Àwọn agbébọn ṣekúpa Baálẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ ọkúnrin lásìkò tí wọ́n lọ sètò ìsìnkú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn agbebọn ti ṣekupa Baalẹ ilu Chanchanji nipinlẹ Taraba, Alhaji Tanimu Kunbiya, ati ọmọ rẹ Yusuf Tanimu.
Alẹ ọjọ Ẹti ni iṣẹlẹ naa waye lasiko ti ori ade ọhun ati ọmọ rẹ n bọ lati ibi eto isinku kan nijọba ibilẹ Takum.
Ninu atẹjade kan lati ọwọ Emmanuel Bello, to jẹ agbẹnusọ gomina Agbu Kefas, o ni inu oun bajẹ gidi lori iku oriade naa ati ọmọ rẹ.
Gomina ipinlẹ ọhun sọ pe ẹni iyi ni oloogbe naa, ko si yẹ ko ku iku ẹsin bẹẹ.
Ninu atẹjade ọhun ni gomina naa ti ke si awọn agbofinro ki wọn bẹrẹ iṣẹ lẹsẹkẹsẹ lati ṣawari gbogbo awọn to lọwọ ninu ikọlu Baalẹ ọhun.
O parọwa si awọn eeyan ijọba ibilẹ ti iṣẹlẹ naa ti waye ki wọn ni suuru, o si ṣeleri fun wọn pe gbogbo ohun to yẹ ni ṣiṣẹ loun yoo ṣe lati ri daju pe awọn to pa Baalẹ naa yoo jiya to tọ labẹ ofin.
Kefas sọ siwaju si pe oun yoo tẹsiwaju lati maa ṣe awọn ohun to yẹ lati ri pe awọn eeyan agbegbe naa ko gbe ninu ifoya kankan.
Igba kẹta ree ti awọn agbebọn yoo ṣeku pa Baalẹ kaakiri ipinlẹ Taraba.
Baalẹ ti wọn kọkọ ṣekupa ni Baalẹ ilu Sansani, ki wọn to tun pa Baalẹ ilu Usmanu ko to kan Baalẹ ilu Takum yii.















