Kí ni Unilorin ń ṣe láti fòpin sí ìjàm̀bá okọ̀ tó ń mú ẹ̀mí lọ ní gbogbo ìgbà l'ọ́gbà ilé ẹ̀kọ́ nàá?

Oríṣun àwòrán, Others
Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Unilorin, ìpínlẹ̀ Kwara ti ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ àti ìlànà láti fòpin sí bí ìjàm̀bá okọ̀ ṣe máa ń wáyé ní òpópónà ilé ẹ̀kọ́ náà.
Ní Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Keje ọdún 2024 ni ìjàm̀bá okọ̀ kan wáyé nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ Unilorin níbi tí akẹ́kọ̀ọ́ kan ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.
Yàtọ̀ sí akẹ́kọ̀ọ́ tó jáde láyé, ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ míì ló tún farapa tí wọ́n ṣì wà nílé ìwòsàn níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí ìjàm̀bá okọ̀ ń gbẹ̀mí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ náà.
Nínú oṣù Kejìlá ọdún 2021 ni ìjàm̀bá okọ̀ gbẹ̀mí èèyàn márùn-ún ní òpópónà tó wọ inú ọgbà náà láti ẹnu géètì.
Àwọn ẹbí náà, tí ìyàwó jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga ọ̀hún ní ìjàm̀bá okọ̀ ní nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án alẹ́ tí àwọn mẹ́ta sì dágbére fáyé lójú ẹsẹ̀.
Ní ilé ìwòsàn ńlá UITH tí wọ́n gbé àwọn méjì yóòkù lọ, ni wọ́n dákẹ́ sí látàrí ìjàm̀bá náà.
Yàtọ̀ sí èyí, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìjàm̀bá okọ̀ máa ń wáyé ní ọ̀nà náà tó sì máa ń la ẹ̀mí àwọn ènìyàn lọ.
Èyí ló mú BBC News Yoruba kàn sí agbenusọ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Unilorin, ọ̀gbẹ́ni Kunle Akogun láti sọ̀rọ̀ lórí ipa tí wọ́n ń kó láti fòpin sí ìjàm̀bá gbogbo ìgbà yìí.
Kunle Akogun sọ pé ọ̀pọ̀ ìgbésẹ̀ ni àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ náà ti ń gbé tẹ́lẹ̀ láti dènà eré àsápadajúdé tí àwọn awakọ̀ máa ń sá ní òpópónà náà.
Ó ṣàlàyé pé lára rẹ̀ ni mímọ àwọn pepele sí àwọn ọ̀nà náà láti máa dènà eré sísá fún àwọn awakọ̀.
Ó sọ pé nítorí bí ọ̀nà ṣe tẹ́ rẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn awakọ̀ ni kìí kó ara wọn ní ìjánu nígbà tí wọ́n bá ń wa ọkọ̀.
Ó wá rọ gbogbo àwọn awakọ̀ tó ń lo òpópónà náà láti máa kó ara wọn ní ìjánu nígbà tí wọ́n bá wà ní òpópónà náà.
Agbenusọ ilé ẹ̀kọ́ náà tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé onírúurú ìgbésẹ̀ ni ilé ẹ̀kọ́ náà ti ń gbé báyìí láti ri pé àwọn ti ọwọ́ àwọn awakọ̀ tí kò bá tẹ̀lé àwọn ìlànà lórí iye òdiwọ̀n eré tí wọ́n gbọ́dọ̀ máa sá ní òpópónà náà bọ aṣọ.
Akogun ní àwọn tún máa bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àyẹ̀wò fún awakọ̀ tó ń ná ilé ẹ̀kọ́ náà láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọn kò máa mú ọtí tàbí egbògi olóró lásìkò tí wọ́n bá ń wa ọkọ̀.
“Àwọn aláṣẹ ń gbé àwọn ìgbésẹ̀ tí a máa fi síta láìpẹ́.”
Èèyàn kan kú, mẹ́sàn-án farapa nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé nínú ọgbà Unilorin

Oríṣun àwòrán, Screenshot/X
Eeyan kan ti sọ ẹmi rẹ nu, ti awọn mẹsan-an mii si farapa ninu ijamba ọkọ kan to waye ninu ọgba fasiti ilu Ilorin ni ọsan Ọjọbọ.
Agbẹnusọ fasiti Unilorin, Ọgbẹni Kunle Akogun, sọ ninu atẹjade kan pe ọkọ akero bọọsi ọ̀hun n ko eero lati inu ọgba ile ẹkọ naa lọ si aarin ilu ni ko to o ni ijamba.
Ṣugbọn ko sọ boya akẹkọọ ni ẹni to ku naa tabi oṣiṣẹ ninu ọgba fasiti.
Ọgbẹni Akogun ṣalaye pe ibanujẹ nla ni iṣẹlẹ naa jẹ fun awọn alaṣẹ Unilorin.
O ni ni kete ti iṣẹlẹ naa waye, ni awọn alaṣẹ fasiti ti gbe igbesẹ idoola, ti wọn si gbe awọn to farapa lọ si ileewosan fasiti ọhun nibi ti wọn ti kọkọ gba itju pajawiri.
Ẹnikan to nilo itju to l’agbara ni wọn gbe lọ si ileewosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo fasiti naa.
“Oju ẹsẹ ni eeyan mẹrin ninu wọn ti pada sile nitori wọn ko farapa pupọ.
Iroyin sọ pe o ku diẹ ki bọọsi naa de ẹnu ọna abajade fasiti, lo ni ijamba.
Awọn eeyan kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ lori ayelujara pe, taya ọkọ naa lo fọ lori ere, eyi to mu ko doju delẹ. Amọ a ko le fidi eyi mulẹ.
Fidio nipa iṣẹlẹ naa to wa lori ayelujara ṣafihan bi awọn to farapa ninu ijamba ọhun ṣe n jẹ irora nilẹ, pẹlu aworan obinrin kan to da bii pe ko si ẹmi lara rẹ mọ.












