Ṣé dandan ni fún àwọn iléèṣẹ́ aládàáni láti san 70,000 owó oṣù òṣìṣẹ́ tí ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ kéde?

Oríṣun àwòrán, Getty image
Afikun ti ba owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ bayii lorilẹde Naijiria, ijọba apapọ ati ajọ oṣiṣẹ ti fẹnuko si ẹgbẹrun lọna aadọrin (70,000) naira bii owo oṣu to kere ju ti oṣiṣẹ kan yoo maa gba.
Lati Ọjọbọ, ọjọ kejidinlogun, oṣu Keje 2024 ti ijọba apapọ ti kede afikun yii ni oriṣiriṣi ero ọkan awọn eeyan lori igbesẹ naa ti n jade.
Bawọn kan ṣe n sọ pe bo ti le wu ko ri, ẹgbẹrun lọna aadọrin yii ṣi yatọ si ẹgbẹrun lọna ọgbọn tijọba n san tẹlẹ, ati pe nnkan yoo tun rrun diẹ si i pẹlu ẹkunwo yii, bẹẹ ni awọn mi-in n sọ pe owo ọhun ko le ka nnkan kan.
Ọpọ eeyan lo n sọ pe ṣebi awọn ti wọn n gbowo lọdọ ijọba ni afikun de ba owo wọn. Wọn ni awọn ti ko ṣiṣẹ ijọba ti wọn si n na ọja kan naa ti awọn oṣiṣẹ n na nkọ.
Bawo ni wọn ṣe fẹẹ ṣe e ti wọn ko ni fi owo ọ̀wọ́n ra ọja ọ̀wọ́n.
Awọn ọlọja ti gbọ pe ijọba fowo kun owo oṣu oṣiṣẹ, wọn yoo sare fowo le ọja bayii,idakeji idẹra ni ẹkunwo naa yoo si fẹrẹ jẹ.
Ọrọ-aje Naijiria funra rẹ nkọ? Njẹ ẹkunwo yii yoo lapa rere lara rẹ ni abi ọmọ wo ni yoo bi?
Ẹka aladaani naa wa nibẹ pẹlu, wọn ti n sọ pe awọn ko lagbara ẹgbẹrun lọna aadọrin lati san fun oṣiṣẹ to gbowo kere ju.
Ileeṣẹ ti ko to nnkan tẹlẹ ti yoo si ni lati sanwo yii, ki ni yoo ṣẹlẹ si i pẹlu awọn to n ṣiṣẹ nibẹ.
Gbogbo eyi ni BBC Yoruba tan imọlẹ si pẹlu alaye lati ẹnu onimọ nipa ọrọ aje ati Amofin, Bisi Iyaniwura.
‘’Dandan ni ki ileeṣẹ aladaani san 70,000 bi eeyan to n ṣiṣẹ nibẹ ba ti le tó mẹẹẹdọgbọn’’

Oríṣun àwòrán, Bisi Iyaniwura
Amofin Bisi Iyaniwura ṣalaye pe labẹ ofin, gbogbo ileeṣẹ aladaani ti eeyan to n ṣiṣẹ nibẹ ba ti to mẹẹẹdọgbọn (25) soke lo gbọdọ san 70,000, owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ yii.
"Ṣugbọn ọpọ wọn ni ko ni i le san an, nitori wọn ti n koju iṣoro ọwọngogo ati aisi owo tẹlẹ ki ẹkunwo too de.
Bi wọn ko ba waa le sanwo naa, ohun ti yoo ṣẹlẹ naa ni pe wọn yoo nilati da awọn oṣiṣẹ kan duro lẹnu iṣẹ lati le sanwo awọn to ba ṣẹku.
A si mọ pe bi wọn ba da awọn eeyan kan duro lẹnu iṣẹ, ki ni iru awọn bẹẹ yoo maa ṣe.?
Ṣugbọn ko si ọgbọn mi-in ti awọn ileeṣẹ bayii le da ju ki wọn din owo ti wọn yoo ma na ku."
"Àwọn tí kò gbowó oṣù lọ́wọ́ ìjọba náà yóò faragbá níbẹ̀"
‘Gbogbo ọmọ Naijiria pata ni afikun owo oṣu yii yoo kan, yala ẹni to n gbowo oṣu lọwọ ijọba tabi awọn ti wọn n ṣiṣẹ ara wọn, tabi awọn ti wọn n ta ọja.
Ọna ti yoo fi kan wọn naa ni pe gbogbo wọn pata ni ọwọngogo ọja to wa nilẹ n kan tẹlẹ, ti yoo si tun maa kan pẹlu ẹkunwo to de.
Boya ẹkunwo ba owo oṣu tabi bẹẹ kọ, ọwọngogo ti wa nilẹ, ko dinku rara, gbogbo eeyan naa lo si n fi ara gba a.
Owo oṣu oṣiṣẹ to kere ju ni ipa lara ọrọ aje Naijiria funra rẹ, tori ohun ti a mọ si Inflation n koju ọrọ aje ilu yii.’’
Ọ̀na àbáyọ
‘’Ọna abayọ to wa naa ni pe ijọba ni lati ṣiṣẹ lori ọna ti ọrọ aje Naijiria yoo fi dide.
Wọn ni lati dẹkun ninawo ni inakunaa lori ohun ti ko nilo.
Ki wọn si yee kowo le ori ohun ti ko ni i mu èrè kankan jade fun ilu.
Awọn ọlọja ti wọn ko mọ ju ki wọn maa fowo kun owo ọja lọ nilati dẹkun rẹ, ki wọn yee fowo kun owo ọja nitori ẹkunwo tijọba ba ṣe.
Owo naa ko ti i to, debi ti yoo ṣẹku. O maa daa ka yee fi aye ni ara wa lara.’’
Bayii ni Bisi Iyaniwura, Amofin ati onimọ nipa ọrọ aje ṣalaye.













