó ti kú ti súnmọ́ 50

Awọn oluwọde ni Kenya

Oríṣun àwòrán, BBC/Mercy Juma

Awọn ọlọpaa tun ti pa eeyan mẹrin miran lọjọ Iṣẹgun lasiko iwọde to n waye tako iṣejọba Aarẹ William Ruto lorilẹede Kenya eleyi to ti mu apapọ iye ẹmi to ti lọ si iwọde naa di aadọta laarin oṣu kan to ti bẹrẹ.

Iṣẹlẹ iṣekupani naa waye ni agbegbe Makueni, Nairobi ati Kitengela.

Ajọ to n mojuto ẹtọ ọmọniyan lorilẹede Kenya kede pe aadọta ẹmi lo ti ba iwọde naa lọ lati igba to ti bẹrẹ ni ọjọ kejidinlogun oṣu kẹfa.

Adele ọga ọlọpaa lorilẹede naa, Douglas Kanja ti ṣekilọ pe o ṣeeṣe ki awọn janduku kan lo anfani iwọde naa lati da wahala silẹ eleyi to mu ki awọn ọlọpaa naa bẹrẹ si ni yin afẹfẹ tajutaju ati ibọn.

Ọpọlọpọ lo fara ṣeṣe lasiko iwọde to waye ni Nakuru, Nairobi, Mombasa, Nyeri ati Machakos.

Ẹgbẹ awọn akọroyin lorilẹede Kenya, (KUJ) ti pe fun iwadii si ọlọpaa ti wọn fi ẹsun kan pe o yinbọn pa akọroyin kan to n ṣiṣẹ rẹ nibi iwọde to waye ni ẹkun Nakuru.

Bi o tilẹ jẹ pe Aarẹ Ruto ti ṣẹwele igbesẹ ofin owo ori tuntun to da gbogbo iwọde naa silẹ, to si tun ti tu igbimọ iṣejọba rẹ ka, awọn oluwọde ṣi n pe fun ikọwefiposilẹ Ruto funrarẹ lori awọn ẹsun bii ọwọja iwa ijẹkujẹ ati aijafafa iṣejọba.

Ẹ̀mí olùwọ́de kan tún ti bọ́ sí ìwọ́de ní Kenya, àwọn olùwọ́de ní kí Ààrẹ Ruto fipò sílẹ̀ ni
Awọn oluwọde ni Kenya

Oríṣun àwòrán, AFP

Àwọn oluwọde tako ijọba lorilẹede Kenya tun ti pada si oju popo bayii pẹlu ipe si Aarẹ orilẹede naa, William Ruto lati kọwe fi ipo rẹ silẹ, lainaani awọn igbesẹ itunu to gbe laipẹ yii.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wọn ti yinbọn pa arakunrin kan nibi iwọde naa lasiko ti awọn oluwọde ọhun n gbe ina woju awọn agbofinro ni itosi ilu Nairobi tii ṣe olu ilu orilẹede naa.

Ni aringbungbun Nairobi, titipa lawọn ṣọbu itaja wa lọwọ bi awọn ọlọpaa ṣe n yi afẹfẹ tajutaju lati tu awọn oluwọde naa ka.

Iwọde naa bẹrẹ loṣu to kọja lati tako abadofin kan to da lori owo ori sisan eyi ti ko dun mọ ọpọ awọn ọmọ orilẹede naa ninu bi o tilẹ jẹ wi pe aarẹ orilẹede naa ti gbẹsẹle abadofin ọhun.

Amọṣa o, awọn oluwọde naa ko sinmi, iwọde ati ẹhonu wọn ti n fẹju si awọn iwa kudiẹkudiẹ iṣejọba, ijẹkujẹ ati aṣemaṣe awọn ọlọpaa eleyi to ṣokunfa iku ọpọ awọn oluwọde lawọn iwọde to ti waye.

Lọsẹ to kọja, Aarẹ Ruto pe fun ijiroro lẹyin to yọ gbogbo awọn ọmọ igbimọ iṣakoso ijọba rẹ nipo ti ọga agba ọlọpaa lorilẹede naa si tun kọwe fi ipo rẹ silẹ.

Awọn ọdọ lo n ṣe agbodegba iwọde naa, pupọ wọn lo si ti faake kọri pe awọn ko ni ọrọ kankan lati ba Aarẹ Ruto sọ ju pe “ko fipo silẹ”.

Awọn oluwọde ni Kenya

Oríṣun àwòrán, BBC/Mercy Juma

Lọjọ iṣẹgun, awọn ero kan gbe oku oluwọde kan to ku lọjọ Iṣẹgun ni Kitengela nitosi agọ ọlọpaa kan lagbegbe gusu ilu Nairobi.

Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede naa ko tii sọ ohunkohun lori iku oluwọde ọhun.

Akọroyin BBC to wa nibi iṣẹlẹ naa ṣalaye wi pe, ariwo “Ruto gbọdọ lọ” lawọn oluwọde naa n pa. Bi wọn ṣe n da ina si oju popo ni wọn n ju okuta lasiko ti wọn gbe pẹrẹgi kana pẹlawọn ọlọpaa.

Wahala tun bẹ silẹ lawọn agbegbe miran jakejado orilẹede Kenya titi kan awọn ilu bii Mombasa, Kisumu, Nakuru ati Nyeri.

Ṣaaju lọjọ Iṣẹgun, adele ọga agba ọlọpaa lorilẹede naa, kede pe awọn iroyin iwadii ọtẹlẹmuyẹ kan ti fihan pe awọn ẹgbẹ ọdaran kan n gbero lati rapala wọ awọn oluwọde naa lati da iwọde wọn ru.

O wa rọ awọn oluwọde ọhun lati ṣe iwọde wọn ni pẹlẹputu ki wọn si ranti pe ojuṣe ọlọpaani lati daabo bo mutumuwa.

Ni ọjọ Aje ni aarẹ orilẹede Kenya, Ruto na ika si ajọ Ford Foundation pe awọn gan lo n ṣe agbatẹru iwọde naa.

Ninu atẹjade kan to fi sita, ajọ Ford Foundation, to fikalẹ si orilẹede Amẹrika ni irọ patapata ni ẹsun naa: “A ko ṣe agbatẹru tabi agbodegba fun awọn iwọde to waye tako abadofin owo ori yii.”