Láti kékeré ni mo ti fún obìnrin lóyún láì lówó lọ́wọ́ – Mr Portable

Oríṣun àwòrán, @ayoolaiya
Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Olu Olowogemo Harejan, ti ọpọ mọ si “Mr Portable” ti ṣalaye pe lati kekere ni oun ti fun obnrin loyun lasiko ti oun ko lowo lọwọ.
Mr Portable lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwwerọ kan pẹlu akẹgbẹ rẹ, Biola Bayo.
Bo tilẹ jẹ pe o lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama, o ni oun ko kọkọ ronu lati lọ si fasiti.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, lati kekere ni oun ti fun fun obirin loyun.
O ni “Awọn eeyan maa n ri bii aṣiṣe amọ mi o ni pe ni aṣiṣe, ati kekere lati n fun eeyan loyun.”
Mr Portable ni nnkan bi ẹni ọdun mẹtalelogun si mẹrinlelogun lọdun 1997 ni oun kọkọ fun obinrin kan loyun bi ko tilẹ sowo lọwọ rẹ lọdun naa lọhun.
Oṣere naa ṣalaye pe aarin oun ati ẹni ti oun fun loyun nigba naa ko gun rege latari ija lemọlemọ laarin awọn.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn mejeji ko tii ni imọ to peye nipa igbeyawo lọdun naa lọhun, lẹyinorẹyin, wọn fi ara wọn silẹ.
Obirin gidi wa ninu awọn onitiata
Ni ti igbagbọ awọn eeyan kan pe oju obinrin to ba n ṣe ere ori itage kii gbebikan, Mr Portable sọ pe ko ri bẹẹ.
Ninu ọrọ rẹ, awọn obinrin mii ti kii ṣe tiata buru ninu iwa nọbi ju awọn obinrin to n ṣe tiata lọ.
O ni “mo pẹlu awọn to maa n sọ pe laye mi o le fẹ eeyan nidi iṣẹ tiata.
“Ṣugbọn awọn to wa ni igboro ninu aye, wọn buru ju awọn onitiata wa gan lọ, agbako ara wọn ju ti onitiata wa lọ.”















