Agbábọ́ọ̀lù wo ni yóò gba àmì ẹ̀yẹ Ballon d’or ti ọdún 2024 yìí?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ta ni agbabọọlu ti yoo gba ami ẹyẹ Ballon d’or ti ọdun 2024 yii ni ibeere ti ọpọ akọroyin atawọn ololufẹ ere bọọlu afẹsẹgba n beere lati igba ti idije EURO ti pari lorilẹede Germany.
Ni ọjọ kẹrin oṣu Kẹsan an ọdun yii ni wọn yoo gbe orukọ awọn agbabọọlu ti ọkan lara wọn yoo gbade Ballon d’or fun saa bọọlu 2023-2024 to ti pari.
O dabi ẹni pe ọrọ ti fẹ bẹyin yọ fawọn agbabọọlu Real Madrid meji, Vinicius Jr ati Jude Bellingham, ti ọpọ ti n sọ pe ọkan ninu wọn ni yoo gba ami ẹyẹ ọhun lẹyin tawọn mejeeji kuna lati gba ami ẹyẹ Copa America ati ti EURO fun orilẹede wọn.
Wọnyii ni awọn agbabọọlu ti o ṣee ṣe ki ọkan lara wọn gba ami ẹyẹ Ballon d’or ọdun 2024.
Vinicius Jr (Real Madrid, Brazil)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ lo ti n darukọ Vinicius Jr pe oun ni ade Ballon d’or ọdun 2024 yii tọ si lẹyin to gba ami ẹyẹ La Liga ati ife UEFA Champions League pẹlu Real Madrid.
Vini gẹgẹ bi ọpọ eeyan ṣe maa n pe e gba goolu mẹrinlelogun sawọn fun Real Madrid nigba to tun ṣeranwo fun goolu mọkanla ni saa bọọlu to lọ.
Idije Copa America ni ọpọ tun ti ro pe Vinicius yoo fakọyọ nibẹ, amọ, ipele komẹsẹ-ọ-yọ ẹlẹni mẹjọ(Quarter Finals) ni Uruguay ti le ikọ agbabọọlu Brazil lọọle.
Lootọ, Vinicius ko lanfani lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ naa tori o ti gba kaadi yẹlo meji ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ naa.
Kaka ni agbabọọlu Brazil to gba ami ẹyẹ Ballon d’or kẹyin lọdun 2007.
Rodri (Manchester City, Spain)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbabọọlu aaringbungbun fun Manchester City, Rodri, tun ni agbabọọlu mii tawọn eeyan ti n sọ pe o le gba ami ẹyẹ Ballon d’or.
Ifẹsẹwọnsẹ kan ṣoṣo ni Rodri ti fidirẹmi ninu gbogbo ifẹsẹwọnsẹ to kopa ninu rẹ lati ibẹrẹ saa bọọlu to lọ titi di asiko yii yatọ si awọn ere bọọlu ti wọn fi pẹnariti yanju rẹ.
Ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije FA Cup naa ni ifẹsẹwọnsẹ kan ọhun.
Rodri gba ife Premier League, o tun gba UEFA Cup ati ife ẹyẹ agbaye fawọn ikọ agbabọọlu lagbaaye.
Rodri fọba le e nigba to gba ife ẹyẹ EURO 2024 to pari lọsẹ to kọja yii pẹlu orilẹede Spain.
Ko si agbabọọlu Manchester City kankan ko ti gba ami ẹyẹ Ballon d’or ri.
Goolu mejila ni Rodri gba sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹtalelọgọta ti o ṣi tun ṣeranwọ fun mẹrinla to gba fun Manchester City ati Spain.
Jude Bellingham (Real Madrid, England)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Jude Bellingham fakọyọ fun ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ni ọdun akọkọ to lo pẹlu ikọ agbabọọlu naa.
Bellingham gba ife mẹta ọtọtọ ni saa bọọlu to lọ lẹyin to gba La Liga, Champions League ati Super Cup ti La Liga.
Goolu mẹtalelogun ni Bellingham ti i ṣe ọdọmọde agbabọọlu England gba sawọn fun Real Madrid ni saa bọọlu to kọja.
Bellingham gbe England de ipele aṣekagba idije EURO 2024, amọ, Spain lo gba ife ẹyẹ naa mọ wọn lọwọ.
Lapapọ, goolu mẹtadinlọgbọn ni Bellingham gba sawọn fun Real Madrid ati England to ṣi tun ṣeranwọ fun goolu mẹrindinlogun.
Lionel Messi (Inter Miami, Argentina)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lionel Messi to ti gba ami ẹyẹ Ballon d’or julọ nigba mẹjọ tun ni agbabọọlu mii tawọn eeyan tun n sọ pe o tun le gba ami ẹyẹ ọhun lẹẹkan sii.
Goolu mejidinlọgbọn ni Messi gba sawọn fun Inter Miami ati Argentina.
Laipẹ yii ni Messi tun gba ife ẹyẹ Copa America fun Argentina lẹyin ti wọn lu Colombia pẹlu ami ayo kan sodo ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije ọhun.
Amọ, goolu kan ṣoṣo ni Messi ri gba sawọn ninu idije ọhun.
Inter Miami to jẹ ìkọ agbabọọlu rẹ ko gba ife ẹyẹ kankan ni saa bọọlu to lọ yii.















