Obìnrin tó ṣẹ̀wọ̀n ọdún 43 fún ẹ̀sùn ìpànìyàn tí kò mọ̀ nípa rẹ̀ gbòmìnira

Sandra Hemme

Oríṣun àwòrán, Innocence Project

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Obinbrin kan to ti ṣẹwọn fun odidi ọdun mẹtalelogoji gbako ti gba itusilẹ bayii lẹyin ti iwadii fi han pe ko mọwọmẹsẹ ninu ẹsun to jiya rẹ.

Sandra Hemme wa lẹni ogun ọdun lasiko ti ile ẹjọ sọ pe o jẹbi ẹsun gigun obirin kan, Patricia Jeschke lọbẹ pa lagbegbe St Joseph, ni Missouri, lọdun 1980.

Iwadii lori idajọ rẹ fi han pe ko si ẹri kankan to so afurasi naa pọ mọ ẹsun ọhun ayafi ọrọ to sọ nile iwosan awọn laarun ọpọlọ lẹyin ti wọn fun loogun orun tan.

Ni bayii to ti wa lẹni ọdun mẹrinlelọgọta, awọn agbẹjọro rẹ sọ pe oun ni ẹni to ṣẹwọn fun ọdun pipẹ julọ nilẹ Amẹrika lori ẹsun ti ko mọwọ-mẹsẹ nipa rẹ.

Ajọ ‘Innocence Project’ to gbe ọrọ rẹ yẹwọ titi to fi gba itusilẹ sọ pe inu awọn dun pe oun atawọn mọlẹbi rẹ ti pada ri ara wọn soju bayii lẹyin ominira rẹ.

Innocence Project ni oun yoo tẹsiwaju lati maa ja fitafita titi ti wọn yoo fi wẹ orukọ rẹ mọ ninu ẹsun naa.

Adajọ Ryan Horsman sọ pe awọn agbẹjọro afurasi ọhun fi ẹri han pe onibara wọn ko jẹbi ẹsun to n jiya rẹ.

Ryan Horsman ni “ile ẹjọ yii ri daju pe ẹri to wa niwaju rẹ fi han obinrin yii ko mọ nnkankan nipa iṣẹlẹ naa.”

Iwadii fi han pe ọlọpaa kan lo foju fo ẹri to sọ ọkan lara awọn akẹgbẹ rẹ pọ mọ iwa iwa ọdaran naa.

Michael Holman, to jẹ ọlọpaa to jẹbi ẹsun ti obnrin naa jiya rẹ, ti jade laye lẹyin to ṣẹwọn fun ẹsun mii lọdun 2015.

Lẹyin itusilẹ obinrin afurasi naa lo lọ pade ẹgbọn rẹ obinrin, ọmọ rẹ ati ọmọ-ọmọ rẹ, ti gbogbo wọn si di mọ ara wọn.

Wayi o, iroyin ni obinrin ọhun yoo nilo iranlọwọ latari pe pupọ ninu igbesi aye rẹ lo ti lo lọgba ẹwọn.