Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Naijriia yóò bẹ̀rẹ̀ sí gba owó yíyá láti ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ - Nelfund

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbogbo awọn akẹkọọ fasiti ati awọn ile ẹkọ giga ni Naijiria to ti fi orukọ silẹ fun eto owo yiya lati ọdọ ijọba apapọ, yoo bẹrẹ si ni gba owo naa lati ọsẹ to n bọ.
Ajọ to n mojuto eto ọhun, NELFUND, fi ikede sita ni Ọjọbọ pe awọn akẹkọọ to n bẹrẹ saa eto ẹkọ miran bayii ni yoo kọkọ bẹrẹ si ni gba owo.
Nigba to n sọrọ, Oludari ajọ NELFUND, Akintunde Sawyerr, sọ lori eto kan lori amohunmaworan Channels pe, awọn akẹkọọ yooku to fi orukọ silẹ ko ni ri owo gba titi di igba ti eto ẹkọ saa tuntun ba bẹrẹ ni ile ẹkọ wọn.
Ikede Ọgbẹni Sawyerr waye lẹyin wakati diẹ ti Aarẹ Bola Tinubu ṣe ifilọlẹ eto owo yiya Nigeria Education Loan Fund (NELFUND) niluu Abuja.
O ni 170,000 akẹkọọ lati awọn fasiti, ile ẹkọ gbogboniṣe, ati ile ẹkọ olukọni, lo fi orukọ silẹ pẹlu NELFUND, ṣugbọn 110,000 lara wọn lo ti pari eto kikọwe beere fun owo.
Ọga agba ajọ naa sọ pe abala meji ni awọn to le jẹ anfaani owo yoya naa pin si –
Abala akọkọ ni awọn ile ẹkọ ti yoo gba owo ile ẹkọ awọn akẹkọọ wọn to kọwe beere fun owo
Abala keji ni awọn akẹkọọ funra wọn ti yoo gba owo ti wọn yoo maa na loṣooṣu
Ọgbẹni Sawyerr ṣalaye pe eto owo yiya fun akẹkọọ jẹ na lati fun Naijiria ni anfanai si adari to dara, ati fun imugbooro ọrọ aje.
Lara awọn amuyẹ ti akẹkọọ ti yoo janfaani owo naa gbọdọ ni ni nọmba UTME, BVN, ati NIN.














