Ọmọ tí kò bá tí ì pé ọdún méjìdínlógún kò lè di akẹ́kọ̀ọ́ nílé-ẹ̀kọ́ gíga ní Nàìjíríà mọ́- Ìjọba àpapọ̀

Aworan awọn akẹkọọ ọkunrin ati obinrin nileewe giga

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti kede pe aaye ko si fun akẹkọọ ti ko ba ti i pe ọdun mejidinlogun (18) lati wọ ileewe giga ni Naijiria mọ.

Minisita fun eto ẹkọ ni Naijiria,Ọjọgbọn Tahir Mamman lo sọ eyi di mimọ niluu Abuja l’Ọjọbọ, ọjọ kejidinlogun, oṣu keje ọdun 2024.

Nibi ipade apapọ kan to ṣe pẹlu ajọ JAMB to n gbani wọle sileewe giga ni Mamman ti ṣalaye pe ijọba apapọ ti bẹrẹ atunṣe si ilana ẹkọ.

O ni nigba ti yoo ba fi di oṣu kẹsan-an ọdun 2024, ti saa eto ẹkọ tuntun yoo bẹrẹ, yoo ti di eewọ fun awọn ọmọ ti ọjọ ori wọn ko ti i pe mejidinlogun lati di akẹkọọ nileewe giga.

Awọn ileẹkọ giga bii yunifasiti, ileewe gbogboniṣe ta a mọ si poli, ileẹkọṣẹ awọn tiṣa ti i ṣe College of Education ati bẹẹ bẹẹ lọ ni ofin naa kan bi ijọba Naijiria ṣe wi.

O fi kun un pe ipinnu yii ti wa ninu eto ijọba tipẹ, ati pe ipade kan yoo tun waye lori rẹ lọjọ kẹfa oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii.

‘’ O wa ninu eto ta a la kalẹ, pe nigba ti yoo ba fi di oṣu kẹsan-an, ofin yii yoo ti wa si imuṣẹ ni gbogbo ileewe pata, yala tijọba ni tabi ti aladaani.’’ Ọjọgbọn Mamman lo sọ bẹẹ.