Wo ìdí tí 'internet' rẹ kò fi ṣiṣẹ́ dáadáa lásìkò yìí

foonu ati laptop ti ko ṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọpọlọpọ awọn papakọ ọkọ ofurufu, ileewosan, irinajo ọkọ ojurin, ati awọn ileeẹ mii to n lo ayelujara, ni iṣẹ wọn ti dẹnukọlẹ bayii, nitori bi ayelujara ‘internet’ ko se ṣisẹ.

Awọn ileeṣẹ nlanla ni ilẹ yuroopu, America, ati kaakiri agbaye, si lo ti n kọminu lori ohun to n ṣẹlẹ.

Ọrọ naa ko yọ awọn banki ati awọn ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ naa silẹ. Ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ bi Sky News, ko si lori afẹfẹ nitori iṣẹlẹ ọhun.

Ni awọn papakọ ọkọ ofurufu bii ti Sydney, Berlin, irinajo reluwe ni UK awọn baalu to yẹ ko rinrinajo ni wọn ko le lọ mọ nitori aisi eto ayelujara.

Microsoft sọ pe ni nnkan alẹ Ọjọbọ ni nnkan to mu internet dẹnu kọlẹ, waye.

Ni Australia, ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ nla nibẹ, Telstra, naa fi ara ko lara idẹnukọlẹ ayelujara.

Awọn ileeṣẹ to n mojuto eto iranwọ pajawiri ni America ti fi ikilọ sita pe, awọn ko ni le ṣiṣẹ kankan lasiko yii.

Koko nnkan to fa bi ayelujara ṣe dẹnu kọlẹ ko tii di mimọ, ṣugbọn ọpọ awọn ti ọrọ kan gbagbọ pe o ni nnkan ṣe pẹlu ẹrọ ayabiaṣa Microsoft.

Ileeṣẹ Microsoft, ogbontarigi ileesẹ kọmputa sọ pe oun ti n gbe igbesẹ atunṣe lori iṣẹlẹ naa, ki awọn eeyan le ni anfaani pada lati lo awọn aapu Microsoft 365.

Bakan naa ni iroyin to n lọ sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ ileeṣẹ kan to n pese aabo lori ayeluajra, Crowdstrike, lo wa nidii iṣẹlẹ naa.

Ileeṣẹ naa ni wọn lo ṣẹṣẹ ṣe ifilọlẹ irinṣẹ akn ‘software’, amọ ti isẹ rẹ foriṣanpọn. Eyi si ni igbagbọ wa pe o da oju opo ayelujara ru fun ọpọlọpọ kọmputa to n lo ayelujara.

Amọ ko tii si aridaju pe nnkan to fa a niyii.