Gbajúmọ̀ orí Instagram dèrò ẹ̀wọ̀n fún òwò ẹrú àti fàyàwọ́ ọmọnìyàn

Aworan Kat Torres
    • Author, Hannah Price
    • Role, BBC Eye Investigations

Nigba tawọn arabinrin ọmọ orilẹede Brazil meji di awati loṣu Kẹsan an ọdun 2022, ẹbi wọn ati awọn ẹṣọ FBI bẹrẹ sii wa wọn kaakiri orilẹede Amẹrika.

Ohun kan ti wọn mọ ni pe gbajumọ ori itakun ayelujara Instagram, Kat Torres ni wọn jọ n gbe pọ.

Ni bayii, Torres ti ẹwọn ọdun mẹjọ he lẹyin to jẹbi ẹsun fifi eeyan ṣe kara-kata ati imulẹru ọkan lara awọn ọmọbinrin orilẹede Brazil to dawati.

‘’Torres dabi ireti fun mi,’’ Ana lo sọrọ yii nipa Torres nigba ti o ba a pade lori Instagram lọdun 2017.

Ana ko si lara awọn obinrin ti FBI n wa, amọ, oun naa fara kaasa iwa ipa Torres.

O ni ọkan oun fa si Torres pẹlu bi o ṣe maa n rinrin oge ati bi o ṣe maa n lọ ode ariya pẹlu awọn oṣere Nollywood.

Ana sọ fun ikọ oluwadii BBC pe o dabi ẹni pe Torres ti bori iwa ipa tawọn eeyan kan maa n ṣe sawọn ọmọde nigba kekere

Aworan Ana

Oríṣun àwòrán, Jack Garland/BBC

Àkọlé àwòrán, Aworan Ana nigba to wa pẹlu Torres lọdun 2019

Ana ni oun ti ni iriri iwa ipa nigba toun wa ni ọmọde, o ni lẹyin naa ni oun fi orilẹede Brazil silẹ ló Amẹrika.

Ẹwẹ, Torres ti gbe iwe kan jade nipa ara rẹ ti o pe orukọ iwe naa ni A Voz ninu eyi to ti sọ pe oun lagbara lati maa sọ asọtẹlẹ.

Ana sọ pe agbara ti Torres ni jẹ nnkan to maa n wu oun nipa rẹ.

Amọ, Ana ko mọ pe irọ lo pọju ninu ọrọ Torres.

Luzer Twersky to jẹ alabagbe Torres tẹlẹ niluu New York ṣalaye pe lati igba tawọn ọrẹ Torres to wa ni Hollywood ti fi ọna mimu oogun oloro ayahuasca han an ni aye rẹ ko ti bakan naa mọ.

Luzer Twersky to jẹ alabagbe Torres tẹlẹ niluu New York

Oríṣun àwòrán, Jack Garland/BBC

Àkọlé àwòrán, Luzer Twersky, to jẹ alabagbe Torres tẹlẹ niluu New York
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Torres sẹleri ifẹ ati owo fawọn onibaara lori itakun igbọrọkaye to ni o wa fun ilera awọn eeyan.

Awọn fidio to fi n gbawọn eeyan ni imọran lori ọrọ ifẹ laarin ọkunrin si obinrin, okowo, ilera, oogun lilo ati ere idaraya naa wa lori itakun igbọrọkaye ọhun.

Onibaara to ba le san $150 le lanfaani lati ba Torres gan an sọrọ ti yoo si wa ojutuu si iṣoro ti ẹni naa ba gbe wa.

Ana, Amanda atawọn mii ti wọn n tẹle Torres sọ pe awọn o nifẹ si kawọn maa ba ẹbi tabi ọrẹ awọn sọrọ mọ tori awọn ti wa pẹlu Torres.

Fun apẹẹrẹ, Ana ko le sọ pe rara nigba ti Torres ni ki o wa ṣe amugbalẹgbẹ foun lọdun 2019.

Ikọ oluwadii BBC ati BBC News Brasil gbe otitọ jade lori bi awọn bi awọn ti wọn lawọn ni imọ nipa nnkan ti ẹmi bii Torres ṣe n pọ si ati bi wọn ṣe n wa eeyan lati fi ṣe katakara kaakiri agbaye.

Nigba ti Ana de ile Torres ni o ri pe igbe aye rẹ lori Instagram yatọ gedegede si igbe aye rẹ ni ikọkọ.

Ana ni ọpọ nnkan ni Torres ko le ṣe fun ra rẹ lai ri oun.

O ni ni ṣe ni gbogbo ile ti Torres n gbe n run nigba toun de ibẹ.

Kat Torres

Oríṣun àwòrán, Kat Torres

Àkọlé àwòrán, Miliọnu kan eeyan lo n tẹle Torres lori Instagram

‘’Mo ti ri bayii pe ni ṣe ni Torres lo mi bi ẹru, o dabi ẹni pe ko si ọna abayọ fun mi mọ.

O fẹẹ jẹ pe ọkan lara awọn eeyan ti wọn fi ṣe kata-kara ni mi,’’ Ana lo sọ bẹẹ.

Ana ni Torres ko sanwo kankan foun pẹlu gbogbo ohun ti oun ṣe nile rẹ.

Amọ, lẹyin oṣu mẹta, Ana ri ọna abayọ pẹlu bi o sẹ ba ọrẹkunrin rọ lọ.

Ana mọ wi pe oun ni lati ṣe nnkan nigba tawọn ọdọmọbinrin orilẹede Brazil kan dawati loṣu Kẹsan an ọdun 2022.

Ni bayii, igbe aye Torres ti yipada lẹyin to ṣe igbeyawo pẹlu Zach, ẹni ọdun mọkanlelogun ti awọn mejeeji ṣi jọ gba ile si Austin ni Texas.

