Ọ̀sẹ̀ kan péré ni a fún Tinubu láti wá ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro Naijiria – Ẹgbẹ́ àwọn ọmọ Àríwá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ awọn ọmọ Ariwa Naijiria, Northern Nigeria Coalition, CNG, ti fun Aarẹ Bola Tinubu ni ọsẹ kan pere lati wa ojutu si iṣoro ti awọn araalu n koju.
CNG ni oun n gbe igbesẹ naa latari ọwọngogo ounjẹ, epo bẹntiro, atawọn iṣoro mi to n ba ọpọ araalu finra.
Wọn ni lootọ ni ọpanlamba iya n jẹ awọn ọmọ Naijria ṣugbọn iya naa pọ lapọju ni ọdọ awọn.
Jamilu Aliyu Chiranci, to jẹ olori ẹgbẹ naa ṣalaye fun BBC pe Naijiria ti wọ ipele to lewu gigi nitori oṣi ati iṣẹ to n ta araalu labẹ iṣejọba Tinubu, ko si sẹni ti yoo sọ pe ọrọ naa ko kan oun.
Chiranchi ni “ninu ohunkohun ti Aarẹ ba maa ṣe, o ni lati gbajumọ bo ṣe maa gba Naijiria la.
“133 miliọnu eeyan lo n ba iṣẹ ati iya finra ni Naijiria, ti ogun miliọnu eeyan si jẹ alairiṣẹṣe tabi alainiṣẹlọwọ.
“Awọn araalu tun n kọminu lori ọrọ awọn ajinigbe, bẹẹni iye owo ti wọn n ta ọja ti le si ni ida 34.19%, iye ti wọn n ta ounjẹ ti gbowo lori ni ida 40.66%.”
Chiranchi ke si Aarẹ Bola Tinubu pe ko tan isọrọ naa lati gbongbo, eyii to bẹrẹ lati igba to ti ṣe afikun iye wo opo bẹntiro, owo ina mọnamọna, bi wọn ṣe ja owo naira si isalẹ fun dọla atawọn nnkan mii to n fi iya jẹ araalu.
Ọkunrin naa tun tako afojusun ijọba lati fi kun owo epo ko le fi owo to ba ri nibẹ kun owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.
O ni Tinubu gbọdọ da gbogbo awọn to n ba jiroro lori eto ọrọ aje sọnu ko si yan awọn mii.
Chiranchi pari ọrọ rẹ pe ko si jọba kankan to tii fa ọwọ aago Naijiria sẹyin bii ti Bola Tinubu, nitori kaka ki ewe agbọn Najiria dẹ, niṣe lo n le koko labẹ rẹ.















