Wo ìdí tí alága ìbílẹ̀ 401 fi kọ̀wé fipò sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà l’Osun lẹ́yìn ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ

Aworan Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke@X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọkan-le-nirinwo (401) alaga ibilẹ ti wọn jẹ alaabojuto ati awọn igbimọ wọn lo ti kọwe fipo silẹ bayii nipinlẹ Ọṣun.

Eyi waye lẹyin idajọ ile-ẹjọ to ga julọ, to ni ijọba ibilẹ ni yoo maa gba owo to tọ si wọn lati ọdọ ijọba apapọ funra wọn bayii, awọn gomina ko ni i gba a mọ bii iṣe wọn.

Alaga mọkandinlaadọrin pẹlu awọn ọmọ alaabojuto 332 ni wọn kọwe fipo silẹ l’Ọṣun bayii.

Bo tilẹ jẹ pe iwe ifiṣẹsilẹ naa gba ori ayelujara kan l’Ojọru, ọjọ kẹtadinlogun oṣu keje 2024 yii, sibẹ, awọn eeyan naa ko sọ idi kankan to mu wọn fiṣẹ silẹ.

Ijọba ibilẹ ọgbọn lo wa nipinlẹ Ọṣun, tijọba ibilẹ onidagbasoke mejilelọgbọn, ẹlẹkun-jẹkun mẹfa ati ọfiisi alakooso kan.

Gomina Ademola Adeleke lo yan ikọ alaga ati alaboojuto to gbẹyin loṣu kẹjọ ọdun 2023.

O fi oṣu mẹfa kun akoko ti wọn yoo lo lọfiisi loṣu keji ọdun 2024.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ALGON ṣalaye idi tawọn alaga fi kọwe fipo silẹ

Alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ALGON ti ẹka ipinlẹ Osun, Sarafadeen Awotunde, ṣalaye fun BBC Yoruba wi pe awọn alaga atawọn ọsiṣẹ yooku kọwe fipo silẹ lẹyin ti ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ti dajọ pe wiwa lọfiisọ awọn lodi sofin.

Ọgbẹni Awotunde to jẹ alaga alamojuto ijọba ibilẹ Ifelodun Central tẹlẹ ṣalaye pe ‘’idajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ko da awọn alaabojuto alaga mọ gẹgẹ bi ojulowo alaga ijọba ibilẹ.

Ni bayii, ani lati lọ ṣe eto idibo bayii, ohun ti ile ẹjọ to ga julọ sọ ni awa tẹle.

O ṣee ṣe ki a dibo ni bẹrẹ ọdun 2025 to n bọ.

Ọgbẹni Awotunde fikun ọrọ rẹ pe igba diẹ naa lawọn alaga alamojuto ni tẹlẹ.

‘’Ni bayii ko si ohun to n jẹ alaga alamojuto mọ ni ijọba ibilẹ lorilẹede Naijiria, gẹgẹ bi idajọ ile ẹjọ to ga julọ ṣe sọ,’’ Awotunde lo sọ bẹẹ.

Ijọba

Tinubu gboṣuba kare fun ile ẹjọ to ga julọ lorileede Naijiria lori idajọ to gbe kalẹ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ti gbe oṣuba kare fun ile ẹjọ to ga julọ lorileede Naijiria lori idajọ to ṣẹṣẹ gbe kalẹ lori ominira awọn ijọba ibilẹ pẹlu iṣakoso owo to tọ si awọn ijọba ibilẹ kaakiri Naijiria, eyi ti awọn gomina n ko si ipamọ.

Tinubu ni awọn araalu, paapaa awọn to ku diẹ kaato fun yoo bẹrẹ sii fa awọn adari wa lawọn agbegbe laṣọ lori bi wọn ṣe n na owo ilu to n wọle fun wọn lati asiko yii lọ.

Bi ẹ ko ba gbagbe, l’Ọjọbọ, ọsẹ yii ni ile-ẹjọ agba naa gbe idajọ kalẹ wi pe ki awọn gomina dẹkun lati maa gba owo to tọ si awọn ijọba ibilẹ, nitori pe wọn ko lẹtọ sii, ati pe o ti di iwa aibofin mu bayii.

Bakan naa ni ile-ẹjọ tun paṣẹ pe awọn gomina ko lẹtọọ lati maa tu iṣakoso awọn ti wọn dibo yan s’awọn ijọba ibilẹ ka, ati pe nipa ṣiṣẹ eyi, wọn ti n tapa si iwe ofin orileede Naijiria ti ọdun 1999.

Ko pẹ si asiko ti idajọ yii waye ni Arẹ Tinubu sọ pe bi ijọba ibilẹ ko ṣe ri iṣẹ ṣe mọ jẹ ọkan gboogi lara awọn ipenija to n doju kọ idagbasoke orileede lati ọdun pipẹ sẹyin.

Nipaṣẹ idajọ yii, awọn eeyan wa – paapaa awọn mẹkunnu – yoo ni anfaani lati bẹrẹ sii fa awọn adari wọn nijọba ibilẹ laṣọ lati ṣalaye bi wọn ṣe n na owo ati bi wọn ṣe n ṣiṣẹ,” wọnyi lohun ti Ajuri Ngelale to jẹ agbẹnusọ Tinubu sọ sita.

Ngelale tẹsiwaju pe “Ohun ti wọn fi n ranṣẹ si apo aṣuwọn ijọba ibilẹ ni yoo bẹrẹ sii di mimọ bayii, ati pe wọn gbọdọ maa fi ṣe awọn iṣẹ to yẹ lati ni awijare kankan.

“Iṣakoso mi lo gbe eyi dide nitori igbagbọ wa ni pe ohun gbogbo gbọdọ tu awọn eeyan wa lara, ati pe idajọ tonii yoo fidi rẹ mulẹ pe gbogbo awọn ti wọn ba yan sipo oṣelu nijọba ibilẹ ni yoo bẹrẹ sii ṣakoso awọn ohun amuṣọrọ araalu.

“Ofin yii fidi mulẹ gẹgẹ bi idaniloju pe a le ọna ofin lati fi ṣatunto orileede yii ati eto ọrọ aje wa lati le ki Naijiria wa ni ipo to dara lati gbe fun awọn eeyan wa ni irọrun.”

Bakan naa lo gbe oṣuba kare fun adajọ agba ati minisita fọrọ eto idajọ lorileede yii ati, Lateef Fagbemi lori ọkan akikanju rẹ, to si ni iṣẹ to ṣe pataki ni idajọ to waye naa.