Amọ, Torres tẹṣiwaju pẹlu bi o ṣe maa n sọ fawọn to n tẹ le e wi pe oun fẹ ran wọn lọwọ.

Bakan naa ni o tun wa ẹni ti yoo maa ba a ṣe ọpọ nnkan nile rẹ gẹgẹ bi o ti ṣe pẹlu Ana.

Aworan ile Torres ni Texas

Oríṣun àwòrán, Jack Garland/BBC

Àkọlé àwòrán, Torres fẹ k'awọn to n tẹ le e maa gbe pẹlu rẹ ni Austin, Texas

Iwadii BBC fihan pe awọn obinrin mẹrin ni Torres gbiyanju pe ki wọn maa gbe pẹlu rẹ lati le maa ba a ṣiṣẹ nile, ṣugbọn ko ṣee ṣe.

Ẹru n ba ọpọ awọn obinrin lati ba BBC sọrọ tori wọn n bẹru wi pe awọn eeyan kan le tabuku wọn lori ayelujara.

Ọkan lara awọn obinrin yii sọ pe Torres tiẹ ti ra tikẹẹti toun yoo fi wọ baalu lati Germany wa si Amerika ni ile rẹ.

Sol ni tiẹ sọ pe oun gba lati ko lọ sile Torres lẹyin toun o nile lori mọ.

Amọ, ko pẹ ju t'awọn obinrin yii fi mọ pe kii ṣe ohun tawọn n ri lori Instagram ni bi Torres ṣe ri loju aye.

Desirre ni Torres sọ foun pe ki lọ maa ṣiṣẹ ni ile ijo kan tawọn obinrin ti maa n ṣi ara silẹ.

Torres ni Desirre gbọdọ da gbogbo owo toun ti na le e lori to fi mọ agbara awọn ajẹ ti Torres n lo fun un.

Eyi lo mu ki ẹru ba Desirre ti o ṣi gba lati lọ maa ṣiṣẹ ni ile ijo ọhun.

Desirre ati Sol ni Torres gbe alakalẹ ilana to lagbara kalẹ fawọn obinrin to n gbe pẹlu rẹ nile ni Austin, Texas.

Wọn ni awọn o gbọdọ ba ara awọn sọrọ, ati pe wọn gbọdọ gba aṣẹ lọwọ Torres ki wọn to le jade sita lati yara wọn tabi ki wọn to le wẹ gan an.

Aworan Kat Torres, Desirrê ati Letícia

Oríṣun àwòrán, Kat Torres

Àkọlé àwòrán, Torres, Desirrê ati Letícia

Sol ṣalaye o nira lati fi Torres silẹ tori oun lowo wa wa lọwọ rẹ.

Amọ, Sol pinnu lati kuro l'ọdọ Torres lẹyin to bẹrẹ si ni gbọ bi Torres ṣe n fun ẹni kan lori foonu to n ba onibara rẹ kan sọrọ pe o gbọdọ lọ ṣiṣẹ asẹwo ni Brazil gẹgẹ bi ijiya rẹ.

Ọrekunrin Sol tẹlẹ lo doola Sol lọwọ Torres.

Desirre ni Torres sọ foun pe ki oun fi iṣẹ ile ijo silẹ lọ maa ṣe aṣẹwo.

Desirre loun kọkọ kọ si Torres lẹnu, ṣugbọn oun pada lati lọ ṣiṣẹ asẹwo lẹyin ti Torres fi ibọn dẹru ba oun.

O ni ẹni ti ko ba pa to $3000 lojumọ gẹgẹ bi aṣẹ ti Torres pa, ẹni naa ko gbọdọ pada lọ ile.

Desirre ni lọpọ igba loun maa n sun sita.

Akọsilẹ ti Desirre fi han BBC fidi rẹ mulẹ bi o ti fi $21,000 ranṣẹ si akaunti Torres.

Awọn ọrẹ Desirre kan tiẹ ti ro pe bo ya wọn ti ṣekupa a ni.

Ana at'awọn mii to bọ sọwọ Torres kan si ẹṣọ eleto abo FBI lati fọwọ ofin mu Torres.

Koda, Ana pin fidio to ṣe eyi to ti ṣalaye pe Torres n dunkooko iku mọ oun pẹlu BBC gẹgẹ bi ẹri.

Lẹyin ti awọn ileeṣẹ iroyin bẹrẹ sii kọ nipa Torres ni o gbera kuro ni Texas rinrin ajo lọ si Maine.

Desirre ati Letica naa ṣe fidio kan eyi ti wọn gbe sori Instagram lati sọ fáwọn eeyan pe ko si ẹni to ji awọn gbe.

Ni oṣu Kọkanla ọdun 2022 ni awọn ọlọpaa gba Torres ni imoran pe ki o wa fun ayẹwo ara re.

Awọn ọmọbinrin mejeeji pada si Brazil loṣu Kejila ọdun 2022.

Ohun to sẹlẹ pẹlu Torres kin ọrọ ajọ iṣọkan agbaye UN lẹyin, lori ọrọ to sọ pe fifi eeyan kata-kara jẹ iwa ọdaran to n gbilẹ lojoojumọ lagbaaye.

Ajọ UN sọ pe owo to to $150bn ni wọn n ri níbẹ lọdọọdun.

Loṣu Kẹrin ọdun yii, ni ikọ oluwadii BBC gba aṣẹ ileẹjọ lati ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Torres ni ọgba ẹwọn lorilẹede Brazil.

O ṣi n reti idajọ lori ọrọ Desirre nigba naa.

Amọ, Torres ba BBC sọrọ pẹlu iwa pẹlẹ.

Kat Torres

Oríṣun àwòrán, Jack Garland/BBC