'Tí Naijiria bá dára lónìí, èèrò yóò dínkù ní ṣọ́ọ̀ṣì'
Ojiṣẹ Ọlọrun kan, Alufa Bayo Oluwayemi, ti sọ pe ni kete ti ayipada rere ba ba orilẹede Naijiria, ni eero yoo dinku ni awọn ile ijọsin.
Nigba to n ba BBC sọrọ lori ipa ti adura le ko ninu idagbasoke orilẹede ọhun, alufa Oluwayemi ṣalaye pe adura nikan ko le yanju awọn iṣoro to n dojukọ Naijiria.
O ni ọpọlọpọ iranṣẹ Ọlọrun lo ma n ro pe o yẹ ki wọn o pa iṣẹ oojọ wọn ti, ni kete ti wọn ba ti gbọ ipe.
Alufa Oluwayemi sọ pe ko si nnkan to buru ninu ki iranṣẹ Ọlọrun mu iṣẹ miran mọ iṣẹ oluwa.
“Ki awọn eniyan o ma maa fi akoko to yẹ ki wọn o fi ṣe iṣẹ ṣofo niwaju Ọlọrun.”
O ni ọpọ eeyan lo gbagbọ pe pipẹ niwaju Ọlọrun nikan ni ọna ti adura le tete gba.
“Eyi ko ri bẹẹ. Awọn orilẹede ti ko gbadura to wa gan-an n ni ilọsiwaju ju wa lọ.
“Idi ni pe pupọ ninu awọn nnkan ti a n gbadura le lori nibi, ijọba ati iṣakoso rere lo n yanju rẹ fun wọn ni awọn orilẹede miran.
O ni aigbọ nnkan ti Ọlọrun n sọ daada, lo mu ọpọ maa taku tii lọrun.
Eyi lo ni ko ṣẹyin agbegbe wa lo mu ki irinajo igbagbọ yatọ ni Naijiria.
“Ti Ọlọrun ba gbe Naijiria soke, ti gbogbo ọdọ niṣẹ lọwọ, eeyan a dinku ni ile ijọsin.”



